Wo àwọn t’áyé rò pé yóò lọ síbi ìgbéyàwó Davido àti Chioma tí wọn ò lọ àtàwọn èèkàn ìlú tó wà níbẹ̀

Aworan Wizkid, Burna Boy, Portable ati Don Jazzy

Oríṣun àwòrán, BBC, Burnaboygram, Portable, Don Jazzy/Instagram

Ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹfa ọdun 2024 yii ni igbeyawo laarin gbajugbaja olorin takasufee n ni, David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido ati Chioma Rowland waye ni tootọ, amọ, awọn eeyan ṣi tun n sọ nipa igbeyawo naa di oni.

Lara ohun tawọn eeyan n sọ nipa rẹ ni awọn eeyan kan taye ti ro pe wọn o lọ sibi igbeyawo naa, ṣugbọn ti wọn o pada lọ sibẹ.

Awọn kan tiẹ ninu awọn eeyan yii ti wọn dabi akẹgbẹ Davido gan an ninu iṣẹ orin kikọ.

Eyi gan an lo mu ki ọpọ ti ro pe wọn gbọdọ wa lara awọn ti yoo wa nibi igbeyawo alarinrin ọhun.

Wọnyi ni diẹ lara awọn taye ro pe pe wọn o lọ sibi igbeyawo Davido ati Chioma, amọ, ti wọn ko lọ, lẹyin o rẹyin.

Portable

Aworan Portable

Oríṣun àwòrán, Portable/Instagram

Gbajugbaja akọrin takasufee, Habeeb Okikiola Badmus ti ọpọ mọ si Portable jẹ ọkan lara awọn olorin tawọn eeyan ro pe wọn o wa nibi igbeyawo Davido ati Chioma.

Amọ, Portable ko si lara awọn alejo to jokoo nibi igbeyawo alarinrin ọhun lagbegbe Victoria Island niluu Eko lọjọ Iṣẹgun.

Ẹwẹ, Portable ṣe fidio kan to pin lori itakun ayelujara ninu eyi to ti ṣo pe olorin mii, Zlatan Ibile, ni ko jẹ ki oun lọ sibi igbeyawo naa.

Portable sọ ninu fidio naa pe Davido ti pe oun lori ago nibi to ti n sọ foun nipa ayẹyẹ igbeyawo ọhun.

O ṣalaye pe nigba ti Davido n ba oun sọrọ lọwọ ni Zlatan pe oun eyi to jẹ ki ọrọ daru.

Portble ni to ba jẹ pe oun wa ni Naijiria ni, oun o ba wa nibi igbeyawo naa.

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 1

Wizkid

Aworan Wizkid

Oríṣun àwòrán, wizkidayo/Instagram

Ayodeji Ibrahim Balogun ti ọpọ mọ si Wizkid jẹ ọkan gboogi ninu awọn olorin takasufee tawọn eeyan ti ro pe yoo peju sibi igbeyawo akẹgbẹ rẹ niluu Eko ṣugbọn ti ko lọ.

Ọpọ eeyan lori ayelujara lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu Wizkid lori bi ko ti lọ sibi igbeyawo ọhun.

Ẹnikan lori itakun ayelujara Tiktok ti darukọ awọn eekan ilu bii Tiwa Savage, Don Jazzy, Rema, Chike, Obi Cubana, Cubana Chief Priest ti wọn wa nibi ayẹyẹ igbeyawo naa.

O ni o fẹẹ jẹ pe Wizkid nikan ni gbajugbaja akọrin takasufee ti ko si nibẹ.

Ẹlomiran tun sọ pe o kere tan bi ogun gomina lo wa nibi igbeyawo alarinrin naa ti Wizkid o lọ.

Ọpọ lo sọ pe ai si ibaṣepọ to dan mọran laarin Wizkid ati Davido ni ko jẹ ko yọju sibi ayẹyẹ naa.

Burna Boy

Aworan Burna Boy

Oríṣun àwòrán, Burnaboygram/Instagram

Olorin ọmọ Naijiria miran ti ọpọ ro pe yoo lọ sibi igbeyawo Davido ati Chioma amọ ti ko lọ ni, Damini Ebunoluwa Ogulu, MFR, ti ọpọ mọ si Burna Boy.

Ẹwẹ, ni Ọjọru ni Burna Boy fi aworan kan ti o n sọ nipa ode orin rẹ ti waye lọ Abamẹta opin ọsẹ yii niluu London soju opo X rẹ.

