'Inú ìbànújẹ́ ni mo wà pẹ̀lú bí àwọn ọmọ mi mẹ́rin ṣe wà ní àhámọ́ àwọn ajínigbé'

Oríṣun àwòrán, Instagram/Chefsafmar
Gbajúmọ̀ alásè tó máa ń se oúnjẹ lórí ayélujára Aisha Kabir tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Chefsafmar ti sọ̀rọ̀ lórí ipò tó wà lẹ́yìn tí àwọn ajínigbé yawọ ilé rẹ̀ tí wọ́n sì jí àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rin gbé lọ.
Ní ìlú Kaduna, àríwá orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé lálẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó kọjá.
Lásìkò tó ń ṣe ìtọ́jú àwọn ìbejì rẹ̀ ní ilé ìwòsàn ni àwọn ajínigbé ya wọ ilé rẹ̀ tí wọ́n sì jí àwọn ọmọ náà – obìnrin mẹ́ta àti ọmọkùnrin kan tí kò ì tíì pé ọdún méjì gbé lọ.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wà lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé tó ń fa awuyewuye ní ẹkùn àríwá Nàìjíríà, níbi tí àwọn ajínigbé ti ń jí àwọn èèyàn gbé láti fi gba owó.
Àwọn ajínigbé náà ti kàn sí ẹbí Aisha gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fi tó BBC News Hausa létí, tí wọ́n sì ń bèèrè fún ọ̀ọ́dúnrún mílíọ̀nù náírà kí wọ́n tó tú àwọn ọmọ náà sílẹ̀.
Agbegbe Keke ní ìlú Kaduna ni Aisha Kabir tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Chefsafmar lórí ayélujára ń gbé ní ìlú Kaduna, ìpínlẹ̀ Kaduna.
Ó ṣàlàyé fún BBC pé òun wà ní ilé ìwòsàn níbi tí àwọn ọmọ ìbejì, ọmọ oṣù méjì tó ń tọ́jú lọ́wọ́ ti ń gba ìtọ́jú, kí òun tó gba ìròyìn pé wọn kò rí àwọn ọmọ òun mọ́.
Ó ní òun wà ní ilé ìwòsàn náà ni ọkọ òun pe òun lórí fóònù pé òun kò bá àwọn ọmọ nínú ilé nígbà tó dé láti inú oko rẹ̀.
“Ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án alẹ́ ni ọkọ mi pè mí láti bèèrè pé ṣe àwọn ọmọ mi dágbére ibi tí wọ́n ń lọ fún mi.
“Mo pe ìyá mi àti ọmọ ìyá mi obìnrin láti mọ̀ bóyá àwọn ọmọ náà wà pẹ̀lú wọn àwọn tí wọ́n ní àwọn kò rí wọn rárá.
“A lo bèèrè lọ́wọ́ àwọn ará àdúgbò ṣùgbọ́n kò sí ẹnikẹ́ni tó mọ ibi tí wọ́n wà.”
Ó sọ pé kò p.ẹ́ ni àwọn rí bàtà àwọn náà ní balùwẹ̀, tí bàbá wọn sì ṣe àkíyèsí pé wọ́n ti já ilẹ̀kùn ẹ̀yìn ilé àwọn.
Ohun táwọn ọmọ ń báwa sọ lórí fóònù

Oríṣun àwòrán, AISHAKABIR/CHEFSAFMAR
Èyí tó dàgbà jùlọ nínú àwọn ọmọ náà ni ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, tí èyí tó tẹ̀le sì jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá. Ọmọ ọdún méje ni ìkẹta, tí ìkẹrin sì jẹ́ ọmọ ọdún méjì.
Yàtọ̀ sí àwọn ọmọ náà, àwọn afurasí ajínigbé náà tún mú ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ táwọn òbí ọmọ náà fi máa ń bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nílé.
Ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n fi pe Aisha àti ọkọ rẹ̀ láti fi bèèrè owó ìtúsílẹ̀ àwọn ọmọ náà.
Aisha pẹ̀lú omijé lójú ní òun kò lè bá àwọn ọmọ náà sọ̀rọ̀ nígbà tí wọ́n pe àwọn nítorí ìbànújẹ́ gba ọkàn òun.
Ó ní ìgbà tí àwọn ọmọ òun kọ́kọ́ pé “níṣe ni gbogbo ara mi ń gbọ̀n nítorí ìbẹ̀rùn tó gba ọkàn mi látàrí ohùn wọn tí mo gbọ́.”
“Nígbà tí wọ́n gbé fóònù fún èyí tó dàgbà jùlọ láti bá wa sọ̀rọ̀, ó ń bẹ bàbá rẹ̀ láti wá owó náà wá nítorí àwọn agbébọn náà ti dúnkokò mọ́ wọn pé àwọn máa pa wọ́n tí wọn kò bá rí owó náà.
Ebi ń pa wá, a ò rí omi mu.”
Aisha fi kun pé inú ìbẹ̀rù bojo àti àìbalẹ̀ ọkàn ni ẹbí òun wà báyìí.
Ó fi ìbànújẹ́ hàn pé òun kò mọ ibi tí àwọn ọmọ òun ń sùn láspikò tí ọyẹ́ ti sọ̀ kalẹ̀ báyìí, tó jẹ́ pé àwọn tí àwọn wà nílé gan ń ká góńgó fún òtútú.
Aisha ń bèèrè fún ìtúsílẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀ àti mímójútó ètò ààbò orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.















