Aráàlú já ṣọ́ọ̀bù, sọ iná sí ọọ́físì àjọ elétò ìdìbò lẹ́yìn ìbò Ààrẹ Ghana

Unrest

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Iroyin lati orilẹede Ghana sọ pe awọn araalu kan ti bẹrẹ si n ja ṣọọbu atawọn ile itaja lẹyin eto idibo Aarẹ to waye nibẹ lọjọ Abamẹta.

Akọroyin BBC to wa ni Ghana jabọ pe agbegbe Dome-Kwabenya, ni idarudapọ naa ti milẹ julọ.

A gbọ pe awọn eeyan naa ti lọ ja gbọgan ti ijọba n ko awọn ohun elo ọgbin si lagbegbe Tamale.

Lara awọn nnkan ti awọn eeyan naa n ji ko nibẹ ni ajilẹ, oogun pakopako, irẹsi, kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta, elo ara ọkọ ati ọkọ akẹru.

Iroyin ni awọn ọlọpaa wa nibi ti awọn eeyan ti n ji ẹru naa ko amọ o ṣoro fun wọn lati ṣe ohunkohun.

Awọn eeyan naa ni ṣe lo yẹ ki ijọba pin awọn nnkan ti awọn n ji naa faraalu amọ awọn alaṣẹ yan lati ko wọn pamọ.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa, ACP Grace Ansah-Akrofi fi lede, o ni lootọ ni iṣẹlẹ naa waye, awọn si ti fi ṣikun ofin mu afurasi mẹrinla.

Yatọ si ile ti ijọba ko ẹru si ti awọn eeyan naa ja, ọlọpaa ni wọn tun kọlu ọọfisi ajọ eleto idibo to wa lagbegbe Savannah.

Ẹwẹ, a tun gbọ pe awọn eeyan naa ti sọ ina si ọọfisi ajọ eleto idibo to wa ni Damongo.

Kàyéèfì ní Ghana, Olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú NPP, Mahamudu Bawumia kí John Mahama ti NDC kú oríire bíborí ìbò ààrẹ, àmọ̀ àjọ ìdìbò EC kò tíì kéde èsì ìbò kankan

Aworan John Mahama

Oríṣun àwòrán, X/John Mahama

Oludije fun ẹgbẹ oṣelu NDC lorilẹẹdẹ Ghana, Aarẹ tẹlẹ John Mahama ti kede pe igbakeji aarẹ orilẹede naa, Mahamudu Bawumia to n dije fun ẹgbẹ oṣelu NPP ti gba pe oun loun bori ibo naa aarẹ to waye lọjọ Abamẹta.

Ninu atẹjade kan to fi sita loju opo X rẹ l'owurọ ọjọ Aiku, John Mahama sọ pe, Bawumia ti pe oun lori aago o si ti ki oun ku oriire gẹgẹ bi olubori ibo aarẹ.

Kayeefi nla leyi jẹ nitori pe titi di asiko ti a n kọ iroyin yii, ajọ eleto idibo Ghana, EC ko tii jede esi ibo kan ṣoṣo bayii lẹyin ọpọ wakati ti eto ibo didi dawọ duro.

Igbakeji Aarẹ Ghana, Mahamudu Bawumia ti tẹwọ gba ijakulẹ rẹ ninu idibo sipo aarẹ orilẹede naa to waye lọjọ Abamẹta, to si ki Mahama ku oriire nitori "araalu ti dibo fun ayipada".

Bi o tilẹ jẹ wi pe Bawumia ti gba pe oun ko bori ibo naa, ajọ eleto idibo Ghana ko tii gbe esi idibo kankan jade.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ní Ghana, ọlọ́pàá mú afurasi mẹ́rin fún ẹ̀sùn ìyìnbọn-pànìyàn lásìkò ìdìbò, àjọ EC ní àwọn kò tíì rí èsì ìbò kankan

Aworan awọn afurasi

Oríṣun àwòrán, Ileeṣẹ ọlọpaa Ghana

Eto idibo apapọ lorilẹẹdẹ Ghana waye lọjọ Satide, ajọ eleto idibo lorilẹẹdẹ naa si ti bẹrẹ kika ibo bayii

Amọṣa oniruuru iṣẹlẹ manigbagbe lo waye lasiko idibo ọhun.

Lara wọn ni ikọlu to wa'ye lawọn agbegbe kan nibi ti iro ibọn ti sun lalọlakọ ti ẹmi si tun ba a lọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Ghana ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ eeyan mẹrin kan ti wọn jẹ afurasi fun isẹlẹ ikọlu awọn qgbebọn kan to waye ni ẹkun idibo ila oorun Awuku Senya ni aringbungbun orilẹẹde ọhun. Eeyan kan lo ku lasiko ikọlu naa, ti eeyan miran si tun fi ara pa.

