Kí ni ìṣubú ìṣèjọba Assad túmọ̀ sí fáwọn èèyàn Syria tó ń ṣe àtìpó nílẹ̀ òkèrè?

Oríṣun àwòrán, Reuters
- Author, Sanaa Alkhoury
- Role, BBC Arabic
- Author, Fundanur Öztürk
- Role, BBC Turkish
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
Níṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Syria tó wà ní agbègbè Altindag, ẹkùn kan ní Ankara, orílẹ̀ èdè Turkey bẹ̀rẹ̀ sí ní gba ijó, tí wọ́n ń kọrin, tí inú wọn sì ń dùn lẹ́yìn tí ìròyìn jáde pé wọ́n ti gba ìjọba lọ́wọ́ Bashar al-Assad.
"Inú mi ń dùn gidigidi – igba àkọ́kọ́ tí inú mi yóò dùn tó báyìí láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn rèé," èyí ni ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu Asif, ọ̀dọ́mọkùnrin tí ọjọ́ orí rẹ̀ wà láàárín ogún ọdún, tó jẹ́ ọmọ ìlú Hama ní orílẹ̀ èdè Syria tó mú àsíá orílẹ̀ èdè Turkey àti ti ẹgbẹ́ alátakò ní Syria dání.
"A ò sùb láti alẹ́ àná. Mi ò lè sọ bí inú mi ṣe dùn tó. Kò sí ẹni tó máa dúró níbi mọ́. Gbogbo èèyàn ló fẹ́ padà sílé nítorí ogun tó ń lọ ní orílẹ̀ èdè wa ti parí. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Turkey gidigidi."
Ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀, Ayham tí òun náà jẹ́ ọmọ Aleppo náà fi èrò yìí hàn.
"A ò lè padà nítorí ìwà ọ̀dájú Assad. A bọ́ lọ́wọ́ Assad, a sá kúrò nílé nítorí a ò fẹ́ kí ó fi tipátipá mú wa láti ṣekúpa àwọn èèyàn wa àmọ́ nígbà tí gbogbo rẹ̀ ti parí báyìí, à ń padà sílé."
Ẹlòmíràn tí òun náà ti ń gbé ní Turkey fún ọdún mẹ́rìnlá ní òun gbèrò láti padà sí Syria àti pé òun ti ṣetán láti padà báyìí.
"Kò sí nǹkankan tó kù fún wa mọ́ níbi. Àsìkò ti tó láti padà sí Syria. A máa lọ tún ìgbé ayé wa bẹ̀rẹ̀ kódà kó túmọ̀ sí pé a máa bẹ̀rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ padà. Lónìí tí mo pinnu láti ṣe ìgbéyàwó ni Syria gba òmìnira, mi ò ní gbàgbé ọjọ́ yìí láéláé."
Bákan náà ni àwọn èèyàn ń dáwọ́ ìdùnnú ní àwọn agbègbè táwọn èèyàn Syria pọ̀ sí ní Turkey tó fi mọ́ Istanbul. Ní Sisli, àwọn èèyàn tò síwájú ilé iṣẹ́ Syria tó wà níbẹ̀, tí wọ́n sì ń fa àsíá ibẹ̀ ya.
Àwọn ọmọ Syria tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́ta ni wọ́n ń ṣe àtìpó ní Turkey láti ìgbà tí ogun abẹ́lé ti bẹ̀rẹ̀ ní Syria lọ́dún 2011.

