Ewé sunko! Babaláwo tó fẹ́ dán ògùn ayẹta wò balẹ̀ níléèwòsàn lẹ́yìn tó yìnbọn fúnra rẹ̀

Aworan Ismail Usman lori ibusun to wa ni ileewosan.

Oríṣun àwòrán, others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

“Iwadii ti bẹrẹ, ati pe Usman yoo foju ba ile-ẹjọ lori ẹsun lilo ibọn ati igbiyanju lati gba ẹmi ara rẹ labẹ iwe ofin Ariwa Naijiria to wa ni abala 231.”

Wọnyi ni ohun ti ileeṣẹ ọlọpaa ilu FCT, Abuja sọ lori Ismail Usman, babalawo kan ti iroyin sọ wi pe o yinbọn fun ara rẹ lasiko to n gbiyanju ati dan ijafafa ogun ayẹta kan to ṣe wo

Ọjọ kẹtalelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2024 ni wọn sọ pe Usman deede yinbọn funra rẹ ni abule Kuchibuyi, to wa ni olu ilu Naijiria lati dan oogun ayẹta ajẹbiidan to pada yiwọ wo, ṣugbọn ti nnan o pada ṣẹnu ire.

Bawo lo ṣe ṣẹlẹ

Iṣẹ babalawo pọmbele la gbọ pe Usman yan laayo niluu Abuja.

Ohun ti a gbọ ni pe niṣe ni Usman ṣẹṣẹ pese oogun abẹnugọngọ to n ṣiṣẹ fun ayẹta, lati le maa lo o loju ogun. Lẹyin to pari gbogbo etutu aṣọ ayẹta ọhun wo, ni wọn lo ibọn agbelẹrọ to ti ni nile mọlẹ, to si yin in funra rẹ nikun.

Ariwo ‘oro ooo, ẹ gba mi o’ ni wọn ni Usman mu bọ ẹnu nigba to rii pe oun ti fẹẹ gba euru jẹ lọwọ ẹbọra nibi to ti n pokaka iku nilẹ to wa.

Lara awọn adugbo la gbọ pe wọn sare ranṣẹ sawọn ọlọpaa to wa nitosi lati wa a wo Usman, ti wọn si ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun wọn.

Awọn ọlọpaa naa la gbọ pe wọn sare gbe Usman digbadigba lọ si ọsibitu lati doola ẹmi rẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti sọrọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Agbẹnusọ ọlọpaa niluu Abuja, Josephine Adeh, nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ jẹ ko di mimọ pe awọn ara agbegbe naa lo ranṣẹ ipe pajawiri si awọn.

O ni awọn ọlọpaa awọn ni ẹkun Byazhin Division lo sare lọ sibẹ lati gbe Usman digbadigba lọ si ọsibitu ijọba to wa ni Kubwa lati doola ẹmi rẹ.

Adeh fi kun ọrọ rẹ pe ọkunrin naa farapa gidigidi, idi ree ti wọn fi tare rẹ si ile iwosan Gwagwalada Specialist Hospital, nibi ti awọn dokita ti n ṣiṣẹ takuntakun lati doola ẹmi rẹ.

“Ọkunrin kan to n jẹ Shandam Michael lo ranṣẹ ipe pajawiri nipa Ismail Usman, babalawo kan to yinbọn funra rẹ lasiko to n gbiynaju lati dan agbara oogun abẹnugọngọ rẹ wo, eyi to pe ni ayẹta ibilẹ. Ikun ni Usman ti yinbọn funra rẹ.

“O ṣeni laanu wi pe oogun abẹnugọngọ naa dalẹ Usman, to si mu ko wa ni baaku-baala pẹlu ifarapa nla. Awọn ọlọpaa wa lati ẹkun Byazhin ni wọn sare lọ doola ẹmi rẹ.”

Bakan naa lo sọ pe awọn ti yẹ ile rẹ wo, wọn si ti ṣawari ibọn agbelẹrọ to n lo, ati pe bo tilẹ jẹ pe Usman n gba itọju lọwọ, sibẹ o ti tapa si ofin lilo ibọn ati igbiyanju lati gba ẹmi ara ẹni ti abala 231 ninu iwe ofin ẹkun Ariwa.

“Iwadii ti bẹrẹ, ati pe Usman yoo foju ba ile-ẹjọ lori ẹsun lilo ibọn ati igbiyanju lati gba ẹmi ara rẹ labẹ iwe ofin Ariwa Naijiria to wa ni abala 231.”

Bẹẹ lo ni Kọmiṣanna ọlọpaa FCT, Ọlatunji Disu bu ẹnu atẹ lu iwa naa.