'Mi o mọ adùn ìgbéyàwó rárá, nítorí bí mo ṣe fẹ́ ọkọ́ mi ló ti wọ inú àìsàn tó paá'

Àkọlé fídíò,
'Mi o mọ adùn ìgbéyàwó rárá, nítorí bí mo ṣe fẹ́ ọkọ́ mi ló ti wọ inú àìsàn tó paá'

Ọjọ yii jẹ ọjọ ti aj agbaye ya sọtọ lati sọ nipa igbeaye awọn obinrin ti ọkọ wọn ku, idojukọ wọn, ati ọna ti awujọ le gba ran wọn lọwọ.

Fun ti ayajọ ọdun 2024, BBC ba awọn obinrin to di opo nigba ti wọn wa ni ọdọ, sọrọ lori iriri wọn.

Ẹnikan lara wọn, Arabinrin Adesina Adeola, sọ pe oun ko ni anfaani lati jẹ adun igbeyawo rara, nitori pe ni kete to loyun fun ọkọ rẹ, ni ọkunrin naa bẹrẹ aisan.

Aisan ọkọ Adeola ni wọn tọju titi di ọdun 2019 to ku.

“Lati igba yẹn, emi nikan ni mo n tọju ọmọ mi lai si iranlọwọ.”

Ẹnikeji, sọ pe inu oyun ni oun wa nigba ti ọkọ oun ku.

Olabisi Kuku, ti ọkọ tiẹ naa ku sọ pe ijamba ọkọ ni ọkọ oun ni, to si fi ẹsẹ pa.

“Kokoro tetanus ti wọn lo wọ inu ọgbẹ ọkọ mi, lo pa a.

“Ọjọ kẹjọ ti wọn sin ọkọ mi, ni mo bi ọmọ mi.”

Bakan naa lo ṣalaye pe ọdun kan gbako ni oun lo nileewosan lẹyin iṣẹlẹ naa, debii pe ẹbi ati ọrẹ tọrọ baara lori ayelujara nitori ilera rẹ.

Arabinrin Kuku sọ pe oun ko ri iranlọwọ kankan lati igba naa.

Ọdun 2022 ni ọkọ rẹ ku.

O sọ pe nini igbagbọ ninu Ọlọrun ṣe pataki fun awọn obinrin to ba jẹ opo.