Àwọn ọ̀dọ́ ‘Gen Z’ tó ń ṣèwọ́de tako àfikún owó orí ní Kenya yabo ilé aṣòfin

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn oluwọde ọdọ ti ọpọ mọ si ‘Gen Z’ ti yabo ile igbimọ aṣofin niluu Nairobi ti i ṣe olu ilu orilẹede Kenya.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn ọdọ oluwọde naa kọju ija sawọn ọlọpaa ti wọn si ya wọ ile aṣofin niluu Nairobi.
Awọn ileeṣẹ tẹlifisan kan ṣafihan bi awọn oluwọde ṣe n gbe ifẹhonuhan lọ si ile aṣofin laarin gbungbun ilu Nairobi.
Awọn akọroyin BBC to wa nibi iwọde naa fidi rẹ mulẹ pe awọn n gbọ iro ibọn tawọn ọlọpaa nibi iwọde naa.
Bakan naa, awọn fidio kan lori ayelujara ṣafihan bawọn eeyan kan ṣe farapa lẹgbẹ ile aṣofin Kenya.
Ẹgbẹẹgbẹrun awọn ọmọ orilẹede Kenya lo ti n ṣe ifẹhonuhan lati aarọ ọjọ Iṣẹgun niluu Nairobi.
Bakan naa ni ifẹhonuhan n ṣẹlẹ kaakiri awọn ilu nla nla lorilẹede Kenya.
Awọn fidio kan lori itagun ayelujara ṣafihan bi ọpọ eeyan ti n rin lọ si Nairobi lati darapọ mọ iwọde ọhun.
Awọn ọdọ n ṣe iwọde tako afikun owo ori lori awọn ohun elo kan ti ijọba kede.
Awọn aṣofin n jiroro lori aba naa ki wọn to so ijiroro wọn rọ lori aba ọhun.















