Kí ló fàá tí ògbóǹtagì agbébọn Dogo Gide fi ń pèsè ààbò fáwọn àgbẹ̀? Àlàyé rèé

Aworan awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, Others

Gbogbo awọn eeyan to n gbe lapa ariwa ilẹ Naijiria lo mọ ọkunrin gbajumọ agbebọn kan torukọ rẹ njẹ Dogo Gide bii ẹni mowo.

Ṣugbọn iyalẹnu nla lo jẹ fun awọn olugbe ipinlẹ Zamfara, nipa bi ọkunrin naa ti bẹrẹ si ni pese aabo to nipọn fun awọn agbẹ to wa nibẹ, ki wọn le pada sori oko wọn pẹlu alaafia ohun ifọkanbalẹ.

Awọn agbẹ to n gbe nilu Tsafe to wa nijọba ibilẹ Maru ipinlẹ Zamfara, ati awọn mii nijọba ibilẹ Fasari nipinlẹ Katsina ṣalaye fun BBC pe ọjọ ti pẹ ti wọn ti n gbe pẹlu Dogo Gide, nipa Ileri rẹ lati maa daabo bo wọn kuro lọwọ awọn ikọ agbebọn ti kii jẹ ki wọn raaye ṣiṣẹ lori oko.

Iroyin taa ri gbọ ni wi pe, Gide lo pada wa silu rẹ ni ipinlẹ Zamfara lẹyin ti awọn oṣiṣẹ ologun ilẹ Naijiria doju ija kọ ọ, ti wọn si ba ile rẹ jẹ.

BBC tun gbọ wi pe, lẹyin ipadabọ rẹ lo ṣeleri lati maa pese aabo fun awọn agbẹ naa, bẹẹ lo ṣekilọ fun awọn ikọ aṣakọlu yooku wi pe ki wọn jawọ ninu iṣẹ ibi wọn, bi bẹẹ kọ yoo ṣe ipalara fun wọn.

Eeyan kan to n gbe nilu naa, tẹwiaju ṣalaye fun BBC pe, apa ibi kan to n jẹ Babbar, ilu Doka nijọba ibilẹ Maru ni Dogo Gide fi ṣe ibugbe tẹlẹ tẹlẹ, ko to dii pe awọn obi rẹ bẹ ẹ lati pada si ipinlẹ Zamfara lẹyin ti awọn Ọmọgun ilẹ Naijiria kọju ija si i.

O tọka sii bi okunrin naa ti n daabo bo wọn lati igba to ti pada de, ati bi awọn agbẹ ti n da oko wọn lọ laisi wahala.

Bakan naa, lo mẹnuba bi awọn agbẹ ni awọn ilu min bi i Taketa, Magami, Madaba, Kabasa, Yarzega, Sabon, Kura ati Munhaye ti n ṣiṣẹ tọsan toru lori oko wọn laisi ifoya gẹgẹ bi wọn ti n ṣe tẹlẹ.

Ẹlomin ninu awọn olugbe ọhun tun sọ fun BBC pe, awọn ọmọ wọn ti lanfaani ati rin kaakiri agbegbe naa pẹlu alaafia, ni paapa julọ awọn ibi ti wọn ko lee de ni nkan bi ọdun marun un sẹyin ni wọn ti bẹrẹ sini de lasiko yii.

Olugbe ọhun ko sai mẹnuba wi pe, gbogbo awọn aṣakọlu to maa n dooru mu wọn tẹlẹ lo ti sa kuro pata pata.

O ṣalaye wipe Dogo Gide ti saaju sọ fun wọn pe, kii ṣe owo wọn ni oun fẹ, ṣugbọn nigba ti wọn beere boya o ti ronu piwada, o ni, ko sọ pato fun wọn nipa ipinu rẹ.

Ẹwẹ, Dogo Gide ṣalaye fun wọn pe, bi aabo to nipọn yoo tiwa lagbegbe naa lo jẹ oun logun, leyi to fa igbesẹ rẹ, ati wipe ki gbogbo agbẹ pada sori oko wọn, kiwọn si maa ba kara kata wọn lọ laisi ibẹru.

Ẹ jẹ́ ká wo sààkùn ibi tí igbesẹ Dogo Gide yóò forí ti si

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkunrin oṣiṣẹ oniroyin kan to n jẹ Mannir Fura Girke, to ṣewadi bọrọ naa, sọ wi pe iyalẹnu gbaa ni ipunu Dogo Gide jẹ fun awọn ara oke oke ọya ni orilẹ ede Naijiria, leyi ti wọn pe ni igbesẹ to wu yi.

Ṣugbọn, eyi nilo ki awọn alaṣẹ farabalẹ lati mọ otitọ to ba wa nidi ọrọ naa, nitori ati mọ boya lododo ni ọkunrin naa ti ronu piwada pata pata kuro ninu iṣẹ aṣakọlu to n ṣe teleri.

Ipenija aiseto eto aabo lapa Ariwa ilẹ Naijiria, lo ti mu ẹbu ẹyin ba ọpọlọpọ ẹka nibẹ, bi i ẹka eto ọgbin ti wọn awọn eeyan agbegbe naa mọ daada.

Ọpọlọpọ awọn ilu to wa nibẹ ni awọn agbegbon ati awọn aṣakọlu ti da awọn agbẹ lọwọkọ dida oko wọn, nipa bi wọn ti n kọlu wọn lemọ lemọ ati bi ba ere oko wọn jẹ.

Bakan naa ni wọn fi tipa tipa mu ki awọn eeyan naa san owo ori.

Lẹyin o rẹyin, iroyin jade nipa bi Dogo Gide tii ṣe ọkan lara awọn afurasi agbebọn, ti yi pada lati maa daabo bo awọn agbẹ kuro lọwọ awọn aṣerubalu nipinlẹ Zamfara lo jẹ igbesẹ ọtun lapa ibẹ.