Ṣó o Láyà: Peller kópa nínú ìdánwò tó dá lórí àṣà àti èdè Yorùbá

Àkọlé fídíò, Peller náà dánra wò lórí ètò So Laya
Ṣó o Láyà: Peller kópa nínú ìdánwò tó dá lórí àṣà àti èdè Yorùbá

Odu ni gbajumọ oriTiktok, Habeeb Hamzat ti ọpọ eeyan mọ si Peller lori itakun ayelujara, kii ṣe aimọ fun oloko.

Laipẹ yii ti BBC Yoruba ṣe ifọrọwerọ pẹlu ọdọkunrin naa ni o kopa ninu idanrawo ranpẹ lori eto Ṣo o Laya.

A beere awọn ibeere to ni ṣe pẹlu ede Yoruba lọwọ rẹ, gẹgẹ bi ọmọ Yoruba.

Peller ṣi igba ibeere, o si mu oniruuru ibeere lati sọ idahun.

Lai ṣe ani-ani, Peller gbiyanju gbiyanju agbara rẹ lori eto ọhun.

Ẹyin gan an funra yin maa ri igbiyanju rẹ ninu fọnran yii.