Ohun tí àwọn ìyàwó ilé àti àwọn tó ti kọ ọkọ ní láti mọ̀ kí wọ́n tó ó gba ìwé ìrìnnà tuntun

Aworan obinrin kan ati iwe irinna Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ajọ to n mojuto iwọle-wọde lorileede Naijiria, NIS ti sọrọ lori awuyewuye to n lọ lori ikanni ayelujara nipa awọn ohun ti obinrin to ti wa nile ọkọ yoo nilo ki wọn to le gba iwe irinna ilẹ Naijiria, tabi lati ṣe paṣipaarọ eyi ti wọn n lo tẹlẹ si tuntun.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn obinrin to ti wa nile ọkọ maa n ṣaniyan, ti wọn si maa n fi ẹdun ọkan wọn han lori awọn ohun ti ajọ NIS maa n beere lọwọ wọn, paapaa lati mu iwe irinna ọkọ wọn wa ko to di pe wọn gba iwe irinna tuntun.

Laipẹ yii ni obinrin kan jade sọrọ lori ikanni ayelujara, nibi to ti n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa, to si ni ko yẹ ko ri bẹẹ rara.

Obinrin naa fi ẹdun ọkan rẹ han lori igbesẹ to gbe lati tun iwe irinna rẹ ṣe, to si loun ko le tẹsiwaju mọ nigba toun de ipele lati ṣafihan iwe irinna ọkọ oun.

Eyi lo si waye lẹyin oṣu diẹ ti ajọ NIS ṣagbekalẹ oju opo ti awọn olugbe Naijiria ko nii nilo lati yọju sileeṣẹ wọn nigbakugba ti wọn ba fẹẹ gba iwe irinna wọn.

Ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2024, ajọ NIS sọ ọ sita wi pe awọn ti ṣagbekalẹ eto kan ti awọn to ba fẹẹ gba iwe irinna wọn ko nii nilo lati de ileeṣẹ wọn, ko to di pe wọn forukọ silẹ mọ, eyi ti wọn pe ni ‘contactless passport application system’.

Wọn ni oju opo ayelujara ni gbogbo eeyan yoo lọ lati fi orukọ silẹ, ika ọwọ wọn, ati aworan wọn silẹ.

Ajọ Immigration ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa ẹsun ti awọn eeyan fi kan wọn

“Mo ni iwe ẹri ọjọ ibi to ṣafihan iru ẹni ti mo jẹ. Awọn akọsilẹ to wa ninu kaadi idanimọ, NIN mi sọ irufẹ eeyan ti mo jẹ, ṣugbọn sibẹ nitori pe iwe irinna atijọ mi gbe orukọ ọkọ mi dani, mo nilo lati fi iwe irinna ọkọ mi silẹ, tabi ki n sọ nipa iru eeyan to jẹ? To ba jẹ pe mo ti kọ ọ silẹ nkọ? Njẹ eyi wa tunmọ si pe nko ki n ṣe ọmọ Naijiria?, IjeomaOgood lo beere ibeere yii lọwọ ajọ NIS loju opo ‘X’

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣugbọn ṣa, lẹyin oriṣiriṣi awuyewuye, ajọ NIS ti wa jade sita lati ṣalaye awọn ohun ti wọn lo ṣokunkun sawọn eeyan, paapaa nipa ẹsun ti wọn fi n kan wọn loju opo ‘X’.

Gẹgẹ bi alaye ti ajọ NIS ṣe, wọn jẹ ko di mimọ pe awọn obinrin ti wọn ti wa nile ọkọ ko nilo lati fi iwe irinna ọkọ wọn silẹ nigbakugba ti wọn ba fẹẹ gba iwe irinna wọn tuntun lati fi dipo eyi ti wọn n lo tẹlẹ, ti ọjọ ti lọ lori rẹ.

Ajọ NIS sọ pe kii ṣe ilana ileeṣẹ wọn, ati pe lati gba iwe irinna tuntun rọpo eyi ti ọjọ ti lọ lori rẹ nii ṣe pẹlu idanimọ awọn ohun to wa ninu iwe ẹri teeyan ba n lo.

“Ẹni lati mọ ni idaniloju wi pe awọn obinrin ti wọn ti ṣe igbeyawo ko nilo lati fi iwe irinna ọkọ wọn silẹ tabi sọ iru eeyan ti ọkọ naa jẹ ko to di pe wọn gba iwe irinna tuntun lati rọpo eyi ti ọjọ ti lọ lori rẹ. Ilana ti a fi lelẹ leyi,” ajọ NIS ṣalaye.

NIS tun fi kun alaye wọn wi pe ‘ohunkohun to ba ti kọja eyi, tunmọ si wi pe ko pe niyẹn.’

