Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé fi orúkọ Israel àti Hamas sínú "ìwé orúkọ àwọn ẹlẹ́sín àti ẹlẹ́lẹ́yà” fún títẹ ẹ̀tọ́ ọmọdé lójú mọ́lẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Amira Mhadhbi
- Role, BBC Arabic
Àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, United Nations, UN ti fi orúkọ àwọn ọmọ ogun orílẹ̀ èdè Israel àtàwọn ikọ̀ alákatakítí ẹ̀sìn Islam ní Palestine sára orúkiọ àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n huwà tako ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé lásìkò ogun èyí tí wọ́n ń pè ní “list of shame”.
Nínú àtẹ̀jáde ọlọ́dọọdún lórí ipa ogun àtàwọn ọmọdé tí UN gbé jáde látọwọ́ akọ̀wé àgbà rẹ̀, Antonio Guterres ni wọ́n ti ṣàgbéjáde orúkọ náà.
Lọ́jọ́ Kẹtàlá, oṣù Kẹfà ọdún 2024 ni wọ́n ṣàgbéjáde ìjábọ̀ lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ oṣù Kìíní sí oṣù Kejìlá ọdún 2023.
Ìgbìmọ̀ ètò ààbò UN yóò jíròrò lórí ìjábọ̀ náà lọ́jọ́ Kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹfà.
“Ní ọdún 2023, àwọn ìwà ipá lórí àwọn ọmọdé pọ̀ púpọ̀ ju bó ṣe yẹ lọ pẹ̀lú àlékún ìdá mọ́kànlélógún.
“Ṣíṣekúpa àwọn ọmọdé tún lékún pẹ̀lú ìdá márùndínlógójì,” ìjábọ̀ náà sọ.
Ìjábọ̀ ọdún 2024 ní Israel àtàwọn ẹkùn tí ogun tí ń wáyé ní Palestine wà lára àwọn ibi tí wọ́n ti tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú mọ́lẹ̀ jùlọ.
Àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n kà sí Israel lọ́rùn
UN ní kò ní dín ẹ̀sùn 5,698 tó fìdí múlẹ̀ tó wà lọ́rùn ọmọ ogun Israel nígbà tí 116 wà lọ́rùn Hamas Izz al-Din al-Qassam Brigades, tí 21 sì wà lọ́rùn ikọ̀ ọmọ ogun alákiatakítí ẹ̀sìn Islam Palestine al-Quds Brigades.
Ìjábọ̀ náà ní àwọn ẹ̀sùn 2,051 míì ni àwọn ń ṣe ìwádìí rẹ̀ lọ́wọ́.
Àtẹ̀jáde UN náà ní àwọn ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé
- àwọn ọmọdé Palestine 2,267 ni wọ́n pa ní Gaza láàárín ọjọ́ Keje oṣù Kẹwàá sí ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Kejìlá ọdún 2023 pẹ̀lú àwọn àdó olóró tí àwọn ológun Israel wọ́n jù sílẹ̀ láàárín ibi tí àwọn aráàlú pọ̀ sí.
- Pé wọ́n pa àwọn ọmọdé Israel mẹ́tàlélógójì – ní orilẹ̀ èdè Israel nígbà tí Hamas ju àdó olóró sí Israel lọ́jọ́ Keje oṣù Kẹwàá
- Ikọ̀ ọmọ ogun Hamas Izz al-Din al-Qassam Brigades jí àwọn ọmọdé Israel mẹ́tàdínláàdọ́ta gbé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ
- ọmọ ogun Israel fi àwọn ọmọdé Palestine 906 sí àhámọ́
- ọmọ ogun Israel ṣe ìkọlù 371 sáwọn ilé ẹ̀kọ́ àtàwọn ilé ìwòsàn
Ikọ̀ ọmọ ogun Hamas Izz al-Din al-Qassam Brigades ṣèkọlù sáwọn ilé ìwòsàn àti ilé ẹ̀kọ́ Israel
Àwọn ẹ̀sùn mìíràn ni pé wọ́n ń pa àwọn ọmọdé àti pé wọn kò fàyè gba àwọn ọmọdé láti rí nǹkan ìbojú àánú gbà.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kí ni “ìwé àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ẹlẹ́yà” àti pé orúkọ àwọn wo ló wà níbẹ̀?
Ní ọdún 2001 ni ìgbìmọ̀ ààbò UN 1379 rọ akọ̀wé àgbà UN láti ṣàfihàn àti ṣe àkójọ orúkọ àwọn orílẹ̀ èdè tó máa ń lo àwọn ọmọdé láti jagun.
