Wo ìlú tí wọ́n ti ń lo ṣọ́ọ̀bù bíi ilé ìwòsàn láti tọ́jú àwọn aláàárẹ̀ ní Nàìjíríà

Awọn ara abule Baita to wa nijọba ibilẹ Gezawa, ipinlẹ Kano, ẹkun Ariwa orileede Naijiria ni wọn ti n rawọ ẹbẹ si awọn alaṣẹ lati kọ ile iwosan igbalode alabọde fun wọn.
Ni abule yii, ṣọọbu kan to jẹ pe ibusun itọju kan ṣoṣo lo wa nibẹ, ti wọn fi n ṣe ọsibitu, nitori pe awọn ohun itọju ti wọn n lo tẹlẹ ti bajẹ tan.
Dokita marun-un ọtọọtọ lo n da awọn eeyan lohun ninu ṣọọbu ti wọn sọ di ọsibitu ojiji yii, gẹgẹ bi awọn ara abule naa ṣe sọ.
Gẹgẹ bi awọn ara abule naa ṣe ṣalaye, wọn ni ọdun 1991 ni wọn ti kọ ile iwosan alabọde ti wọn ti pa ti naa, nitori pe ijọba ko bojuto o.
Awọn ara abule naa sọ pe eeyan ti ko din ni ẹgbẹrun mẹwaa lo n wa si ile iwosan ọhun lati gba itọju loṣu, ati pe awọn abule bii mẹwaa to wa lagbegbe abule Biata ni wọn ti n wa gba itọju.
Nitori ipo ti ile iwosan alabọde naa wa, pẹlu bi awọn ogiri rẹ ti ṣe la, to si ti jọ bi eyi to fẹẹ wo lulẹ, lo jẹ ki wọn pa a ti lati ma ṣe lo o mọ.

Lati bii ọdun mẹsan sẹyin ni wọn ti n kuro lati inu ṣọọbu kan bọ si ṣọọbu miran. Ọdun meji sẹyin, ni wọn tiraka lati gba ṣọọbu kan to tun ni yara kan ninu.
Ni bayii, awọn dokita n lo yara kan lati fi da awọn eeyan lohun, nigba ti wọn n lo yara keji lati fi ṣe itọju awọn alaisan, paapaa awọn ti wọn ba fẹẹ da duro fun itọju.
Pẹlu eto ti wọn ṣe yii, sibẹ inu awọn ara abule naa ko dun nitori pe ipo ti nnkan wa nibẹ ko fun awọn dokita lanfaani lati ṣiṣẹ bo ti tọ ati bo ti yẹ.
Ipo ti eto ilera wa lagbegbe naa ti fa iku ọpọ awọn eeyan, paapaa awọn obinrin ti wọn n bimọ.
Pupọ awọn obinrin yii si ni wọn n ku lasiko ti wọn n gbe wọn digbadigba lọ si ọsibitu nla fun itọju ni Minjibir tabi Gezawa.
Obinrin kan to pe ara rẹ ni Zainab Abdullahi labule naa sọ fun BBC pe inu oun kii dun ni gbogbo igba toun ba ti gbe ọmọ oun lọ si ṣọọbu ti wọn pe ni ọsibitu fun itọju.
O tiẹ tun sọ pe oun ti padanu ọmọ meji lati irọbi, nitori bi wọn ṣe bẹrẹ sii sun ẹjẹ lẹyin ti wọn bimọ tan.



“Fun bi ọdun meji le sẹyin, gbogbo igba ti mo ba ti gbe awọn ọmọ mi wa sibi, o maa n dun mi lati ri ṣọọbu ti wọn pe ni ọsibitu yii, nitori pe koda awọn dokita kii ri anfaani lati ṣiṣẹ wọn bo ti tọ, nitori pe ṣọọbu naa kere,” Zainab lo sọ eyi.
O fi kun ọrọ rẹ pe “Mo padanu ọmọ mi meji lasiko irọbi. Eyi to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ waye ni nnkan bi ọsẹ diẹ sẹyin, nitori pe lẹyin to bimọ tan, ni ẹjẹ bẹrẹ sii da lara rẹ, oju ọna lo dakẹ si lasiko ti a n gbiyanju lati sare gbe e lọ si ọsibitu nla to wa ni Gezawa.”
Zainab tun sọ pe “ọmọbinrin mi miran to ku lọdun diẹ sẹyin naa ku nipa iṣẹle yii, niṣe lo n da ẹjẹ ni kete to bimọ tan.
“To ba jẹ pe ile iwosan alabọde ati ohgun itoju to dara wa ni Baita ni, awọn ọmọ mi mejeeji yoo ṣi wa laye.Fun idi eyi, mo n rawọ ẹbẹ sijọba lati wa ṣe atunṣe lori ile iwosan to wa nibi.”
Bakan naa ni baale ile kan ni abule naa, Rabi'u Abdulmuminu, sọ pe oun naa padanu iyawo ati ọmọ rẹ nitori ipo ti ko dara ti eto ilera wa ni Baita.
“Ko to kan mi, ọpọ awọn eeyan ni wọn ti padanu mọlẹbi wọn, ko to di pe o kan emi naa loṣu diẹ sẹyin, nitori pe mo padanu iyawo ati ọmọ mi.”