Oríṣun àwòrán, Azra Tosuner / BBC
Ìbẹ̀rù
Pẹ̀lú bí inú àwọn èèyàn ṣe ń dùn, kìí ṣe gbogbo èèyàn ló wù láti padà sílé ní kíákíá.
Ní Berlin, Rasha, ti gbàgbọ́ nínú ọkàn rẹ̀ pé òun kò lè rí àwọn ẹbí òun tó wà ní Damascus mọ́.
Láti bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn, ogun tó ń wáyé ní Syria ti mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn bíi Rasha gbàgbọ́ pé àwọn kò lè ní ìbáṣepọ̀ kankan pẹ̀lú àwọn tó ti wáyé sẹ́yìn mọ́.
Fún Rasha, ìdùnnú rẹ̀ dàpọ̀ mọ́ ìrònú. Ohun tó wù ú lọ́kàn ni láti kó gbogbo ẹrù rẹ̀ kó sì padà sílé àmọ́ ó ní ọ̀rọ̀ náà gbà èrò gidigidi.
"Mo mọ̀ pé kò sí ìpayà lórí pé èèyàn kan yóò fi poro òfin gbé wa láì nídìí mọ́ ní ẹnubodè àmọ́ ti ìpinnu wa gba èrò tó lágbára."
Ohun kan tó tún ń ṣe ìdènà fún ìpinnu Rasha jẹ́ ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣàtìpó ní Germany. Ó kú ọdún kan fún un láti gba ìwé ìgbélùú, èyí tí yóò fún un ní àǹfàní láti máa rìn sí ibi tó wù ú ní Germany.
Ó ní ó wu òun láti padà sí Syria láì pàdánù gbogbo nǹkan tí òun ti jẹ àǹfàní rẹ̀ láti ìgbà tí òun ti wà ní Germany bíi èdè, ẹ̀kọ́ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
"Tí mo bá padà báyìí láì ní ìwé ìgbélùú, ó ṣeéṣe kí n pàdánù gbogbo nǹkan yìí."
Bákan náà ni ipò táwọn èèyàn rẹ̀ wà ní Damascus jẹ́ ohun tó ń kọ ọ́ lóminú.
"Kó tó di àná, mo máa ń rò ó pé mi ò lè rí ilé wa mọ́ àmọ́ ìrètí ti wà fún mi báyìí."
Ó ní inú òun dùn pé ìjọba Assad ti lulẹ̀ àmọ́ ìbẹ̀rù ṣì gba ọkàn rẹ̀ pé tí àwọn alákatakítí ẹ̀sìn míì bá dìde ńkọ́.

Oríṣun àwòrán, WAEL HAMZEH/EPA-EFE/REX/Shutterstock
Rasha jẹ́ ọ̀kan lára èèyàn mílíọ̀nù mẹ́rìnlá tó fi ilé wọn sílẹ̀ nígbà tí ogun bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 2011. Gẹ́gẹ́ bí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ṣe sọ, ogun yìí ló sọ ọ̀pọ̀ èèyàn di aláìnílé mọ́ jùlọ lásìkò yìí.
Èèyàn mílíọ̀nù márùn-ún tó jẹ́ ọmọ Syria ló ń ṣe àtìpó ní Turkey, Lebanon, Jordan, Iraq àti Egypt. Germany, táwọn ọmọ Syria tó wà níbẹ̀ jẹ́ 850,000 ni orílẹ̀ èdè tí kò sún mọ́ Syria táwọn èèyàn tó ń ṣe àtìpó tún pọ̀ sí.
Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aṣàtìpó, gbígbé ní ilẹ̀ òkèrè jẹ́ ìpèníjà ńlá fún wọn nítorí àwọn ìṣòro tí wọ́n kojú àti ìbẹ̀rù bojo.

