Tinubu, Atiku àtàwọn èèkàn míì kí Ààrẹ tí ìlú ṣẹ̀ṣẹ̀ dìbò yàn ní Ghana, John Mahama kú oríre

Oríṣun àwòrán, X/John Mahama
Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu ti ki aarẹ ti ilu ṣẹṣẹ dibo yan lorilẹede Ghana, John Dramani Mahama ku orire aṣeyọri rẹ ninu eto idibo to waye ni ọjọ keje oṣu kejila ọdun 2024.
Nigba to n kan si Mahama lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ, Aarẹ Tinubu ni oun lero pe ipadabọ Mahama sipo Aarẹ yoo pese anfani pupọ fun ọrilẹede Ghana ati ilẹ Afrika.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ aarẹ fi lede fun awọn akọroyin, Tinubu ki awọn ọmọ orilẹede Ghana ku orire lori bi wọn se fun ijọba awarawa ni anfani, eyi to n mu alaafia jọba lasiko eto idibo.
Tinubu ni ohun iwuri ati awukọse nla lo jẹ fun gbogbo agbaye pe orilẹede Ghana pinnu lati lo ijọba awarawa lati mu igbaye gbadyn ba orilẹede naa.
"Ni orilẹede Naijiria, ẹtọ awọn araalu ni lati yan olori wọn fun ara wọn jẹ ohun iwuri pupọ."
Bakan naa ni Aarẹ Tinubu tun kan sara si igbakeji aarẹ orilẹede Ghana, to tun jẹ oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu NPP, Mahamudu Bawumia fun bi o ṣe gbe pe oun lulẹ saju ki ajọ eleto idibo to kede .
Tinubu ni ohun ti Bawumia se ṣafihan igbagbọ rẹ si ijọba awarawa.
NI pari ọrọ rẹ, Aarẹ Tinubu dupẹ lọwọ Aarẹ Nana Akufo fun bi o ṣe jẹ olori rere to ni ifẹ ati ilọsiwaju orilẹede Ghana lọkan
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Yatọ si Tinubu, igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ, to tun dije du ipo Aarẹ lọdun to kọja, Atiku Abubakar naa tun kan sara si Aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan naa.
Abubakar lo fi ọrọ ọhun lede loju opo X rẹ.
O ni "Ọlọla julọ, Aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, mo ki yin ku oriire.
"Wọn sọ fun mi pe ẹ fẹ lọ si ṣọọṣi, mo ni si ki n tete fi ohun ranṣẹ si yin ki ẹ to wọ ile ijọsin."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2