Ṣugbọn ajọ NIS sọ pe o ni awọn iwe kan ti awọn obinrin yoo nilo lati fi ṣe paṣipaarọ idanimọ wọn si orukọ ẹni ti wọn ba fẹ, iyẹn awọn to ti kọ ọkọ pẹlu awọn obi ti wọn fẹẹ gba iwe irinna fawọn ọmọ wọn.

Ajọ NIS sọ pe ọna mẹrin ọtọọtọ ni gbigba iwe irinna tabi lati gba tuntun rọpo eyi ti ọjọ lọ lori rẹ le gba waye.

Ṣugbọn gẹgẹ bi wọn ṣe ṣalaye siwaju, wọn ni ohun meji lo le fa ki awọn obinrin ti wọn ti wa nile ọkọ fi iwe irinna ọkọ wọn tabi kaadi idanimọ ijọba apapọ ti ọkọ wọn silẹ.

Awọn iwe ẹri ti obinrin nilo lati fi gba iwe irinna rẹ lẹyin to ba ti ṣegbeyawo

Ajọ NIS sọ pe awọn obinrin ti wọn ba ti ṣe igbeyawo, ti wọn si fẹ maa lo orukọ ọkọ wọn yoo nilo awọn iwe ẹri pataki kan, ko to di pe wọn gba iwe irinna wọn.

Awọn iwe ẹri naa ni wọn pe ni:

  • Iwe iroyin ti wọn ṣe lati fi ṣafihan wi pe wọn ti yi orukọ wọn pada si ti ọkọ wọn nitori igbeyawo
  • Iwe irinna ti obinrin naa n lo tẹlẹ
  • Iwe ẹri ti igbeyawo
  • Iwe irinna ti ọkọ n lo, tabi kaadi idanimọ ijọba apapọ (NIN) ti ọkọ
  • Kaadi idanimọ tijọba apapọ (NIN)
  • Iwe ẹri ti ijọba ibilẹ ti wọn bi wọn si
  • Iwe ẹri ọjọ ibi tabi iwe ẹri ọjọ ori

Awọn ohun ti awọn obinrin to ti kuro nile ọkọ yoo nilo lati fi ṣe paṣipaarọ iwe irinna wọn

Ajọ aṣọbode to n mojuto iwe irinna lọ sorileede miran, NIS sọ pe o ni awọn iwe ẹri kan ti awọn obinrin ti wọn ti kọ ọkọ wọn silẹ labẹ ofin yoo nilo bi wọn ba fẹẹ gba iwe irinna tuntun, tabi ṣe paṣipaarọ iwe irinna ti wọn n lo tẹlẹ si tuntun.

Wọn ni awọn iwe ẹri yii ni wọn yoo nilo lati fi yi orukọ wọn pa kuro ni ti ọkọ wọn ti wọn n lo, pada si orukọ baba wọn ti wọn n lo latilẹ.

Awọn iwe ẹri naa ni:

  • Iwe ẹri ile ẹjọ to ṣafihan wi pe lotitọ ni ile-ẹjọ ti pin wọn niya
  • Iwe irinna ti wọn n lo tẹlẹ
  • Iwe iroyin ti wọn ṣe lati fi yi orukọ pada
  • Newspaper publication to that effect
  • Kaadi idanimọ tijọba apapọ (NIN)
  • Iwe ẹri ti ijọba ibilẹ ti wọn bi wọn si
  • Iwe ẹri ọjọ ibi tabi iwe ẹri ọjọ ori

Awọn iwe ẹri ti awọn ọmọde yoo nilo lati gba iwe irinna wọn

Ajọ NIS sọ pe, fun awọn obi ti wọn ba fẹẹ gba iwe irinna lọ soke okun fun awọn ọmọ wọn, wọn nilo lati ni awọn iwe ẹri kan to ṣe pataki pupọ.

Lara awọn iwe ẹri naa ni:

  • Iwe aṣẹ ti awọn obi yoo tọwọbọ pe awọn fẹẹ ṣe e (Consent letter)
  • Iwe irinna awọn obi ọmọ naa
  • Kaadi idanimọ tijọba apapọ (NIN) ti ọmọ naa
  • Iwe ẹri ti ijọba ibilẹ ti wọn bi wọn si
  • Iwe ẹri ọjọ ibi tabi iwe ẹri ọjọ ori

Awọn ohun ti awọn iyawo ile ti wọn ko yi orukọ pada nilo lati tun iwe irinna tuntun gba

Ajọ NIS tun ṣalaye siwaju nipa awọn iwe ẹri ti awọn iyawo ile ti wọn ko yi orukọ wọn pada yoo nilo lati fi gba iwe irinna tuntun.