Eyi si lo jẹ ki ọpọ eeyan maa bi i leere nipa ayẹyẹ igbeyawo Davido pe kilode ti ko wa nibẹ.

Awọn mii tiẹ n bi i leere wi pe kilode ti ko ti fii ki Davido ku oriire lẹyin to ṣe igbeyawo pẹlu Chioma.

@badlieutanant atawọn mii lo sọ fun Burna loju opo X pe ṣe lo yẹ ko gbagbe ohun kohun to ba wa laarin wọn ki o ṣi ki Davido ku oriire.

Amọ, Burna ko fesi si gbogbo ọrọ tawọn eeyan n bi i leere lori ayẹyẹ igbeyawo Davido.

Aworan Burna Boy

Oríṣun àwòrán, Burna Boy/X

Diẹ lara awọn eekan ilu to wa nibi igbeyawo Davido àti Chioma ree

Don Jazzy

Aworan Don Jazzy

Oríṣun àwòrán, Don Jazzy/Instagram

Gbajugbaja olorin ati olootu orin ni Naijiria n ni, Don Jazzy wa lara awọn to ba Davido ati Chioma ni alejo nibi igbeyawo wọn.

Don Jazzy wa lara awọn to da agbada bolẹ nibi ayẹyẹ igbeyawo naa.

Zlatan Ibile

Aworan Davido ati Zlatan

Oríṣun àwòrán, Zlatan Ibile/Instagram

Bo tilẹ jẹ pe Portable ti kọkọ pariwo ninu fidio kan to ṣe lori itakun ayelujara pe Zlatan o lọ sibi igbeyawo Davido, Zlatan Ibile pada wa nibi ayẹyẹ naa.

Ọpọ eeyan lo ri Zlatan ninu fidio ti oun naa n da gọjọ gọjọ nibi igbeyawo ọhun.

Portable tiẹ pada sọ pe Zlatan pẹ ko to de ibi ayẹyẹ naa.

Amọ, gbogbo aye lo ri Zlatan pọ mọ ọkọ iyawo nibi aṣeyẹ naa.

Victor Osimhen

Aworan Victor Osimhen

Oríṣun àwòrán, Victor Osimhen/Instagram

Gbajugbaja ẹlẹsẹ ayo ọmó Naijiria, Victor Osimhen naa wa lara awọn peju sibi igbeyawo Davido ati Chioma niluu Eko.

Gbogbo eeyan lo ri Osimhen ninu fidio kan lori ayelujara nibi ti o ti di mọ Davido gbagi.

Awọn mejeeji ba ara wọn sọrọ diẹ nibi ayẹyẹ ọhun ti Osimhen ṣi n ki Davido ni mẹsan an mẹwaa.

Lẹyin ti wọn kira tan ni Osimhen to lọ jokoo.

Oloye Olusegun Obasanjo

Aworan Oloye Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọrọ igbeyawo Davido ati Chioma kan agba, o ṣi tun ewe.

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọdọ lo pọju nibi igbeyawo naa, aarẹ ana orilẹede Naijria, Oloye Olusegun naa ko gbẹyin ninu awọn alejo to wa nibi ayẹyẹ ọhun.

Aarẹ ana Naijiria naa wọ aṣọ funfun ti o ṣi jokoo nibi ayẹyẹ naa.

Cubana Chief Priest

Aworan Cubana Chief Priest ati Davido

Oríṣun àwòrán, Cubana Chief Priest/Instagram

Ọrọ igbeyawo Davido ati Chioma kan Cubana Chief Priest naa gbọngbọn

O ti sọrọ kan to ni ṣe pẹlu aṣọ to wọ lọ sibi igbeyawo naa eyi tawọn bẹrẹ si ni sọrọ le lori.

Ọpọ bẹrẹ si ni sọ oriṣiiriṣii nigba ti Cubana Chief Priest sọ pe miliọnu meje naira ni oun fi ran agbada toun wọ lọ si ibi igbeyawo Davido ati Chioma.

Wo ohun ti àwọn ìlúmọ̀ọ́ká sọ níbi ìgbéyàwó Davido àti Chioma

Aworan Ooni. Sanwo-Olu,Cubana Chief Priest

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/X

Iyawo dun lọsingin, ọkọ tun mi gbe. Lai ṣe ani ani, aye gbọ nipa igbeyawo alarinrin olorin takasufee, Davido ati iyawo rẹ Chioma niluu Eko.

