Àwọn gómìnà láti Àríwà sọ ọ̀nà tí wọ́n fẹ́ gbà yanjú ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní Naijiria

Oríṣun àwòrán, KATSINA STATE GOVERNMENT
Awọn gomina meje ni apa guusu ariwa lorilẹede Naijiria ti kede sita pe awọn yoo siṣẹ papọ lati gbe ogun ti eto aabo to mẹhẹ ni apa guusu ariwa orilẹede Naijria.
Awọn Gomina sọ eyi lasiko ipade, ti wọn si gbagbọ pe igbesẹ yii yoo pese anfani fun ilọsiwaju ọrọ aje ati ọpọ araalu ni yoo jẹ anfani naa.
Bakan naa, awọn Gomina yii ni awọn mọ pe ọpọ ẹmi ati dukia lo ti sọnu nitori eto aabo to mẹhẹ ni ipinlẹ wọn.
Ipade ọlọjọ meji waye ni ipinlẹ Katsina pẹlu ajọsepọ United Nations Development Programme ati ijọba orilẹede Germany ati Norway.
Awọn Gomina ni agbara wa lati pese ohun iranwọ lati mu aye dẹru fun awọn ara ipinlẹ.
Nigba to n sọrọ, Gomina ipinlẹ Katsina, Dikko Radda to jẹ olugbalejọ ipade naa ati alaga ẹgbẹ awọn Gomina ni apa ariwa ni ọpọ awọn Gomina ni ẹkun na lo bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lati gbe ogun ti eto aabo to mẹhẹ.
“Lakọkọ, a mọ pe a ni iṣoro eto aabo ni agbegbe yii, idi ree a ti fi fọwọsowọpọ lati gbe ogun ti iṣoro yii, ti a si ti ẹsẹ ile bọ.
“A ti ba arawa sọ otitọ ọrọ nipa awọn aṣiṣe wa ati bi a ṣe le pese ọna abayọ.
“Ajọ UN sọ fun wa bi a ṣe le wa ojutu si iṣoro aabo. A ti seto awọn agbofinro ni ipinlẹ wa lati koju iṣoro aabo yii.
“A n wo eto ọgbin naa, to se anfani fun eto ọrọ aje wa, ti yoo si tun pese iṣẹ fun aaalu”
Gomina Radda fogun rẹ gba ori pe awọn Gomina ti ṣetan fọwọsowọpọ lati jẹ ki gbogbo ero wọn wa si imusẹ.
O wa kesi awọn eeyan jakanjakan ni ipinlẹ naa lati sugba ijọba lati jẹ ki gbogbo ero yii wa si imusẹ.
Awọn Gomina to wa ni ijoko ni Gomina Umar Namadi lati ipinlẹ Jigawa ati Dauda Lawal lati Zamfara.
Awọn igbekeji Gomina lo soju ipinlẹ Gomina ipinlẹ Sokoto ati Kaduna, ti akọwe ijọba ipinlẹ Kano si soju Gomina Kano.












