Makinde ṣí aṣọ lójú ẹ̀rọ amúnáwá tí yóò máa tan iná ọba fún àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Oyo

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti ṣe afihan abala akọkọ ẹrọ amunawa oni mẹgawaati mọkanla ti yoo maa tan ina ọba fun awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ.
Ninu ọgba ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ to n bẹ ni agbegbe Agodi niluu Ibadan ni akanṣe eto naa ti waye lọjọ Ẹti.
Lasiko to n sọrọ ni ibi ipejọpọ naa, Kọmisana fun ohun amuṣagbara, Amofin Temilolu Aṣamu ṣe alaye pe ọdun 2019 ni igbesẹ ti bẹrẹ lati wa ojutuu si ipenija ina ọba ni ipinlẹ Ọyọ. Lati igba naa si ni wọn ti n ṣe ipese ina to n lo agbara oorun, iyẹn 'Solar' jakejade ipinlẹ naa.
O ni igbiyanju lati mu ki anfani naa kari ipinlẹ Ọyọ lo ṣe atiwaye afihan ẹrọ amunawa ti wọn ṣe lonii.
Aṣamu fi kun ọrọ rẹ wi pe ipinlẹ Ọyọ jẹ ọkan lara awọn ipinlẹ mẹfa lorilẹede Naijiria to n gbe iru igbesẹ yii.
Ninu ọrọ tiẹ, Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ni ipinlẹ Ọyọ ti bẹrẹ igbesẹ lati maa pese ina ọba fun ara rẹ lati inu oṣu kejila ọdun 2021 ko to di pe ijọba apapọ fun awọn ijọba ipinlẹ ni anfani lati maa pese ina ọba fun ara wọn l'ọdun 2023.
Makinde tẹsiwaju wi pe ajọṣepọ pẹlu ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ lo mu ko di irọrun lati sọ aba ipese ina ọba di ofin ninu oṣu keji ọdun yii.
O ni bii ọdun kan gbako ni awọn fi ṣofo lori igbiyanju lati gba aṣẹ lọwọ ajọ to n ṣe akoso ina ọba lorilẹede Naijiria, 'The Nigerian Electricity Regulatory Commission (NERC)' ki wọn to ri aṣẹ gba fun abala ẹrọ amunawa ti wọn ṣe afihan rẹ lonii, ṣugbọn lati akoko yii lọ, abẹ akoso ijọba ipinlẹ Ọyọ ni iru aṣẹ naa yoo wa.
Makinde dupẹ lọwọ gbogbo awọn eniyan ati oludokoowo to fi ọwọ sọwọpọ pẹlu ijọba rẹ fun aṣeyọri ileeṣẹ ti yoo maa pese ina ọba fun awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ.
Lati inu oṣu kejila ọdun 2021 ni ijọba ipinlẹ Ọyọ ti gbe igbesẹ lori ipenija to n koju ina ọba n'ipinlẹ naa. Akanṣe eto ipesẹ ina ọba eleyii ti ileeṣẹ to n pelo ina ọba, 'Elektron Energy' ṣe agbekalẹ rẹ lo na ijọba ipinlẹ Ọyọ ni owo ti o to Billiọnu Mẹjọ Naira.
Abala akọkọ ni Gomina Makinde ṣiṣọ loju rẹ lonii, awọn ibi ti yoo si maa tan ina si ni, ọfisi Gomina ipinlẹ Ọyọ to n bẹ ni agbegbe Agodi, Ilu Ibadan ati ayika rẹ, awọn ibubo eto ilera mejila ọtọọtọ.
Lara awọn ibudo ti ọwọja ina naa yoo de ni ile iwosan Adeoyo, ile iwosan ijọba to n bẹ ni agbegbe Ring Road, papa iṣere Lekan Salami, ile ẹjọ giga to n bẹ ni agbegbe Ring Road, ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, ati awọn ile ẹkọ kọọkan to n be ni agbegbe ibi ti ẹrọ naa yoo maa tan ina si.
Iṣẹ ṣi n tẹsiwaju lori awọn agbegbe ti o ku ni ipinlẹ Ọyọ

Ọkanojokan alejọ pataki lo pejupesẹ si ibi akanṣẹ eto naa. Lara wọn ni awọn lọbalọba jakejado ipinlẹ Ọyọ, awọn aṣoju ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ, awọn aṣoju ileeṣẹ ologun ati ẹgbẹ awujọ. Awọn igbakeji Gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Ọyọ naa ko gbẹyin ni ibi ipejọpọ naa.
Lọjọ kẹsan an oṣu kẹfa ọdun 2023 ni Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu buwọlu agbekalẹ ipinka ina ọba ti o si fun awọn ijọba ipinlẹ ni anfani lati maa pẹsẹ ina ọba ni awọn ipinlẹ wọn.
Lati igba naa si ni awọn ijọba ipinlẹ ni ọkanojọkan ti n gbe igbesẹ lati pese ina ina ọba. Yatọ si ipinlẹ Ọyọ ti o ṣe afihan abala akọkọ ipese ina ọba lonii, laipẹ yii ni ijọba ipinlẹ Eko naa buwọlu igbesẹ lati bẹrẹ sini pese ina ọba, gẹgẹ bi ijọba ipinlẹ naa ṣe n ke si awọn ileeṣẹ aladani to n pese ina ọba lati ṣe amulo anfani naa.