Oriṣiiriṣii fọto ati fidio lati ibi igbeyawo naa niluu Eko lo lu ori itagun ayelujara pa.

Aṣọ n pe aṣọ ranṣẹ nibi igbeyawọ alarinrin naa, bẹẹ ni ọpọlọpọ ilumọọka, alẹnulọrọ ati gbajumọ lawujọ lo peju sibi ayẹyẹ naa to waye lagbegbe Victoria Island niluu Eko lọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹfa ọdun 2024 yii.

Ọpọ awọn alẹnurọ ati ilumọọka ti wọn wa nibi ayẹyẹ igbeyawo ọhun ni wọn ti sọrọ lori igbeyawo naa.

Wọnyi ni diẹ lara ohun tawọn ọtọkulu to wa nibi ayẹyẹ igbeyawo Davido ati Chioma sọ nipa ayẹyẹ naa.

Gomina Babajide Sanwo-Olu

Aworan Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/X

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, to wa lara awọn ọtọkulu to wa nibi igbeyawo naa ki tọkọ taya ko oriire igbeyawo wọn.

Sanwo-Olu ni ‘’ọrọ ifẹ yin lagbara, inu mi si dun lati wa lara awọn to peju sibi ayẹyẹ igbeyawo yin.

Mo gbadura pe ki igbeyawo yin kun fun ibukun, ifẹ ati ayọ.

Ẹ maa ba ara yin kalẹ, ẹ o si jọ ni aṣeyọri to pọ gẹgẹ bi ẹbi.''

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 2

Ooni Adeyeye Enitan Ogunwusi

Aworan Ooni Ile Ife

Oríṣun àwòrán, ooniadimulaife/Instagram

Ooni Ile Ife, Kabiesi Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ojaja keji naa wa nibi igbeyawo Davido ati Chioma niluu Eko.

Fidio kan to lu ori ayelujara pa ṣafihan bi Davido ṣe dọbalẹ niwaju Ooni ti Kabiyesi naa si fi ọwọ ko o mọra ti ori-ade naa ṣi n ṣe adura fun un.

Gomina Dapo Abiodun

Aworan Dapo Abiodun ati Davido

Oríṣun àwòrán, Prince Dr. Dapo Abiodun, CON/X

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapo Abiodun naa ko gbẹyin ninu awọn ọtọkulu to peju sibi igbeyawo Davido ati Chioma.

Gomina Abiodun naa ki Davido ati aya rẹ Chioma loju opo X rẹ.

Ọmọba Abiodun ni ‘’mo ki ogbontarigi akọrin takasufee, David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido ku oriire igbeyawo rẹ pẹlu ololufẹ rẹ ati ọjọ to ti pẹ, Chioma.

Mo gbadura pe Eledua yoo fi oore si igbeyawo wọn.

Ore ọfẹ Ọlọrun ati ifẹ yoo si jọba ninu idile wọn.

Skip Instagram post, 3
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 3

Nkechi Blessing

Aworan Nkechi Blessing

Oríṣun àwòrán, Nkechi Blessing Sunday/Instagram

Oṣere tiata, Nkechi Blessing naa wa lara awọn ilumọọka to wa nibi igbeyawo Davido ati Chioma.

Nkechi ti kọ ọrọ kan soju opo Instagram rẹ nigba to wa lode ariya naa.

Nkechi ni ‘’oju ti lẹri bayii nibi igbeyawo ti a wa.

Bi ọti mimu ṣe pọ ni ounjẹ naa pọ fawọn eeyan lati jẹ.

Koda, mo n wo bi mo ti le gbe ounjẹ lọ ile gan an.

Skip Instagram post, 4
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 4

Cubana Chief Priest

Aworan Cubana Chief Priest

Oríṣun àwòrán, Cubana Chief Priest/Instagram

Lara awọn ilumọọka to wa nibi igbeyawo Davido ati Chioma ni Cubana Chief Priest.

Ọrọ ti o sọ nibi igbeyawo naa ti di ohun ti ọpọ eeyan n gba bi ẹni n gba igba ọti bayii.

Nibi ayẹyẹ igbeyawo yii ni Cubana Chief Priest ti sọ pe ‘’duro na, jẹ ki n ka agbada mi ti mo fi N7,000,000 ran.

