Iye ìgbà tí kọ́lẹ́rà ti jà ní Naijiria, tó sì mú ẹ̀mí lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Láti bíi ọ̀sẹ̀ mélòó kan sẹ́yìn báyìí ni àìsàn kọ́lẹ́rà èyí tí Yorùbá máa ń pè ní àìsàn onígbá méjì tún ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣọṣẹ́ látàrí bí àjàkálẹ̀ àìsàn náà ṣe tún gbòde.
Kọ́lẹ́rà jẹ́ àìsàn tó máa ń mú èèyàn máa yàgbẹ́ gbuuru, èébì àti kí omi ara máa gbẹ pátá.
Ó máa ń yára gbẹ̀mí èèyàn tó sì ti ṣokùnfà ikú ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́nu ìgbà tí àjàkálẹ̀ ààrùn náà bẹ̀rẹ̀ láìpẹ́.
Níbi ti ọwọ́jà àìsàn náà le tó lásìkò yìí, àjọ tó gbógunti àjàkálẹ̀ àìsàn ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, NCDC ti kéde rẹ̀ bí wàhálà ńlá tó nílò àmojútó gidi.
Oúnjẹ àti omi tí kò bá ní ìmọ́tótó ni àwọn onímọ̀ sọ pé ó máa ń fa kọ́lẹ́rà.
Kòkòrò àìfojúrí Vibrio cholera ni wọ́n ló máa ń fà á, tí èèyàn tó bá lùgbàdì àìsàn yìí sì máa ń ya àwọn kòkòrò yìí mọ́ ìgbẹ́.
Àìsàn kọ́lẹ́rà máa ń yára tàn kalẹ̀, tó jẹ́ pé tí èèyàn kan bá ti ni, ó ṣeéṣe kí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ara ẹni náà ko.
Kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àjàkálẹ̀ àìsàn yìí yóò máa tàn ní Nàìjíríà, láti ọdún pípẹ́ ni orílẹ̀ èdè yìí ti máa ń ní àjákalẹ̀ àìsàn yìí pàápàá lásìkò òjò.
Èyí ló mú wa ṣe àkójọ àwọn ìgbà tí àjàkálẹ̀ àìsàn ti ṣọṣẹ́ ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àjàkálẹ̀ kọ́lẹ́rà àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà (1970 – 1972)

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀, láàárín ọdún 1970 sí 1972 ni àìsàn kọ́lẹ́rà kọ́kọ́ fojú hàn ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti ọdún 1817 ni wọ́n ti kọ́kọ́ ní àkọ́ọ́lẹ̀ àìsàn ní àwọn orílẹ̀ èdè lẹ́kùn Asia àti ìlà oòrùn Áfíríkà.
Lẹ́yìn tí àjàkálẹ̀ àìsàn náà wáyé nígbà náà lọ́hùn-ún ló di ohun tó ń wáyé ní ọdọọdún pàápàá lásìkò òjò.
Lásìkò náà, bí àìsàn kọ́lẹ́rà yára tàn kálẹ̀ nítorí kò só àwọn kòtò ìdòmínu tó péye, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn èèyàn tó ní àǹfàní sí omi tó ṣe é bùmu bùẹ̀ kò wọ́pọ̀.
Àsìkò yìí gan ni olórin jùjú nnì, Ebenezer Obey fi àìsàn náà kọrin, tó sì rọ àwọn èèyàn láti máa wà ní ìmọ́tótó láti dènà lílùgbàdì àìsàn kọ́lẹ́rà.
Nítorí àìsí àkọ́ọ́lẹ̀ tó péye, a ò lè fìdí iye èèyàn tó lùgbàdì tàbí bá àìsàn náà lọ múlẹ̀ ní pàtó, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló pàdánù ẹ̀mí wọn sọ́wọ́ àìsàn kọ́lẹ́rà nígbà náà.
Àjọ National Library of Medicine nínú àkọ́ọ́lẹ̀ tí wọ́n ṣe ní lẹ́yìn ọdún 1991, kọ́lẹ́rà ti ṣọṣẹ́ ní ọdún 1992, 1995, 1996 àti 1997.
Ẹkùn àríwá Nàìjíríà ni àìsàn yìí ti máa ń wọ́pọ̀ jùlọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àkọ́ọ́lẹ̀ ní iléeṣẹ́ ètò ìlera ìpínlẹ̀ Kano ní àpapọ̀ èèyàn 5,824 ló lùgbàdì kọ́lẹ́rà láàárín ọdún 1995 sí 2001.
Ní ọdún 2010 ni àjàkálẹ̀ àìsàn kọ́lẹ́rà tún gbòde lẹ́kùn àríwá orilẹ̀ èdè Nàìjíríà bákan náà pẹ̀lú àkọ́ọ́lẹ̀ èèyàn 3,000 tó lùgbàdì rẹ̀, tí èèyàn 781 sì pàdánù ẹ̀mí wọn sí àìsàn onígbáméjì.
Láti ìgbà náà ni iye èèyàn tó ń lùgbàdì àìsàn kọ́lẹ́rà ti ń pọ̀si ní ọdọọdún.
Ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn rẹ̀, àjọ tó ń rí sí àjàkálẹ̀ àìsàn Nàìjíríà, NCDC ní èèyàn tí àwọn furasí pé ó lùgbàdì kọ́lẹ́rà ní Nàìjíríà ti lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún .
Láàárín oṣù Kìíní sí oṣù Keje ọdún 2021, NCDC èèyàn 3,604 ló jáde láyé nínú èèyàn 111,602 tó ní àìsàn kọ́lẹ́rà nígbà náà.
Ní báyìí tí àìsàn ti tún ń jà ràìnràìn, NCDC ní ìpínlẹ̀ mọ́kànlélọ́gbọ̀n, àti ìjọba ìbílẹ̀ 107 ni ọwọ́jà àìsàn kọ́lẹ́rà ti tàn dé.
Ẹ jẹ́ ka wà ní ìmọ́tótó, ká sì ṣọ́ra fún àwọn nǹhkan tó lè mú wa lùgbàdì àìsàn kọ́lẹ́rà.












