Ilé ẹjọ́ gba béélì Dele Farotimi pẹ̀lú N50m

Aworan Dele Farotimi

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ile ẹjọ giga to n jokoo niluu Ado Ekiti ti gba beeli agbẹjọro agba, Dele Farotimi.

Farotimi ni wọn fun ni beeli ni owurọ ọjọ Aje pẹlu owo toto Aadọta milọnu naira pẹlu oniduro.

Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Action Congress(AAC) ninu ele idibo ọdun 2023, Omoyele Sowore lo kede eyi loju opo ayelujara X lọjọ Aje.

"A ti bori ipele akọkọ. Dele Farotimi ti gba beeli pẹlu aadọta milọnu naira pẹlu oniduro to ni ilẹ."

Bẹẹ ba gbagbe, Agbaọjẹ agbẹjọro to tun jẹ oludasilẹ Afe Babalola University, ABUAD, Oloye Afe Babalola ti sọ pe ti ajafẹtọọ Dele Farotimi ba le fidi ẹsun to fi kan oun múlẹ, yoo gb'ominira lọgba ẹwọn to wa.

Ni ibẹrẹ ọsẹ yii nile ẹjọ majisreeti kan ju Farotimi sẹwọn titi ti igbejọ rẹ yoo fi tẹsiwaju lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti Oloye Babalola fi kan an.

Ṣaaju ni Farotimi fẹsun kan agbaọjẹ agbẹjọro naa ninu iwe ti o ṣẹṣẹ kọ jade pe o gbe iwa ibajẹ wọ eto idajọ orilẹede Naijiria.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Lẹ́yìn ìkìlọ̀ Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá, àwọn olùwọ́de kọ jalẹ̀ lórí ìfẹhonúhàn

Ẹwẹ igbẹjọ lori ẹsun naa yoo tẹsiwaju lonii, ti awọn oluwọde to n se ifẹhonuhan tako minu ajafẹtọ agbẹjọro, Dele Farotimi, Take It Back Movement si yari pe awọn yoo tẹsiwaju pẹlu ifẹhonuhan lẹyin ti ileeṣẹ ọlọpaa gbe ikilọ sita.

Ifẹhonuhan ni wọn ni yoo waye ni ipinlẹ Eko, Ekiti, ilu London ati orilẹede Canada.

Saaju ni ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti gbe ikilọ sita pe awọn ko ni faye gba iwọde kankan lasiko yii nipinlẹ Ekiti.

Ninu atẹjade kan ni agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Abutu Sunday fi lede fawọn akọroyin, awọn ko ni faya gba eyikeyi iwọde tabi ifẹhonuhan.

Ẹwẹ ninu aworan ti awọn ẹgbẹ to fẹ se ifẹhonuhan fi sita loju opo X ni ko si ni si ohunkohun ti yoo yẹ ifẹhonuhan naa.

Ninu aworan naa, Ẹgbẹ Take It Back Movement ko si nnkan ti yoo yẹ erongba wọn lati se ifẹhonuhan naa

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2