Awọn iwe ẹri naa ni:

  • Iwe irinna ti ọjọ ti lọ lori rẹ, eyi ti wọn n lo tẹlẹ
  • Kaadi idanimọ tijọba apapọ (NIN)
  • Iwe ẹri ti ijọba ibilẹ ti wọn bi wọn si
  • Iwe ẹri ọjọ ibi tabi iwe ẹri ọjọ ori
Iwe irinna Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi o ṣe le fi orukọ silẹ lati gba iwe irinna tuntun rọpo eyi ti ọjọ ti lọ lori rẹ

Ajọ NIS sọ pe awọn ọmọ Naijiria le gba iwe irinna tuntun lati rọpo eyi ti ọjọ ti lọ lori rẹ nipa nini oju opo NIS lori ẹrọ ibanisọrọ wọn, nigba ti wọn ba si ti ni oju opo (APP) yii, anfaani ti wa fun wọn lati fi orukọ silẹ, ati pe awọn eeyan tun le fi orukọ silẹ loju opo ayelujara (website) wọn.

Nigba ti wọn ba ti ni ikanni (App) naa, tabi ti wọn ti wa loju opo ayelujara wọn, ohun ti awọn to ba fẹẹ fi orukọ nilo lati ṣe ni pe ki wọn tẹle awọn alakalẹ ilana ti wọn fi sibẹ, lara rẹ ni:

Ṣiṣi oju opo ara ẹni (Create profile): Awọn to ba fẹẹ fi orukọ silẹ gbọdọ ni imeeli to n ṣiṣẹ loorekoore lati ṣe iforukọsilẹ

Wiwo boya wọn peregede (Eligibility check): Wọn yoo la idanwo rampẹ kọja lati mọ boya wọn le peregede lati ṣe iforukọsilẹ lati gba iwe irinna tuntun rọpo eyi ti ọjọ ti lọ lori rẹ.

Ṣiṣe idamọ awọn ẹri akọsilẹ (Identify details): Wọn yoo fi nọmba idanimọ ijọba apapọ (NIN) wọn silẹ, ati pẹlu nọmba to wa lara iwe irinna ti wọn n lo lati wo o.

Ṣiṣe akọsilẹ idanimọ ati fifi awọn iwe ẹri kikun silẹ (Personal information and document upload): Awọn oluforukọsilẹ yoo kọ gbogbo idanimọ wọn silẹ lawọn ibi to yẹ, bẹẹ si ni wọn yoo ko gbogbo iwe ẹri bii NIN, iwe-ẹri ọjọ ibi, iwe-ẹri ijọba ibilẹ ati awọn miran silẹ.

Titẹ ika (Biometric capture): Awọn oluforukọsile yoo nilo lati lo ẹrọ ibanisọrọ wọn lati ṣe ontẹ ọwọ wọn.

Sisan owo (Make payment): Wọn yoo san owo to yẹ lati pari gbogbo eto ati ilana naa.

Lẹyin gbogbo eyi ni wọn yoo ṣẹṣẹ fi ohun ti wọn ṣe ranṣẹ, ti wọn yoo si duro lati wo bo ṣe lọ.

Ajọ naa tun ṣalaye siwaju sii pe awọn yoo ṣe gbogbo eto iforukọsilẹ naa lọdọ wọn, ti wọn yoo si fi ranṣẹ si adirẹẹsi ti wọn ba silẹ lẹyin ti iṣẹ ba ti pari lati ọdọ wọn.

Bi o ṣe le forukọ silẹ fun iwe irinna Naijiria fun awọn to ti ṣegbeyawo ati awọn ọmọ

O le fi orukọ silẹ lati gba iwe irinna Naijiria loju opo ajọ ẹṣọ aṣọbode to n ri sọrọ iwe irinna nipa titẹlẹ ilana, iyẹn fun awọn to ba ṣẹṣẹ fẹẹ gba iwe irinna tun igba kọkọ, fun agbalagba ati fun awọn ọmọde:

Iwe idanimọ lati ileeṣẹ ijọba ibilẹ tabi iwe ẹri ti ipinlẹ tabi iwe ẹri idanimọ apapọ ti a mọ si National Identity Card.

Fun awọn oṣiṣẹ ijọba: Iwe apejuwe to ni nọmba igbanisiṣẹ, igba ati asiko to ti lo lẹnu iṣẹ ati ipo to wa lẹnu iṣẹ ninu.

Kaadi idanimọ ibi iṣẹ

Iwe iforukọsilẹ fun iwe irinna ti o ti pari

Iwe ẹri igbeyawo, nibi to ba ti yẹ

Iwe ẹri ọjọ ibi (Awọn ti wọn ba bi lati inu oṣu kejila, ọdun 1992 ni lati fi iwe ẹri ajọ to n mojuto ikaniyan ni Naijiria, NPC silẹ)

Ẹni ti ko ba ni iwe ẹri ọjọ ibi yoo lọ si kọọtu lati ṣe iwe, eyi ti kọmiṣanna eto ibura nile ẹjọ yoo buwọlu pẹlu aworan idanimọ pelebe

Iwe to ṣafihan owo sisan.