Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba tún fẹ́ rọ Sultan ìlú Sokoto lóyè? Ohun tí a mọ̀ nípa rẹ̀ rèé

Sultan Muhammad Sa'ad Abubakar

Oríṣun àwòrán, others

Laipẹ yii lawọn iroyin kan n lọ kaakiri pe ijọba ipinlẹ Sokoto n gbere lati rọ Sultan ti ilu Sokoto, Muhammad Saád Abubakar kẹta loye.

Iroyin yii mu ọpọ lominu nitori pe irufẹ igbesẹ yii ṣẹṣẹ waye ni ipinlẹ Kano ni nibi ti ijọba ipinlẹ to wa nibẹ ti gbọn Emir Ado Bayero yọ kuro ni ipo Emir ilu Kano eleyi to si ti n fa ọpọlọpọ wahala ati ipẹjọ nibẹ.

Amọṣa o, ijọba ipinlẹ Ṣokoto ti sọ pe irọ ati ahesọ ti ko lẹsẹ nilẹ ni iroyin naa.

Ninu atẹjade kan eyi ti wọn fi sita ni ọjọ Iṣẹgun, agbẹnusọ fun ijọba ipinlẹ Sokoto, Abubakar Bawa, ṣalaye pe irọ lasan ti ko lẹsẹ nlẹ ni iroyin naa. O ni awọn to fẹ pa ina ajọṣepọ alaafia to wa laarin ijọba ipinlẹ naa ati igbimọ aṣiwaju awọn ẹlẹsin musulumi lo n tan iroyin irọ naa ka.

Iroyin yii bẹrẹ bẹrẹ ẹsun ti igbimọ kan to n ja fun ẹtọ awọn musulumi, MURIC gb ekalẹ pe ijọba ipinlẹ Sokoto n gbero lati yọ Sultan nipo.

Lẹyin eyi, igbakeji aarẹ lorilẹede Naijiria, Kashim Shettima pẹlu tẹnumọ ọ ni ọjọ Aje pe ipo Sultan jẹ ipo ti o kun fun ọpọ ọla ati ọwọ nitori naa abo to peye gbọdọ wa fun un.

Igbakeji Ààrẹ Shettima n ki Sultan Muhammad Sa'ad Abubakar III

Oríṣun àwòrán, x/Kashim Shettima

Ninu ọr ọrọ to sọ nibi ipade apero kan to da lori kudiẹkudiẹ ọr abo ni Naijiria, eyi to waye ni Katsina, Shettima ṣalaye pe pataki ni ipa ti Sultan n ko eleyi to si rọ igbakeji gomina ipinlẹ Sokoto, Idris Gobir to wa nibi eto naa pe ko rii daju pe onyẹ kan ko yẹ aga naa ati ipo Sultan gẹgẹ bi aṣiwaju awọn ẹlẹsin musulumi.

Ijọba ipinlẹ Ṣokoto tọka si ẹsun ti ẹgbẹ MURIC fi kan an nipa yiyọ Sultan Sokoto nipo naa gẹgẹ bi eyi ti ko lẹsẹ nilẹ, bẹẹni wọn fi da ij awọn musulumi loju pe ko si eto kankan lati rọ Sultan loye.