Ilé ẹjọ́ da ẹ̀bẹ̀ Yahaya Bello fún béèlì nù, wọ́n ní kó padà sí àhámọ́

Oríṣun àwòrán, X/Yahaya Bello
Adajọ Maryann Anenih ti ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti kọ lati fun gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, Yahaya Bello ni beeli to bere fun lọwọ ile ẹjọ.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ, adajọ Anenih ni ọna ti Bello gba lati bere beeli naa ko tẹle ilana ofin.
Yahaya Bello, to jẹ gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Kogi, n jẹjọ lọwọ pẹlu awọn meji mii lori ẹsun ṣiṣe owo ilu ti iye rẹ to aadọfa biliọnu naira mọkumọku ti EFCC fi kan wọn.
Adajọ ni ohun ti iwe ẹbẹ fun beeli naa eyi to ni wọn fi sọwọ ni ọjọ kejilelogun oṣu kọkanla n beere fun ni iyonda lati ma jẹjọ lati ile.
Ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kọkanla ni Yahaya Bello farahan ni ile ẹjọ niwaju onidajọ Anenih.
Bello pẹlu Umar Shuaibu Oricha atI Abdulsalam Hudu lo n jẹjọ ẹsun mẹrindinlogun ti EFCC ka si wọn lẹsẹ.
Ki lo sẹlẹ saaju?
Gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, Yahaya Bello jẹwọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ lorilẹede Naijiria, EFCC n fi kan an pe o ṣe owo to to ọgọrin biliọnu Naira baṣubaṣu.
Nigba ti igbẹjọ oṣu to lọ bẹrẹ, ọkan lara awọn oṣiṣẹ ile ẹjọ naa ka ẹsun mẹrẹrindinlogun ti wọn fi kan an lẹsẹẹsẹ si eti Bello atawọn meji miran ti wọn fi ẹsun kan pẹlu rẹ - Shuaibu Oricha ati Abdusami Hudu, gbogbo wọn lo si dahun pe awọn ko jẹbi.
Amofin agba, Joseph Daudu SAN to lewaju ikọ agbẹjọro fun Yahaya Bello, ti amofin agba, Kẹmi Pinhẹro, SAN ni o n ṣoju fun ajọ EFCC















