Àìrí onímọ̀ràn gidi, fífi ojú olóore gúngi, kún ara ohun tó fa ìjákulẹ̀ mi - Olajumoke Oníbúrẹ́dì
Arabinrin Olujumoke Orisaguna to di ilumọọka lọdun 2016 lẹyin ti gbajugbaja ayaworan T.Y. Bello gba igba burẹdi to n kiri lori rẹ ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ si i lẹyin t'awọn eeyan mọ ọn tan.
Ṣebi ori ti yoo gbeni ni i gbe alawore koni, nibi ti Arabinrin Bello ti n ṣiṣẹ fọto rẹ lo ti gan-an ni Jumoke to n ta burẹdi niluu Eko.
Níbẹ ni Bello ti wo arabinrin naa pe o le maa ṣiṣẹ arinrin oge pẹlu ẹwa ti Eledua fi jinki rẹ.

Oríṣun àwòrán, TYbello/BBC
Ninu ifọrọwerọ yii pẹlu BBC, Ọlajumọkẹ Ọlagunna ti ọpọ mọ si Ọlajumọkẹ oniburẹdi ṣalaye pe fifi oju oloore gungi jẹ ọkan gboogi lara awọn ohun to ṣe okunfa ijakulẹ oun kuro ni ipo itura bọ si inira.
O ni bakan naa ni oun ko tun ri onimọran gidi lawọn asiko kan ni irinajo oun eleyi to ni o ṣe okunfa bi oun ṣe di ẹni ti n ṣe iṣẹ ṣugbọn laisi ere kankan.
Mo fẹ lọ si ileẹkọ, nitori aikawe ṣe ọpọ ijamba fun mi - Ọlajumọkẹ

Bakan naa ni gbajumọ igbakan naa tun ṣalaye pe ohun kan to jẹ oun logun bayii ni pipada lọ ka iwe.
O ni idi ti kikawe ṣe di ọranyan lẹmi oun bayii ni pe oun rii pe ka ni oun kawe ni awọn to parapọ pẹlu agbẹjọro oun lu oun ni jibiti ko ni le ṣe bẹẹ rara.
Bakan naa lo ni ọpọ owo ni oun ti padanu lẹnu iṣẹ nitori aikawe oun.