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Ghana ni awọn afurasi naa ti wa lahamọ, ti iwadii si n tẹ siwaju

Ki lawọn oludije n sọ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bi ko ba si nnkan miran , awa ni yoo bori-

John Mahama, Oludije NDC

Oludije fun ẹgbẹ alatako NDC lorilẹẹdẹ Ghana, Aarẹ tẹlẹ, John Mahama ti oun pẹlu dibo ni ilu rẹ to wa ni Bole Bamboi lagbegbe Savanah sọ pe o da oun loju pe oun ni yoo bori ibo aarẹ naa.

"O da mi loju bi ada pe awọn eeyan orilẹede Ghana yoo fun mi lanfani lati sin wọn lẹẹkan sii, mo dẹ ni igbagbọ ninu ohun ti araalu ba sọ."

O ni bi nnkan ba lọ ni irọwọ rọsẹ o daju pe ẹgbẹ oṣelu NDC ni yoo bori.

Bakan naa lo ṣe abẹwo si oju ooru baba rẹ ko to lọ di ibo.

Araalu yoo dibo fun wa nitori awọn ayipada ti ijọba wa n ṣe lọwọ - Mahamudu Bawumia, Oludije NPP

Igbakeji aarẹ orilẹede Ghana, Ọmowe Mahamudu Bawumia to jẹ oludije fun ẹgbẹ oṣelu NPP pẹlu sọ oe oun naa ni idaniloju lati bori.

Ọmọwe Bawumia pẹlu sọrọ lẹyin to di ibo tirẹ lọjọ Abamẹta.

"Ọkan mi balẹ pe didun lọsan yoo so fun wa, awọn eeyan orilẹede Ghana ti ri ọpọ ayipada ninu igbe aye wọn. Mo si nigbagbọ pe wọn yoo yan ohun to tọ lati le tẹ siwaju loju ọna ilọsiwaju ati idagbasoke."

Ki lajọ eleto idibo n sọ?

Ajọ Eleto idibo Ghana, EC ti fi da awọn ọmọ orilẹede naa loju pe awọn yoo bẹrẹ si ni kede awọn esi ibo lẹkunjẹkun bi wọn ba ṣe n yanju aropọ awọn ibo gbogbo nibẹ.

Ajọ EC ni ohun to n fa idiwọ pẹlu kika ibo ati kikede esi lọwọ yii ni awọn idiwọ ati wahala ti awọn oludibo at'awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan da silẹ lawọn ibudo ikabo kan.

Ajọ eleto idibo naa ni awọn ko tii tẹwọ gba esi idibo kankan lati awọn ẹkun.

Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ń ka ìbò Ààrẹ tó wáyé ní Ghana

Ghana elections

Eto idibo gbogbogbo orilẹde Ghana ti pari bayii, awọn eeyan orilẹede naa si ti n reti ki esi ibo jade.

Ajọ to n ri si eto idibo orilẹede naa, Electoral Commission, nikan lo laṣẹ lati kede ẹni to bori gẹgẹ bi ofin orilẹede naa ṣe gbe kalẹ.

Wayi o, esi ibo ti n wọle lati kaakiri awọn ibudo ti eto idibo ọhun ti waye ṣaaju lọjọ Satide.

Aago marun un irọlẹ ni ibo didi dopi.

Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ èèyàn mẹ́rin tó ṣíná ìbọn bolẹ̀ níbi ìdìbò Ààrẹ Ghana

Ghana election

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọwọ ọlọpaa orilẹede Ghana ti awọn mẹrin kan ti wọn fẹsun kan pe wọn lọwọ ninu iro ibọn to dun lakọlakọ ni Ariwa orilẹede naa lọjọ idibo gbogbogbo.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọhun fi lede lọjọ Abamẹta lo ti kede ọrọ naa.

Atẹjade ọhun ni "Ọwọ ọlọpaa orilẹede Ghana ti tẹ eeyan mẹrin kan lọsan oni, orukọ awọn eeyan naa ni majid Issah, Fodi Issiage kamara, Yakubu Simalia ati Alhajji Bashiru Mohamed lori ẹsun pe awọn lo yinbọn ni Nyankpala to wa ni iha Ariwa."

Ọlọpaa sọ pe eeyan kan lo ba iṣẹlẹ naa lọ, nigba ti ẹlomii farapa nibẹ.

Wayi o, ifọrọwanilẹnuwo ti bẹrẹ fun awọn afurasi ti ọwọ tẹ, ẹni to farapa si ti wa nile iwosan bayii nibi to ti n gba itọju.

Ghana election

Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí a fáwọn iléeṣẹ́ ìròyìn lánfààní láti gbé ètò ìdìbò Ghana sórí afẹ́fẹ́ - Alága àjọ elétò ìdìbò

Aworan John Mahama NDCati Bawumia NPP

Oríṣun àwòrán, John Mahama

Alaga ajọ eleto idibo, EC, lorilẹede Ghana, Arabinrin Jean Mensa, ti kede pe ajọ naa ti fawọn akọroyin lanfaani lati gbe eto idibo orilẹede Ghana sori afẹfẹ.