Skip Instagram post, 5
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post, 5

Wo àwọn fọ́tò àwòdamiẹnu láti ibi ìgbéyàwó Davido àti Chioma l'Eko

Aworan Davido ati Chioma

Oríṣun àwòrán, Thesabiradio/X

Ni ṣe ni aṣọ n pe aṣọ ranṣẹ nibi igbeyawo laarin gbajugbaja akọrin takasufe, Davido, ati afẹsọna rẹ, Chioma Rowland niluu Eko lọjọ Iṣẹgun

Ọrọ igbeyawo yii jẹ ọkan lara awọn nnkan tawọn eeyan n sọ nipa rẹ julọ lori itagun ayelujara papaa julọ X lonii ọjọ Iṣẹgun kẹẹdọgbọn oṣu Kẹfa ọdun 2024 ti a wa yii.

Lati ọjọ Aje ni Davido ti kọkọ ti fi awọn aworan rẹ kan ati ti Chioma lede loju opo Instagram rẹ.

Amọ, oriṣiiriṣii fọto ati fidio lo ti n jade lati ibi igbeyawo naa lati aarọ ọjọ Iṣẹgun.

Wọnyii ni diẹ lara awọn fọto to ti de ori itakun ayelujara X ati Instagram lati ibi igbeyawo Davido ati Chioma.

Òní ni ìgbéyàwó Davido àti Chioma – Wo bí ìfẹ́ wọn ṣe bẹ̀rẹ̀ àti àwọn nǹkan tí wọ́n là kọjá

Davido ati Chioma

Oríṣun àwòrán, Davido/Instagram

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2024, ni ayẹyẹ igbeyawo yoo waye laarin gbajugbaja akọrin takasufe, Davido, ati afẹsọna rẹ, Chioma Rowland.

Ṣaaju ikede ayẹyẹ naa ni iroyin s pe wọn ti ṣe igbeyawo wọn ni bi ọdun kan sẹyin.

Eyi jẹyọ ninu ọrọ kan ti Davido sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe ninu oṣu Kẹta pe, oun ti gbe Chioma niyawo.

Asiko ti ololufẹ mejeeji ọhun fi wa ni isinmi, lẹyin iku ọmọ wn, Ifeanyi, ni igbeyawo naa waye.

Lati ọdun 2018 ti Davido ti kede to si ṣafihan Chioma gẹgẹ bi ololufẹ rẹ, ninu orin rẹ kan Assurance’, ni iroyin ko ti dawọ duro lori ifẹ wọn.

Bakan naa ni awọn mejeeji kii tẹti lati fi ifẹ han si ara wọn ni gbangba.

Davido ti figba kan sọ ninu ifrwanilẹwo pe, o ti to ogun ọdun ti oun ti mọ Chioma, ti wọn si pade nigba to wa ni ipele akọkọ ni fasiti.

Ọdun 2013 si ni irinajo ifẹ ti bẹrẹ laarin wọn.

“Igbesẹ to dara julọ ti mo ti i gbe ni fifẹ Chioma.”

Ninu oṣu Kẹjọ, ọdun 2029, Davido kede pe awọn ẹbi wọn ti mọra.

Ninu oṣu Kẹwaa ọdun naa si ni wọn bi akọbi ọmọ wọn, Ifeanyi, botilẹ jẹ pe Davido ti bi ọmọ meji tẹlẹ. Amọ, ibanujẹ wọ inu ile ololufẹ mejeeji nigba ti ọmọ wọn ku.

Inu odo iwẹ igbalode to wa ninu ile wọn ni ọmọ naa ti mu omi yo.

Eyi waye lẹyin oṣu kan ti Ifeanyi sẹ ọjọ ibi ọdun mẹta.

Fun ọpọlọpọ oṣu si ni awọn mejeeji ko fi yọju si gbangba, yala lori ayelujara tabi igboro.

Ninu oṣu Kejila, awọn mejeeji yọju si Qatar nibi ti Davido ti kọrin ni idije agbaye lọdun 2022.

O ku diẹ ko pe ọdun kan ti ọmọ wọn ku, ni akọrin naa tun kede pe wọn bi ibeji ni orilẹede America.

Ohun to yẹ ki o mọ nipa Davido

Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 1992 ni wọn bi gbajugbaja akọrin, David Adeleke.

O di ilumọọka olorin lọdun 2010.

Oriṣiriṣi ami ẹyẹ si lo ti gba, lara eyi ti BET ati MTV wa.

Bakan naa ni wọn fi orukọ rẹ silẹ fun ami ẹyẹ Grammy lọdun 2024.