Kàyéfì! Òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè kú níbi tó ti ń dáhùn ìbéèrè nílé aṣòfin l'Abuja

Ile asofin Naijiria

Oríṣun àwòrán, National Assembly

Ọrọ di wo mi, ki n wo ọ nile igbimọ aṣofin niluu Abuja lọjọ Iṣẹgun, nigba ti oṣiṣẹ ajọ aṣọbode kan deedee ṣubu lulẹ, to si ku.

Iṣẹlẹ yii waye lasiko ti ọkunrin naa farahan niwaju igbimọ kan lati dahun ibeere.

Ile aṣofin sọ ninu atẹjade kan ti alaga igbimọ to wa fun eto iroyin, Akin Rotimi, fi sita pe "ojiji ni ọkunrin naa bẹrẹ aisan nigba to n dahun ibeere lọwọ ni bii aago kan ọsan".

O ni "ipaya nla ni iku oṣiṣẹ aṣọbode naa jẹ fun wa".

Ọgbẹni Rotimi sọ pe awọn oṣiṣẹ ileewosan to wa nile aṣofin gbiyanju lati doola rẹ, ṣugbọn ẹmi rẹ papa bọ.

Wọn ko darukọ ọkùnrin naa nitori a ti bọwọ fun ẹbi rẹ.

Botilẹ jẹ pe wọn ko sọ ohun to ṣeku paa, iroyin sọ pe ariwo "mo fẹ mu omi, mo fẹ mu omi" ni ọkùnrin naa pa ko too ṣubu lulẹ.