'Ọkàn wa ṣẹ̀ṣẹ̀ balẹ̀ báyìí': Aráàlú sọ̀rọ̀ lẹ́yìn táwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ gbàjọba ní Syria

Aworan awọn araalu Syria
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọpọ araalu lo ti bẹrẹ ajọyọ lẹyin ti iroyin jade pe awọn ikọ ologun HTS ti ya wọ olu ilu Syria, Damascus, ti aarẹ Syria si ti sa kuro ilu.

BBC bọ si igboro lati ba awọn araalu sọrọ lori isẹlẹ naa.

Ọkan ninu awọn eeyan to ba wa sọrọ, ẹni to pe orukọ ara rẹ ni Hussein sọ fun BBC pe oun jẹ alatilẹyin Aarẹ Bashar al-Assad. O ni ẹru n ba oun.

"A ko mọ nnkan to ma sẹlẹ ninu ile. Wọn le pw wa, wahala ni," o ṣalaye.

"Ẹnikẹni to ba ṣiṣẹ pẹlu ijọba to kogba wọle tabi ileeṣẹ ologun, wọn ni awọn yoo fun wọn ni anfani lati kuro ni ilu jẹjẹ ṣugbọn ko si ẹni to mọ boya otitọ ni, wọn yoo san gbese ti wọn jẹ."

O ti mu awọn mọlẹbi rẹ pẹlu rẹ sugbọn ko ni iwe irinna lati kuro lọ si orilẹede miiran.

Nigba ti BBC de si Syria. Ọna lọ si Damascus lo wa ni sisi. Bi a sẹ n sumọ olu ilu naa, a ri ami pe awọn ologun ti juwọlẹ- ọpọ ọkọ ileeṣẹ ologun ni wọn ti wa kalẹ. Bakan naa ni a ari aṣọ ologun ti awọn ologun ti ya silẹ.

Ọpọ awọn genge ọkunrin ni a ri ti wọn yinbọn soke, ti wọn si n se ajọyọ gbigba ijọba.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

A ri awọn araalu to n wa ọkọ kiri, ti wọn si sọ pe nnkan yoo yi pada bayiinigba ti Asaad ti lọ. Arugbo kan bu sẹkun.

"Mo dupẹ, mo dupẹ," o bẹrẹ si ni ma gba adura . "Olori buburu ti ṣibu. Olori buburu ti ṣubu!"

Ọpọ mọlẹbi iya yii lo ti ku labẹ ijọba Assad, o sọ pe awọn mii wa ni ọgba ẹwọn.

A ba tọkọtaya pẹlu awọn ọmọ wọn sọrọ, ti wọn ba wa sọrọ pẹlu idunu lọkan wọn.

"Inu wa dun lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti n dari wa. A wa ni ọgb ẹwọn ni ọdun 2014, ti a si ti jade bayii, a dupẹ lọwọ Ọlọrun. A bori nitori awọn ọkunrin wa , awọn ologun, ni bayii a fẹ tun Syria kọ si orilẹede nla.

"A n kesi awọn eeyan wa to wa ni oke okun ti wọn sa kuro pe ki wọn ma pada bọ. "Ọkan ati ile wa ni a ti si silẹ fun wọn."

Awọn araalu yawọ ile Aarẹ tẹlẹ, ji ọpọ nnkan ini rẹ gbe

Ibi ti aarẹ Assad wa ni ko yẹ ọpọ ṣugbọn orilẹede Russia ti kede pe o ti balẹ si ilu Moscow.

BBC kan si ile rẹ, ti a si ri ọpọ awọn araalu to n yawọ ile ni Damascus, ti wọn si n ji ọpọ nnkan gbe lọ.

A ri awọn eeyan to n gbe aga, ti ko si si ẹnikẹni to n da wọn duro. Awọn ikọ ologun to gba ijọba yii mu ominira wa ṣugbọn wọn ko pese aabo.

Àkọlé fídíò, Watch: BBC sees looting at Bashar al-Assad's Damascus residence

Kí ló ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ báyìí lorílẹ̀èdè Syria lọ́wọ́ báyìí?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Olori awọn ọmọ ogun ọlọtẹ to n lewaju ogun ni Syria ni awọn ọmọ ogun rẹ ti gba olu ilu orilẹede naa, Damascus.

Ikọ ologun naa kede pe Syria ti bọ lọwọ adari buburu ti Aarẹ Bashar al-Assad si ti salọ kuro lorilẹede naa.

Eyi ni ibẹrẹ ohun ohun tuntun, HTS sọ lori Telegram.

Awọn eeyan ti Assad ti mọlẹ ti awọn ikọ ologun ni wọn le pada si ile wọn bayii.

"Eyi yoo jẹ orilẹede Syria tuntun nibi ti alaafia yoo ti ma jọba", HTS sọ.

Ọpọ awọn ọmọ orilẹede ti wọn ni lati sa kuro lorilẹede naa ni wọn ti bẹrẹ si ni ma se ajọyọ lori ayelujara.

"Ọlọrun mi, n ko le dakẹ ẹkun. Mo n rọ nipa ọjọ ti ma pada," ajafẹtọ ọmọ niyan, Rima Flihan kọ eyi sori oju opo ikanni Facebook.

Ikọ agbebọn Hayat Tahrir al Sham sisẹ papọ pẹlu awọn ikọ miiran ti wọn si ti gba iṣakoso ọpọ ilu to fi mọ Aleppo, Hama ati Deraa lati igba ti rogbodiyan naa ti bẹrẹ lọsẹ to kọja.

Erongba wọn ni lati da ijọba Aarẹ al-Assad ru.

Bo ti lẹ jẹ pe ileeṣẹ Aarẹ Syria ni iroyin ẹlẹjẹ ni pe awọn ti kuro ni olu ilu naa.

Ileeṣẹ aarẹ ni awọn sisẹ ṣugbọn ko si ẹnikẹni to ri awọn, ti eyi lo si fa ti awọn araalu fin n yẹ iwọle ati ijade wo ni orilẹeede naa lati mọ boya arẹ ti japa.

Minisita fun ọrọ abẹle lorilẹede Syria ni awọn ni ileeṣẹ ologun layika Damascus, ti ko si si bi wọn ṣe fẹ wọle.

Ibẹruboju ti balẹ si gbogbo agbegbe Damascus, ti gbogbo oju ọna si da paroparo.

Akọroyin kan to n gbe ilu naa ni awọn eeyan ni ilu naa ti kọkọ jade ṣugbọn onikaluku ba ẹsẹ rẹ sọrọ nigba ti wọn iroyin pe awọn ikọ ologun HTS ti yawọ ilu naa.

"Ọpọ sọọbu lo ti wa ni titi pa. Mo gbiyanju lati wọ inu sọọbu kan, wọn ni awọn ti palẹmọ. Awọn araalu n tiraka lati ra ounjẹ sile.

Fọnran lori ayelujara ṣafihan ni awọn eeyan se n se ajọyọ lẹyin ti wọn wo ere baba aarẹ to wa ni guusu Jeramana.

Aarẹ orilẹede Amẹrika, Donald Trump ni "Syria ko dara,ṣugbọn wọn ko ki n se ọrẹ wa.

"Ko yẹ ki orilẹede Amẹrika ni ajọsepọ kankan pẹlu Syria. Ko ki n se ija wa. Ẹ jẹ ko ma lọ, ẹ ma finu si ."

Aworan awọn araalu

Oríṣun àwòrán, Reuters