Ọmọ ọdún mẹ́sàn án tó ń fi iná ṣeré jó ilé àwọn òbí rẹ̀ gúrúgú ní Kwara

Fire

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iroyin lati ipinlẹ Kwara sọ pe ọmọ ọdun mẹsan an kan ti dana sun ile awọn obi rẹ to wa ni ojule kejilelaadọta, ni adugbo Mandate Housing Estate, Ilorin.

Iroyin ni ṣe ni ọmọde naa n fi iṣana ṣere, eyii to ran mọ ibusun ile wọn, ti ina ọhun si gba gbogbo ile naa.

Hakeem Adekunle, to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ panapana ipinlẹ Kwara lo fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ.

Ileeṣẹ panapana ni irufẹ iṣẹlẹ yii kan naa ti waye ri lọdun to kọja niluu Ilorin, nibi ti ọmọ kekekre kan ti jo ile awọn obi rẹ gurugu.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels, Hakeem Adekunle sọ pe nigba ti ọmọde naa gbọ ohun ọkọ eyọkẹlẹ baba rẹ, ẹru baa, lo ba ju ina ọhun si abẹ ibusun pẹlu igbagbọ pe ibunsun ọhun yoo pa ina naa.

O ni "Lẹyin iṣẹju diẹ ni baba rẹ wọ inu iyara ti ko si mọ ohun to n ṣelẹ, baba rẹ ko gbogbo ẹbi wọn ja lati lọ ra awọn nnkankan.

"Wọn ti ikẹkun ile wọn, wọn si jade lai mọ pe ewu n bẹ loko longẹ.

"Nigba ti wọn yoo pada dele ni wọn ri pe ina ti jo gbogbo ile naa ti ko si ku dukia kankan fun wọn mọ."

Adekunle lo akokoko naa lati ki awọn ọbi nilọ lati maa fa awọn ọmọ wọn leti nipa ewu to wa ninu ki ọmọde maa fi ina iṣere.

O tun rọ awọn obi lati mu iṣana atawọn nnkan mii to lo gbina jina si ikawọ awọn ọmọ wọn.