Lọ́kọláyà kan kú lásìkò Hajj ní Saudi Arabia

Aworan Lọkọlaya naa

Awọn tọkọtaya kan lati orilẹede Amẹrika wa lara awọn to ku lasiko Hajj to ṣẹṣẹ pari ni Saudi Arabia.

Awọn tọkọtaya naa, gẹgẹ bi ọmọ wọn obinrin ṣe sọ fun BBC, lo nnkan bii wakati meji ninu oorun ki o to di wi pe ooru amuju ṣe iku pa wọn.

Alhaji Alieu Dausy Wurie, ẹni ọdun mọkanlelaadọrin ati Haja Isatu Wurie ẹni ọdun marundinlaadọrin ti wọn n gbe ni agbegbe Bowie ni ipinlẹ Maryland wa lara awọn eeyan ẹgbẹrun kan o le ọọdunrun ti wọn ku si Saudi Arabia lasiko Hajj ọdun yii.

Odinwọn ooru ọdun yiile ni ida 50⁰C lawọn akoko kan ni Saudi Arabia.

Saida Wurie ṣalaye fun BBC pe ikọ arinrinajo ti awọn obi rẹ dara pọ mọ kuna lati pese awọn nnkan ti wọn ṣeleri fun wọn, bii ounjẹ ati omi lọpọ yanturu.

Ni ọjọ Aiku ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹfa, ni awọn mejeeji di awati, lẹyin ọsẹ meji ti wọn de Saudi Arabia.

Lẹyin ọjọ diẹ, ni ọmọ wọn obinrin kede pe wọn ti jade laye.

O ṣalaye fun BBC pe irinajo silẹ mimọ Hajj mu awọn obi oun lọkan gidi gan ni

Lọkọlaya naa dara pọ awọn ọgọrun arinrinajo kan ti wọn ba ileeṣẹ arinrinajo kan lati Amẹrika lọ si orilẹede Saudi Arabia.