Láti ìgbà náà ló ti máa ń wà nínú ìjábọ̀ akọ̀wé àgbà UN lọ́dọọdún.
Àwọn ẹ̀sùn márùn-ún tí wọ́n ní orílẹ̀ èdè bá hù orúkọ rẹ̀ máa wà lára àwọn tó ń huwà ipá sáwọn ọmọdé ni:
- Lílo àwọn ọmọdé láti fi jagun
- Pípa àwọn ọmọdé
- Lílo àwọn ọmọdé fún ìbálòpọ̀
- Ṣíṣe ìkọlù sáwọn ilé ẹ̀kọ́ àti ilé ìwòsàn
- Jíjí àwọn ọmọdé gbé
Bákan náà ni wọ́n ní orílẹ̀ èdè tí kò bá jẹ́ kí àwọn aráàlú àtàwọn ọmọdé rí ohun ìbójú àánú woni gbà náà ṣẹ̀ sófin.
Lára àwọn tó wà nínú orúkọ náà ni Boko Haram, Taliban àti àwọn alákatakítí ẹ̀sìn Islam.
Ọdún tó kọjá ni wọ́n fi Russia sára wọn.

Israel fèsì
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ikọ̀ Hamas àtàwọn alákakítí ẹ̀sìn Islam kò ì tíì sọ̀rọ̀ lórí àtẹ̀jáde UN yìí, orílẹ̀ èdè Israel ní ìwà àìtọ́ ni UN hù.
Ní ọjọ́ Keje, oṣù Kẹfà ni olórí oṣìṣẹ́ sí akọ̀wé àgbà UN, Courtenay Rattaray sọ fún aṣojú Israel sí UN, Gilad Erdan níbi ìpàdé kan pé àwọn máa fi òrúkọ àwọn ọmọ ogun Israel sára àwọn tó ń tẹ ẹ̀tọ́ ọmọdé lójú mọ́lẹ̀.
Agbẹnusọ UN, Stephane Dujarric ní ìdí tí wọ́n fi máa ń sọ fún àwọn orílẹ̀ èdè kalẹ̀ ni fún wọn láti mọ̀ ṣáájú àti láti dènà àhesọ.
Àmọ́ Erdan sọ fún Rattaray nínú fídiò kan tó fi sórí ayélujára pé ìwà àìtọ́ ni wan fẹ́ hù náà àti pé wọ́n fẹ́ kan irin mọ́ Hamas lápá ni.
Olóòtú ìjọba Israel, Benjamin Netanyahu nínú àtẹ̀jáde kan ní UN ti darapọ̀ mọ́ àwọn tó ń ṣe àtìlẹyìn fún àwọn Hamas apànìyàn àti pé àwọn ọmọ ogun Israel wà lára àwọn ọmọ ogún tó ní ìwà ọmọlúàbí jùlọ lágbàáyé.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Kí ni ipa tí orúkọ yìí ní?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Èròńgbà ìjábọ̀ yìí ni láti ṣàfihàn nǹkan tí àwọn ọmọdé ń kojú àmọ́ kò ì tíì sí òfin tó dè é.
Àgbà onímọ̀ nípa ìwádìí ní Oxford Institute for Ethics, Law and Armed Conflict, Emanuela-Chiara Gillard sọ fún BBC pé fífi orúkọ àwọn orílẹ̀ èdè sínú ìjábọ̀ náà kàn jẹ́ láti pariwo fáráyé lásán nítorí kò sí nǹkankan ti yóò tẹ̀yìn rẹ̀ jáde fún wọn.
Ó ní ó le ní ipa lórí bí àwọn orílẹ̀ èdè ṣe le fún Israel ní ohun ìjà nítorí wọ́n lè gbàgbọ́ pé Israel kò tẹ̀lé òfin àmọ́ kò ní ìjìyà kankan nínú.
UN ní ikọ̀ agbáṣùmọ̀mí ni Israel, UK àti US ka Hamas àtàwọn alákatakítí ẹ̀sìn Islam Palestine kún nítorí náà ìjábọ̀ àwọn kò yí ipò yìí padà.
Kí wọ́n tó lè yọ orúkọ ẹgbẹ́ tàbí orílẹ̀ èdè kúrò lára àwọn tó ń huwà ipá sáwọn ọmọdé, orílẹ̀ èdè náà máa jíròrò pẹ̀lú UN lórí àwọn ọ̀nà tí wan máa gbà láti ri pé wọn ò ṣe àwọn nǹkan tí wan fẹ̀sùn rẹ̀ làn wọ́n mọ́.