Arabinrin Mensa ni awọn akoroyin le gbe iroyin lati awọn ibudo idibo to fi de ibudo iko ibo jọ.

Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ ni alaga eleto idibo Ghana fidi rẹ mulẹ ko si nnkan kan to ṣokunkun ninu eto idibo Ghana.

Arabinrin Mensa ni ''gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ pe lati ọdun 1992, nigba ti a ba fẹ kede ẹni to jawe olubori nikan ni a maa n fun awọn ileeṣẹ iroyin lanfaani lati gbe eto idibo sori afẹfẹ.

Ṣugbọn eyi ti yi pada bayii, ko si ibudo idibo tawọn akọroyin ko le de bayii.

Ẹwẹ, Opoku Agyemang to jẹ igbakeji oludije sipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu NDC ti kepe awọn eeyan pe ki wọn tubọ jade si lati dibo.

O ni ọjọ to sẹ pataki ni ọjọ idibo gbogbogbo jẹ loridẹede Ghana eyi to yẹ kawọn ọmọbibi mu ni ọkunkundun.

Àwọn ọlọ́jà kò dá ọjà títà dúró bí ètò ìdìbò gbogbogbò ṣe ń lọ ní Ghana

Aworan awọn ọlọja

Bi eto idibo gbogbogbo ṣe n lọ lọwọ lorilẹede Ghana, bakan naa lawọn ọlọja naa n ta ọja wọn ti wọn ko si jẹ ki eto idibo naa di wọn lọwọ.

Bo tilẹ jẹ pe eyi ko ri bẹẹ lawọn orilẹede Afirika mii, ni Ghana, ẹnikẹni to ba ti dibo tan le pada sẹnu iṣẹ rẹ lai si wahala.

Ajọ eleto idibo orilẹede Ghana ti sọ fawọn araalu ṣaaju tẹlẹ wi pe ki wọn kuro ni ibudo idibo lẹyin ti wọn ba ti dibo wọn tan.

Aworan awọn ontaja
Aworan awọn ontaja
Aworan awọn ontaja
Aworan awọn ontaja

BBC le fidi rẹ mulẹ pe idokowo n lọ kaakiri ilu Accra tii ṣe olu ilu orilẹede Ghana bi eto idibo ṣe n lọ lọwọ

Ètò ìdìbò gbogbogbò ti gbérasọ ní Ghana

Oludibo

Awọn eniyan orile-ede Ghana ti n jade sita lati dibo ninu eto idibo gbogbogboo to n waye.

Eto idibo naa ni wọn yoo ti yan aarẹ wọn tuntun, ati awọn ọmọ ile aṣofin.

Akọroyin BBC jabọ pe, idibo ti bẹrẹ ni ọpọlọpọ ibudo to wa ni olu ilu ẹkun Ashanti, Kumasi.

Oludibo

Igbakeji aarẹ to wa lori oye, Mahamudu Bawumia, ati aarẹ orilẹede naa nigba kan ri, John Mahama, lo n lewaju laarin awọn oludije.

Ọdun 2016 ni wọn dibo yan Nana Akufo-Addo to wa lori oye bayii, yoo si pari saa rẹ lẹyin eto idibo to n bọ lọna.

Awọn ibo wo ni yoo waye lọjọ Abamẹta?

Ibo Aarẹ – oludije mejila n du ipo yii

Ibo awọn aṣofin – awọn oludije kaakiri ẹkun 275 ni Ghana ni yoo kopa ninu rẹ

Nigba wo ni esi ibo naa yoo jade?

Gẹgẹ bo ṣe ṣẹlẹ lawọn eto idibo to ti waye sẹyin, o ṣeeṣe ki a mọ ẹni to jawe olubori lọjọ kẹwaa, oṣu Kejila yii kan naa.

Gẹgẹ bii alakalẹ ofin to rọ mọ eto idibo ni Ghana, esi ibo gbọdọ jade laarin ọjọ mẹta ti eto idibo ba waye nibẹ.

Iléèṣẹ́ ológun sọ pé òun kò nìí kó ọmọ ogun sí ibùdó ìdìbò

Ileeṣẹ ologun orile-ede Ghana sọ pe lootọ ni oun yoo wa ni igbaradi, ṣugbọn ko ni si ọmọ ogun kankan ni ibudo idibo.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun, Aggrey-Quashie, sọ ninu atẹjade kan pe awọn yoo ko awọn ọmọ ogun lọ si awọn agbegbe kan, lati ṣe atilẹyin fun ileeṣẹ ọlọpaa, ki idibo le lọ lai si wahala.