Oríṣun àwòrán, EPA-EFE/REX/Shutterstock
'Return will not be simple'
Pípadà kò lè rọrùn
Ayah Majzoub tó jẹ́ igbákejì adarí ẹkùn Middle East and North Africa ní àjọ Amnesty International tẹmpẹlẹmọ pé pípadà sílé kò lè rọrùn.
Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó fẹ́ padà sílé ni wọ́n ti pàdánù ilé wọn, iṣẹ́ àtàwọn èèyàn wọn.
"Ètò ọrọ̀ ajé Syria ni ogun tí ṣàkóbá fún. Àwọn àjọ ẹlẹ́yinjú àánú gbọ́dọ̀ ṣe àrídájú rẹ̀ pé ààbò wà fún àwọn tó wù láti padà sílé, wọ́n nílò ibùgbé, oúnjẹ, omi àti ètò ìlera."
Majzoub tún sọ pàtàkì rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ fi tipátipá lé àwọn èèyàn padà sí orílẹ̀ èdè wọn, pé ó gbọ́dọ̀ tí ọkàn àwọn tó fẹ́ padà sílé wá ní.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Fún Mahmoud Bouaydani, ẹni tó ń ṣe àtìpó ní Turkey, Iroyin láti Damascus ṣe ìrántí àwọn ohun tó ti wáyé sẹ́yìn fún un.
Ó ní ṣe ló dàbí pé òun ń wo àwòrán àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn, bí wọ́n ṣe ń fi kẹ́míkà ṣe ìkọlù àti àdó olóró láti ojú òfurufú.
Ọdún 2018 ló dá kúrò ní Douma lẹ́yìn tó ti wà ní àhámọ́ fún ìgbà pípẹ́, tó sì ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ Komputa ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Kocaeli University lẹ́bàá Istanbul.
"Ohun àkọ́kọ́ tó wá sọ́kàn mi ni ilé ẹbí wa. A ò mọ ohun tó ti ṣẹlẹ̀ si báyìí, bóyá wọ́n ti tà á láì sí ìmọ̀ sí wa."
Mahmoud ní àfojúsùn láti parí ẹ̀kọ́ rẹ̀. "Mo fẹ́ ṣe àbẹ̀wò sí Syria ná àmọ́ mo fẹ́ mọ bí ètò ààbò, ìṣèjọba ṣe rí ná. Mi ò fẹ́ fi ààbò tí mò ń rí níbí tafala tàbí pàdánù ètò ẹ̀kọ́ mi.
Ní ìlú Zarqa ní Jordan, Um Qasim ní ọdún méjìlá ni òun ti lò gẹ́gẹ́ bí aṣàtìpó. "Àwọn èèyàn gbà wá tọwọ́ tẹsẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjò ni àjò yóò máa jẹ́."
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gbèrò láti padà sí Syria, ó kọminú lórí ipò ọrọ̀ ajé ibẹ̀ báyìí. Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn òun tó wà ní Syria ló wà nínú ìnira nítorí àìsí iná, omi, ọ̀wọ́n gógó àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
"Inú wa dùn pé ìṣèjọba ti wà sópin àmọ́ kí kúrò ní Jordan, lẹ́yìn àwọn nǹkan tí a ti kó jọ níbí yóò nira."

Oríṣun àwòrán, EPA-EFE/REX/Shutterstock
Ní ẹnubodè Masnaa ní Lebanon, lógún lọ́gbọ̀n àwọn ọmọ Syria ló ti tò síbẹ̀ tí wọ́n fẹ́ kọjá láti padà sí Syria.
Lebanon ni àwọn aṣàtìpó pọ̀ sí jùlọ ní àgbáyé.
Dalal Harb, tó jẹ́ agbenusọ àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ní Lebanon sọ pé àwọn ṣe àkíyèsí pé àwọn èèyàn ti ń padà sí Syria.
Ó ní àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UNHCR ní ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn ni láti padà sí orílẹ̀ èdè rẹ̀ nígbà tó bá wù ú.
Harb ṣàlàyé pé àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé ṣetán láti ṣe ìrànwọ́ fún ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ padà sí Syria àtàwọn tó bá fẹ́ lọ wo bí nǹkan ṣe rí ná.
Fún ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn Syria, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ jẹ́ ohun tó wúwo tó wà lọ́kàn wọn. Àwọn ìrántí ogun, pípàdánù ohun ìní wọn ṣì gba ọkàn wọn, tí wọ́n sì ń ṣọ́ra lórí bí nǹkan yóò ṣe rí tí wọ́n bá padà sí Syria.












