Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Attiéké, oúnjẹ tí Unesco kéde gẹ́gẹ́ bí nǹkan ìṣẹ̀mbáyé tí kò gbọdọ̀ parun

Oríṣun àwòrán, AFP
Ajọ iṣọkan agbaye ti jẹ ko di mimọ pe awọn ti fi ounjẹ Attiéké saarin akọsilẹ ounjẹ ninu eto aṣa iṣẹmbaye to ṣe pataki.
Attiéké jẹ ounjẹ kan to gbajumọ ni orile-ede Ivory Coast.
Ẹgẹ ti wọn lọ ni wọn fi n ṣe ounjẹ naa.
UN sọ pe iwuri nla lo jẹ fun ajọ iṣọkan agbaye.
Ounjẹ naa gbayi debi pe, awọn kan n jẹ gẹgẹ bi ounjẹ aarọ, ọsan ati alẹ.
Yatọ si Attiéké ti wọn n pe ounjẹ ọhun, wọn tun fun un ni inagijẹ 'Ivorian couscous', ẹja asun ni wọn fi n jẹ ẹ lati gbadun ẹ.
Ni nnkan bi ọpọlọpọ ọdun sẹyin ni wọn bẹrẹ sii ṣe ounjẹ naa lorileede Ivory Coast, ṣugbọn to ti wa di gbajugbaja bayii kaakiri ilẹ Afrika.
Ọkan lara awọn aṣoju ilẹ Ivory Coast ninu ajọ UNESCO, Ramata Ly-Bakayoko, sọ nibi akanṣe ipade didaabo bo nnkan aṣa iṣẹmbaye ẹlẹẹkọkandinlogun iru ẹ to waye lorileede Paraguay wi pe, Attiéké dara pupọ ninu igbesi aye awọn eeyan.
Ọti kan naa ti wọn n pe ni 'Japanese sake', ni wọn tun ti fi kun iwe akọsilẹ ọhun lọdun yii.
Nilẹ Ivory Coast, ko si ibi ti wọn kii tii fi ounjẹ Attiéké ṣalejo, bi wọn ṣe fi n ṣalejo lode ariya bii ayẹyẹ igbeyawo, eto isinku, ayẹyẹ iṣọmọlorukọ, naa ni wọn tun n jẹ nibi eto iribọmi ti awọn Kristiẹni.
O kọja ounjẹ lasan, nitori pe ounjẹ ọhun ti di ohun amuṣọrọ to n pawo wọle fun ọpọ awọn obinrin nilẹ Ivory Coast.
Bi awọn iyale-ile ṣe n se 'Attiéké', naa ni awọn ọlọmọge n se e, ti wọn si tun fi n ṣe ifigagbaga lawujọ lati mọ ẹni to mọ sise rẹ julọ.
Ounjẹ naa kii ṣe ounjẹ ti wọn n se laarin ọjọ kan, nitori bo ṣe ni ilana pipese rẹ, koda, eyi gan-an lo jẹ ki ajọ UNESCO fi sinu akọsilẹ awọn nnkan aṣa iṣẹmbaye wọn.
Eepo ẹgẹ ni wọn yoo bẹ, ti wọn yoo ge, ko to di pe wọn po o papọ mọ ẹgẹ wọn ti rẹ sinu omi tẹlẹ.
Lẹyin eyi ni wọn yoo fun un papọ lati yọ sitaaṣi (starch) to wa ninu rẹ kuro, ko to di pe wọn lọ sa a, ko le gbẹ, ki wọn to ṣẹṣẹ lo fun un papọ lati din.
Lẹyin ti gbogbo igbesẹ ọhun ba pari, wọn yoo dii sinu apo lati gbe e lọ saarin ọja fun tita fawọn eeyan.
Ounjẹ ti wọn sọ pe iran kan n fi silẹ fun awọn iran to n bọ lẹyin ni, kii ṣe ohun aṣa iṣẹmbaye to le parẹ, gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.
Ilana ṣiṣe rẹ la gbọ pe iya yoo gbe fun ọmọ rẹ, ti ọmọ naa yoo tun gbe e fun ọmọ ti oun naa ba bi, ati pe ounjẹ naa "jẹ opo idanimọ fun gbogbo ọmọ ilẹ Ivory Coast", Ms Ly-Bakayoko lo sọ bẹẹ.
Ajọ UNESCO tẹnumọ idi to fi ṣe pataki lati maa daabo bo eto ilana aṣa.
Bi wọn ṣe fi 'attiéké' kun awọn ohun aṣa iṣẹmbaye ninu akọsilẹ, tọka si pataki iṣọkan gẹgẹ bi ohun ajọgbe, UNESCO jẹ ko di mimọ.
Adun ounjẹ ọhun tun ti fa ariyanjiyan kaakiri agbaye.
Lọdun 2019, ariwo nla lo sọ lorileede Ivory Coast nigba ti obinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Florence Bassono, alaṣẹ ati oludasilẹ Faso Attiéké lati orileede Burkina Faso, gba aami ẹyẹ nibi ipatẹ ọja agbẹ agbaye niluu Abidjan, iyẹn Abidjan International Agriculture Show.
Ọpọ awọn ọmọ ilẹ Ivory Coast ni wọn binu, ti wọn si faraya wi pe ko yẹ ki ajoji kan wa gba aami ẹyẹ to jẹ pe ounjẹ ilẹ awọn ni mọ wọn lọwọ.
Ni ibẹrẹ ọdun yii, ajọ kan ti wọn pe ni African Regional Intellectual Property Organization ṣe iforukọsilẹ aami idanimọ ti a mọ si 'trademark', lati le fi dabo bo awọn ẹgẹ ti wọn n ṣe lawọn orileede miran, eyi ti wọn n fi orukọ attiéké ta – ni ibamu pẹlu bi wọn ṣe n ṣe ọti champagne ni France pẹlu orukọ naa.















