Àlàyé lórí ọlọ́pàá obìnrin tó ṣe fídíò akẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó fipá bá ọmọ ọdún 17 lòpọ̀

Oríṣun àwòrán, @harrison_gwamnishu/Instagram/Nigerian Police
Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria ti sọrọ lori fọnran ọmọ ọdun mẹtadinlogun ti wọn fẹsun kan ọlọpaa kan nipinlẹ Edo pe o fipa ba lopọ.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi lede, ileeṣẹ ọlọpaa ni oun ti da ọlọpaa to ṣe fọnran naa, Edith Uduma duro lẹnu iṣẹ.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa tun fidi rẹ mulẹ pe ọlọpaa ti wọn fẹsun ifipabanilopọ, Abraham Uzuobo, kan naa ti wa ni ahamọ bayii.
Fọnran naa to ti wa lori ayelujara ṣafihan bi Abraham ṣe n tiraka lati wọ sokoto lati bo abẹ rẹ.
Fọnran naa tun ṣafihan ọmọbinrin naa to jokoo sori aga, ti kos si da bi pe o la oju.
BBC ko ti le fidi fọnran naa mulẹ.
Gẹgẹ bi o ṣe wa ninu atẹjade naa, ohun to sẹlẹ ni pe, wọn yọ fọnran naa kuro lori ayelujara lẹyin ọsẹ kan ti iṣẹlẹ naa waye.
“Iwadii fihan pe Abraham mu ọmọbinrin naa kuro ni ahamọ lati lọ ba a lopọ ni ọfisi kan ti ko si eeyan nibẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi ṣalaye.
“Lasiko ti ifipabanilopọ ọhun n lọ lọwọ ni Uduma wọle lati wa ka nnkan to n sẹlẹ. Ṣugbọn o kọ lati fi ọrọ to ẹka to kan leti.
O wa pinnu lati pe ọkọ rẹ, Ibrahim Mohammed pe ko fi gba owo lọwọ ọlọpaa akẹgbẹ rẹ to fi pa ba ọmọ naa lopọ, ko si bo ọrọ naa.”
Iwadii fihan siwaju pe Abraham san 45,000 naira lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye ṣugbọn wọn tun pinnu lati gba owo lọwọ rẹ lẹẹkan si, to si kọ lati san owo eyi to fa ti wọn fi sọ fun DPO , ti wọn si gbe fọnran naa sita.
Uduma ṣalaye ara rẹ lori iṣẹlẹ naa
Ẹwẹ, Edith Uduma to padanu iṣẹ lori iṣẹlẹ naa ti n pariwo sita pe nnkan ti ileeṣẹ ọlọpaa n sọ kọ lo sẹlẹ ati pe oun fi isẹlẹ ọhun to ẹka ti ọrọ kan leti ni ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye.
Bakan naa lo ni oun ko gba owo lọwọ afurasi.
Ninu fọnran to jade lọjọ kẹrinlelogun oṣu kọkanla, Uduma ni oun ko se ohunkohun, to si jẹ pe oun ti to awọn ọga leti ni kiakia ti ọrọ iṣẹlẹ naa waye .
“Abraham wa si ọdọ mi lati wa gba kọkọrọ lọwọ mi pe oun fẹ tu afurasi silẹ.
Mo fun olusọ ahamọ ni kọkọrọ pe ko tẹle Abraham lọ sibẹ.
N ko ri Abraham ati kọkọrọ titi awọn eeyan mi fi wa lati wa bere kọkọrọ.
“Nigba ti n ko ri, ti mo si wa lọ, ti mo si ka nibi to n ti nse iṣẹ laabi, ti mo si ka a silẹ.
O fi ẹri sita pe oun fi fọnran naa ransẹ si ẹka ti ọrọ kan.
O ni oun ko bere owo lọwọ Abraham ṣugbọn oun fi fọnran naa ransẹ si awọn akẹgbẹ rẹ ki wọn to ji foonu rẹ lọ.















