Ọmọ orílẹ̀èdè Ukraine 43,000 ló ti bá ogun Russia lọ – Zelensky

Ukraine
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Aarẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky ti sọ pe apapọ ẹgbẹrun mẹtalelogoji eeyan lo ti jade laye lẹyin ti Russia ko ogun ja orilẹede naa.

Ninu atẹjade kan loju opo ayelujara rẹ, Zelensky ni awọn to ti farapa ninu ogun naa ti le ni 370,000.

O fi kun pe ọmọ ogun Russia 198,000 lo ti pade iku wọn ni Ukraine nigba ti awọn ọmọ ogun 550,000 farapa loju ija.

Bo tilẹ jẹ pe Zelensky funra rẹ lo sọ ọrọ yii, BBC ko tii ṣe iwadii lati fidi iroyin naa mulẹ.

Latẹyinwa ni awọn alaṣẹ lati Kyiv ati Moscow ti maa n kede awọn to farapa tabi ku lọdọ alatako amọ wọn kii fẹ sọrọ pupọ nipa ati awọn ologun ti awọn funra wọn padanu.

Ikede tuntun yii fi han pe ọpọ ọmọ ogun lo ṣubu loju ija ni Ukraine.

Nigba ti Zelensky kede awọn to ku kẹyin ninu oṣu Keji ọdun yii, ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn lo fi lede nigba naa.

Awọn onimọ sọ pe Zelensky fi ikede tuntun yii sita lẹyin ti Aarẹ to n bọ lọna l'Amẹrika, Donald Trump ni ko din ni 400,000 ọmọ ogun Ukrain to ba ogun naa lọ nigba ti Russia padanu ologun 600,000.

Trump ti sọ pe ogun ọhun ko tẹ oun lọrun, oun si ṣẹtan lati fopin si.

Ẹwẹ, ijọba ilẹ Gẹẹsi ti sọ ṣaaju pe ọmọ ogun Russia ti iye wọn le ni 45,000 lo ku ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2024 yii nikan ṣoṣo.

Gẹgẹ bii ohun ti ijọba UK sọ, nnkan bii 1,523 ọmọ ogun Russia lo n padanu ẹmi wọn loju ogun naa lojumọ kan.