Èlò yóò na láti ṣe ètò ìdìbò àti láti borí ìdìbò ní Ghana?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Komla Adom
- Role, Senior Journalist, BBC News Pidgin
- Reporting from, Accra
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Eto idibo ti di ohun to nilo ọpọlọpọ owo ni ilẹ Afrika.
Ọpọ eeyan lo n kọminu lori owo ti wọn fi n se eto idibo ati ajọsepọ to ni pẹlu awọn oludije.
Awọn amoye ni, gbogbo ọna nioṣelu fi faaye gba iwa ibajẹ lawujọ.
Ileeṣẹ kan to n risi iwadii CDD ti bẹrẹ si ni ma pariwo ikilọ pe ọpọ owo ti awọn eeyan yii na lo gba ọna eburu wa paapa ni orilẹede tí wọn ko ki n se iwadii nípa orisun owo ipolongo.
Ni ọdun 2022, orilẹede Kenya na owo toto $383m fun eto idibo, ọkan to gara julọ lagbaye.
Lorilẹede Naijiria, Ajọ INEC ṣe akọsilẹ owo toto N313.4b fun eto idibo ọdun 2023.
Bakan naa, South Africa na owo toto R2.302b lati se amojuto eto idibo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Elo yoo na lati ṣe eto idibo Ghana?
Ni ọdun 2020, ajọ eleto idibo Ghana na owo to le ni GH 760m lati fi se eto idibo ni akoko ti gbogbo awọn oludibo jẹ milọnu mẹtadinlogun.
Ajọ eleto idibo Ghana EC na owo to to GH 365m lori iforukọsilẹ awọn oludibo pẹlu afikun GH 80m ati GH 288 lati fi se eto idibo ni ọdun naa.
Ajo eleto idibo tun ni awọn na GH 28m lori idanilẹkọọ awọn oludibo.
Lẹyin ọdun mẹrin, ile igbimọ aṣofin buwọlu GH 786.9m fun ajọ eleto idibo lati se eto idibo ọdun 2024.
Ajọ naa tun tí bẹrẹ fun afikun GH 140m, owo ti wọn ni ti ko ba kun owo eto idibo, yoo nira lati se eto idibo, Osei Kyei Mensah Bonsu sọ fun ile igbimọ aṣofin ni oṣu Kejila ọdun 2023.
Ajọ eleto idibo ṣe atupalẹ bí wọn ṣe fẹ na owo naa fun eto idibo
- GH 200m fun iforukọsilẹ awọn oludibo
- GH 323m fun ṣiṣe eto idibo
- Apapọ jẹ GHC 543m

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bawo lo ṣe wọn to lati bor ninu eto idibo ni Ghana?
Ileeṣẹ to n ṣe iwadii ni ọdun 2021 ni, o to GH 1.5b lati bori ninu eto idibo aarẹ Ghana.
Oludari ileeṣẹ naa, Kojo Asante sọ fun BBC pe owo naa pọ.
"Gbogbo awọn to wa ninu ijọba ni wọn jẹ gbese nítorí ẹnikẹni to ba se atilẹyin fun wọn n retí kan pada.
O ṣalaye pe fun ọpọ ọdun sẹyin ni awọn eeyan ro pe ti awọn ba se onigbọwọ fun awọn oloṣelu, wọn ma ni ajọsepọ nla pẹlu ijọba.
Iwadii naa tun ni fun eeyan lati bori ninu eto idibo fun ile igbimọ aṣofin, yoo ni lati na owo to to GH 9m.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Owo ti awọn Oludije yoo na lati fi ṣe ipolongo ibo
Owo ẹgbẹ oselu: Owo ti ẹgbẹ oselu meji to n lewaju fun eto idibo ọdun yii fun ile igbimọ aṣofin lo jẹ GH 45,000 fun ẹgbẹ oselu NDC ati GH 90,000 fun ẹgbẹ oselu NPP, ti owo ti ipo Aarẹ si jẹ GH 530,000 fun NDC ati GH 90,000 fun NPP.
Owo ajọ eleto idibo: Ajọ eleto idibo n gba owo toto GH 100,000 fun foomu Aarẹ ati GH 10,000 fun obinrin.
Owo ipolongo: Ọpọ awọn ẹgbẹ oṣelu lo n lọ kiri lati se ìpolongo ibo lori atẹgun. Owo ti ọpọ n na lo jẹ GH 4,000 si GH 100,000.
Owo agbegbe: Ọpọ awọn Oludije yoo ma n wa ọna lati tu awọn araalu loju tí wọn yoo si ma ọpọ ìṣe akanṣe.
Owo toto GH 10,000 ni wọn ma n na.
Ipolongo ibo/Rira Ibo: Eyi na jẹ ọkan ninu ohun tó n gba owo lọwọ Oludije ibo.
Owo fun alamojuto ibo fun ẹgbẹ oselu

Oríṣun àwòrán, Getty Images












