Ṣé lóòtọ́ ni pé wọ́n ń ta NIN àti BVN àwọn ọmọ Naijria ní N100 lórí ayélujára? Ohun tí a mọ̀ rèé

Kaadi idanimọ NIN

Oríṣun àwòrán, NATIONAL IDENTITY MANAGEMENT COMMISSION

Lọsẹ to kọja yii, ajọ kan ti ki i ṣe ti ijọba, Paradigm Initiative, kede pe awọn ra nọmba idanimọ NIN to jẹ ti Minisita ibaraẹnisọrọ, ọgbọn atinuda ati ọrọ aje lori ayelujara,Bosun Tijani, ni ọgọrun-un kan naira pere.

Ajọ naa ṣalaye pe ko si aabo lori awọn nọmba pataki to ni i ṣe pẹlu igbesi aye, iṣuna ati jijẹ ọmọ Naijiria, iyẹn NIN ati BVN.

Wọn ni ti ọgọrun-un naira ba le ra nọmba NIN odidi minista lori ayelujara ni Naijiria, o jẹ pe ewu n bẹ loko longẹ gidi fun araalu lasan.

Yatọ fun ti Bosun ti wọn lawọn ra yii, Ọgbẹni Gbenga Sesan, olori ajọ Paradigm sọ pe awọn tun ra ti Ọmọwe Vincent Olatunji to jẹ ọga nipa aṣiri lori ayelujara ni iye kan naa.

O ṣalaye pe awọn ri tifun-tẹdọ nọmba NIN awọn ọmọ Naijiria rẹpẹtẹ ra loju opo ayelujara ọhun.

O ni oju opo kan ti wọn n pe ni ‘AnyVerify.com.ng’ ni awọn kan ti n ta nọmba aṣiri awọn ọmọ Naijiria ni ọgọrun-un kan naira pere.

Eyi to n tọka si pe ohun ti araalu ro pe o bo gẹgẹ bi nọmba aṣiri, gbangba lo wa lori opo naa. Ati pe beeyan ba ti ni ọgọrun-un kan naira lọwọ, abuṣe buṣe.

Iru nnkan wọnyi n tẹ ẹtọ to yẹ ko bo aṣiri eeyan loju mọlẹ ni bi ajọ naa ṣe wi.

Wọn ni ewu nla lo wa nibẹ fun ọmọ Naijiria kọọkan ati ọrọ aje wa lapapọ.

‘’Ki i ṣe awọn ọmọ Naijiria lo wa nidii ọrọ yii, nitori a le fidi ẹ mulẹ pe awọn nnkan yii ni i ṣe pẹlu NIMC, a si ni ẹri. ‘’A ra NIN Tunji Bosun, minisita ibaraẹnisọrọ,ọgbọn atinuda ati ọrọ aje lori ayelujara, ati ti Ọmọwe Vincent Olatunji ni ọgọrun-un kan naira pere.’’

Kí ni Bosun Tijani wí nípa NIN rẹ̀ tí wọ́n ní wọ́n rà lówó pọ́ọ́kú lórí ayélujára?

Nigba to n fesi si iṣẹlẹ naa loju opo X, Ọmọwe Bosun Tijani ti i ṣe minisita fun ibaraẹnisọrọ, ọgbọn atinuda ati ọrọ aje lori ayelura lorilẹde yii, sọ pe ohun ti fi iṣẹlẹ naa to Minisita fun ọrọ abẹle, Olubunmi Tunji-Ojo, leti.

Bosun ti ko sọ pe ajọ naa n sọ otitọ tabi wọn n parọ, ṣalaye pe, oun ti sọ iṣẹlẹ naa fun alajọṣiṣẹpọ rẹ lẹka to n ri si ọrọ idanimọ, National Identity Commission (NIMC), "mo si mọ pe ileeṣẹ rẹ ti bẹrẹ iṣẹ lori ọrọ naa".

Bakan naa lo ni ẹka Nigeria Data Protection Commission (NDPC), to wa labẹ minisiri oun ti bẹrẹ iwadii lori ohun ti ajọ Paradigm sọ.

Ọmọwe Bosun tun sọ pe o ṣe pataki lati ni ẹka kan ti yoo maa ri si bi araalu yoo ṣe maa gbadun lilo ayelujara, ti awọn ẹka kọọkan yoo si maa ni akọsilẹ, ibaraẹnisọrọ, ki aabo tun le fẹsẹ mulẹ si lori afẹfẹ.

Ṣaa, ọrọ yii ti di ohun ti awọn ọmọ Naijiria n gba bii ẹni gba igba ọti, kaluku n sọ ero rẹ lori ipo ti aabo nnkan aṣiri lori ayelujara wa lorilẹede yii.