Oríṣun àwòrán, Labaran Baita
Abdulmimunu fi kun ọrọ rẹ pe “Ọwọ alẹ ni iṣẹlẹ naa waye nigba to ku diẹ ki iyawo mi bimọ, o jiya pupọ nitori pe ọsibitu naa ko sunmọ abule wa.
“Nigba ti a de ọsibitu nla to wa ni Gezawa, o ti padanu agbara to pọ, ọmọ naa si kun sii ninu ko to di pe o bi i,” o sọ bẹẹ.
O sọ siwaju pe “Oun naa pada ku, nitori ti mo mọ pe to ba jẹ pe a ri ọsbitu gidi lati gbe iyawo mi lọ, iyawo mi ko nii ku, bẹẹ ni ọmọ mi naa yoo si tun wa laye.”
Baale abule Baita, Alkasim Isiyaku sọ pe awọn pinnu lati kuro ni ọsibitu naa nigba ti awọn ṣakiyesi pe ogiri rẹ ti n la, ti awọn ko si fẹẹ fi ẹmi awọn eeyan sinu ewu.

Baale naa sọ pe fun ọpọlọpọ ọdun ni awọn ti kọ lẹta ranṣẹ si ijọba lori atunṣe, ṣugbọn ti wọn ko gbọ esi kankan.
“A ti n kọ lẹta si ijọba lati bi ọdun meje sẹyin wi pe ki wọn wa ṣe atunṣe si awọn irinṣẹ ati ọsibitu naa, ṣugbọn ko si esi kankan.”
Baalẹ naa sọ pe inu awọn dun lọpọlọpọ fun obinrin to pinnu lati fi ṣọọbu rẹ silẹ lati rọpo ọsibitu to ti dẹnukọlẹ naa.
Hajiya Zuwaira Baita sọ pe oun pinnu lati fi ṣọọbu rẹ silẹ nitori awọn obinrin ati awọn ọmọde ti wọn nilo itọju ni agbegbe naa ati awọn abule to sunmọ wọn.
“Mo rii pe awọn obinrin ati ọmọde ko ni lanfaani lati ri awọn dokita mọ bi awọn ọsibitu ati ile itọju ko ba ṣiṣẹ mọ.”

O sọ pe “Ọpọ awọn alaboyun ati awọn ọmọ wọn lati agbegbe to sunmọ wa ni wọn gbẹkẹle ile iwosan wa lati gba itọju.
“Fun idi eyi, mo pinnu lati gbe ṣọọbu mi kalẹ fun igba diẹ, ko to di pe ijọba dide lati wa ṣe atunṣe lori ile iwosan to dẹnukọlẹ naa.”
Awọn ara abule naa wa n n rawọ ẹbẹ si ijọba fun iranlọwọ lori ipenija ti awọn obinrin ati awọn ọmọde n dojukọ nitori aisi eto aabo to peye latari ile iwosan alabọde ti ko si.

Kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Kano, Abubakar Labaran Yusuf sọ fun BBC pe oun ko mọ ohunkohun nipa nnkan to n ṣẹlẹ ni Baita, nitori pe oun ko tii figba kan gba lẹta kankan lati ibẹ ri.
“Nko tii gba lẹta tabi aẹjiṣẹ kankan lati ọdọ wọn ri, ṣugbọn ni bayii ti mo ti wa gbọ, mo maa ran awọn eeyan mi lọ lati mọ ohun to n ṣẹlẹ nibẹ, ati nnkan ti wọn fẹ.
“Igba naa ni maa too ṣẹṣẹ mọ boya wọn wa lara awọn agbegbe to wa ni akọsilẹ lati ṣiṣẹ akanṣe nibẹ, ati pe bi wọn ko ba wa si nibẹ, mo maa gbiyanju lati fi wọn sinu ipele to kan ni ibẹrẹ ọdun tuntun.”
Labaran tun fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti ni ẹgbẹrun meji ile iwowsan nipinlẹ Kano.
Ni bayii, mọkanla ninu awọn ile iwosan naa ni awọn abule to wa ni Kani ni wọn ti mu fun atunṣe.
















