Nkò nígbàgbọ́ nínú ẹ̀sìn nítorí pé kò sí ẹ̀sìn níjọba ọ̀run – Wolii Genesis

Oríṣun àwòrán, Genesis Global/Facebook
Alaṣẹ ati alakoso ijọ Celestia Church of Christ, Genesis Global Parish to wa niluu Eko, Wolii Israel Oladele Ogundipe ti sọ pe oun ko nigbagbọ kankan ninu ẹsin, bi ko ṣe iwa ọmọluabi ati ifẹ to ṣe pataki.
Wolii Ogundipe sọrọ naa ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu akọroyin ileeṣẹ PUNCH laipẹ yii.
Wolii Oladele Genesis sọ pe bo tilẹ jẹ pe Kristiẹni loun, sibẹ o jẹ ko di mimọ pe ko sohun to n jẹ ọrọ ẹsin nijọba ọrun, to si ni idi pataki niyẹn toun fi n ba awọn ọmọ ijọ miran ati musulumi ṣe papọ.
O tẹsiwaju pe Kristiẹni kii ṣe ẹsin, bi ko ṣe ọna si igbe aye, fun idi eyi, o ni gbigbe ifẹ, alaafia ati iṣọkan larugẹ lo ṣe pataki lati maa fi ṣe iwaasu ati ipolongo ijọba ọrun.
“Nko nigbagbọ ninu ẹsin. Kristiẹni kii ṣe ẹsin, bi ko ṣe pe o jẹ ọna igbe aye rere. Oniwaasu nipa ifẹ ni mi, nitori pe ko si ohun to n jẹ ọrọ ẹsin nijọba ọrun. Ọdọọdun ni mo maa n kopa nibi eto waasi Ramadaani.
“Mo maa n ṣe Iftah pẹlu awọn Musulumi. Awọn miran to n lọ ṣọọṣi buru ju awọn abọriṣa lọ. Awọn kan n wọ aṣọ sutana, ṣugbọn iwa wọn buru ju ti ejo lọ. Awọn miran si wa ti wọn ko wọ sutana tabi yẹri eti, sibẹ eniyan bi eṣu ni wọn jẹ.”
Wolii Genesis fi kun ọrọ rẹ wi pe, fun wi pe oun n kopa nibi ipẹjọpọ Ramadaani ko tumọ si pe oun wa lati idile Musulumi, bi ko ṣe pe iranṣẹ ati oludari loun jẹ, toun si gbọdọ ko gbogbo eeyan mọra.
“Ẹ ma gbagbe pe Jesu ba awọn ẹlẹṣẹ jẹ, to si ba wọn mu. Nko ri awọn Musulumi gẹgẹ bi ẹlẹṣẹ, ọlọkan mimọ ni wọn jẹ. Mo sunmọ awọn ọpọ Musulumi. Fun wi pe mo n kopa ninu eto Ramadaani ko ni ohunkohun lati ṣe pẹlu wi pe mo wa lati idile Musulumi.
“Mo n ṣe eyi nitori pe bi mo ṣe jẹ iranṣẹ naa ni mo tun jẹ adari. Gbogbo igba ti wọn ba ti pe mi lati wa waasu gẹgẹ bi adari ni mo maa n lo lati fi yi aye awọn eeyan pada.”
Siwaju sii lo ni ọpọ awọn eeyan ti awọn jọ n ṣe ẹsin Kristiẹni lo ti bu ẹnu atẹ lu oun, ati pe bi wọn ṣe n sọrọ soun, naa lawọn ẹlẹsin Musulumi n sọrọ sawọn olori ẹsin wọn ti awọn naa n ṣebi toun.

Oríṣun àwòrán, Genesis Global/Facebook
Sisan idamẹwaa kii ṣe nipa ipa ninu ijọ mi
Bakan naa, nigba to n sọrọ lori erongba rẹ nipa sisan owo idamẹwaa, Wolii Genesis sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun maa n san owo idamẹwaa oun ninu ijọ, sibẹ oun kii mu awọn ọmọ ijọ oun ni ipa lati san an.
O ni ohunkohun to ba wu onikaluku lo ṣe pẹlu owo idamẹwaa rẹ, nitori pe oun kii ṣe oludajọ.
Ninu ọrọ rẹ, o ṣalaye pe “A maa n san idamẹwaa ninu ijọ wa. Mo maa n san idamẹwaa, ṣugbọn mi o kii fipa mu awọn ọmọ ijọ lati san idamẹwaa.
“Mo ti sọ ọ nigba kan ri; nko lọwọ si owo ijọ. A maa n lo idamẹwaa lati fi ran awọn opo lọwọ ninu ijọ wa ni. Ṣugbọn ohunkohun to le wu ki awọn eeyan maa fi owo idamẹwaa ṣe ninu ijọ wọn ko kan mi, mi o kii ṣe adajọ.”















