Wo ìdí tí Ààrẹ Ruto fi gbá rìfáàsì lóri òfin owó orí lẹ́yìn ìwọ́de tó pa ọ̀dọ́ 22 ní Kenya

William Ruto

Oríṣun àwòrán, Reuters

    • Author, Basillioh Rukanga
    • Role, BBC News, Nairobi

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Kenya, William Ruto ti yí ohùn padà lórí àbá láti mú àlékún bá owó orí èyí tó ti ń fa rògbòdìyàn ní orílẹ̀ èdè náà láti ọjọ́ Ìṣẹ́gun.

Nígbà tí Ruto ń bá àwọn aráàlú sọ̀rọ̀ lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹfà, ọdún 2024 ní Nairobi, olú ìlú orílẹ̀ èdè Kenya ló ti kéde ìpinnu pé àwọn kò ní mú àlékún bá àwọn owó orí náà mọ́.

Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn táwọn ọ̀dọ́ bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de láti tako ìgbésẹ̀ ìjọba láti mú àlékún bá owó orí.

Ruto ní òun ti ṣetán láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ lẹ́yìn tí ìwọ́de náà ti ṣokùnfà ikú àwọn ọ̀dọ́ méjìlélógún.

Ó ní òun kò ní buwọ́lu àbá náà dòfin.

“Lẹ́yìn tí mo ti ṣàgbéyẹ̀wò gbogbo àwọn awuyewuye tó ń wáyé lórí àbá ìsúná láti mú àlékún bá owó orí, tí mo sì tẹ́tí sí àwọn èèyàn Kenya tí wọ́n ní àwọn kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú àbá ìsúná náà.

“Mo ti gbà, mi ò ní buwọ́lu àbá náà, a sì máa yọ ọ́ kúrò nínú èròńgbà wa. Àwọn èèyàn ti sọ̀rọ̀.”

Ó tẹ̀síwájú pé òun máa túnbọ̀ máa tẹ́tí sáwọn ọ̀dọ́ láti mọ nǹkan tí wọ́n fẹ́.

Bákan náà ló ṣo pé ó jẹ́ ohu ìbànújẹ́ fún òun pé àwọn ọ̀dọ́ kan pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìwọ́de náà nítorí kìí ṣe ohun tó yẹ kó wáyé rárá.

Oluwọde ni Kenya

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ifẹhonuhan lori ofin kan ti ijọba Kenye buwọlu ti gba eeyan marun un, ti abala apa ile igbimọ aṣofin si gba ina lasiko nti awọn oluwọde tu sita.

Awọn oluwọde ni ofin naa yoo jẹ ki wọn san owo ori ni tipatipa eyi to n fa nira fun ọpọ araalu, ti ọpọ okowo si ti dẹnu kọlẹ nitori bi eto ọrọ se ri bayii, ti ọpọ ko ri ọwọ ri lọ sẹnu.

Ọlọpaa yin bọn ṣawọn oluwọde lọjọ Isẹgun, eyi to fa bi ọpọ eeyan ṣe jade laye, ti awọn mii si farapa yanayana.

Ijọba ti juwọ diẹ silẹ ninu awọn ofin na sugbọn awọn oluwọde fẹ ki ijọba juwọ ofin naa lẹ patapata.

Orisun ofin to fa ifẹhonuhan

Ijọba kọkọ fowo toto ida mẹrindinlogun(16%) le burẹdi ati ida mẹdọgbọn(25%) owo sori ororo ounjẹ.

Bakan naa ni ijọba n gbero n lati fowokun owo ti o ba wọn fowo ransẹ si eeyan mi ati owo ori lori ọkọ, to jẹ ida 2,5%.

Ni adehun si ifẹhonuhan naa, ijọba ni awọn yoo juwọle awọn ofin naa.

Awọn onimọ niluu Kenya ni igbesẹ ijọba lati fowo kun owo ori jẹ eyi ti ko bo jumu pẹlu bii nnkan se ri lasiko ti eto ọrọ aje mẹhẹ.

Pẹlu ofin yii, awọn ọmọde to jẹ obinrin ko ni ni anfani lati ri owo ra paadi nnkan oṣu.

Tẹlẹ pupọ awọn ọmọge yii ko ni anfani lati ra paadi yii nitori bi nnkan se ri lọwọ lorilẹede Kenya.

Ki lo fa ifẹhonuhan?

Awọn oluwọde ọdọ ti ọpọ mọ si ‘Gen Z’ ti yabo ile igbimọ aṣofin niluu Nairobi ti i ṣe olu ilu orilẹede Kenya.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn ọdọ oluwọde naa kọju ija sawọn ọlọpaa ti wọn si ya wọ ile aṣofin niluu Nairobi.

Awọn ileeṣẹ tẹlifisan kan ṣafihan bi awọn oluwọde ṣe n gbe ifẹhonuhan lọ si ile aṣofin laarin gbungbun ilu Nairobi.

Ki lo de ti awọn oluwọde se n binu?

Bo ti le jẹ pe ijọba ti juwọ diẹ ninu awọn ofin, awọn ofin si wa bii ọwọn gogo owo ori lori kiko nnkan wọle.

Sugbọn ariwo lori ofin n gboro si, ti awọn araalu Kenya si n binu si ijọba pe awọn ko gba ero araalu ro.

Ki ni yoo ṣẹlẹ bayii.

Ni bayii ti ofin ti kuro ni ile igbimọ aṣofin, Aarẹ ni lati buwọlu laarin ọjọ mẹrinla tabi ko fi ranṣẹ pada si ile igbimọ aṣofin pe ki wọn se atunṣe.

Ijọba tun le gbe igbesẹ lati le pẹtu si awọn araalu .