Ṣé lóòótọ́ ni pé àwọn Igbo kìí ta ilẹ̀ fún àjòjì?

Oríṣun àwòrán, BBC/Getty Images
Ní ẹnu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni awuyewuye kan gbà orí ayélujára nígbà tí akọ̀ròyìn iléeṣẹ́ Arise TV kan, Reuben Abati sọ lórí bí àwọn ẹ̀yà Igbo ṣe ń ra ilẹ̀ káàkiri.
Ó sọ lórí ètò kan pé àwọn ẹ̀yà Igbo kìí tá ilẹ̀ fún àjòjì ní ìlú wọn.
Ọ̀rọ̀ yìí fà awuyewuye lórí ayélujára níbi tí àwọn kan ti ń sọ pé ìbanilórúkọ jẹ́ ni ẹ̀sùn náà táwọn mìíràn sì gba nǹkan tí Abati sọ gbọ́.
Èyí ló mú kí BBC ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ ni mo ní ní ìpínlẹ̀ Enugu – Alhaji Nura

Oníṣòwò kan tó ń gbé ní agbègbè Ugwu ní ìpínlẹ̀ Enugu, Alhaji Nura tó jẹ́ ọmọ ìlú Durse ní ìpínlẹ̀ Jigawa sọ fún BBC pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilẹ̀ àti ilé ni òun ní ní ìpínlẹ̀ Enugu.
Nura sọ pé ìpínlẹ̀ Enugu ni wọ́n bí òun sí, tí òun sì ti ń gbé ibẹ̀ láti ọgọ́ta ọdún lé díẹ̀.
Nígbà tí a bi pé báwo ló ṣe ra àwọn ilẹ̀ rẹ̀ tó wà ní Enugu, ó ṣàlàyé pé kò sí nǹkan tí èèyàn kò lè rà níwọ̀n ìgbà tí owó bá ti wà.
"Ọ̀rọ̀ lórí owó ni, ẹni tó bá ní owó lọ́wọ́ yóò ra ilẹ̀, tí èèyàn kò bá sí ní owó lọ́wọ́, kò lè rí ilẹ̀ rà.
"Nígbà tí bàbá-bàbá mi dé sí Enugu, ó ra ilẹ̀ tó fi kọ́ ilé. Ilé ọgbọ̀n ló kọ́ sí Enugu kó tó jáde láyé.
"Lẹ́yìn tó kú tán, àwọn ọmọ rẹ̀ tá ilé àti ilẹ̀ tí wọ́n jogún lọ́wọ́ rẹ̀, tí wọ́n sì kó lọ sí agbègbè Ugwu."
Alhaji Nura ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ni òun ní Enugu, ọ̀kan ní Ogui Road, òmíràn ní Owerre Road àti ní Ogidi Lane.
Ó ní èyí tí ó wà ní Awusa jẹ́ èyí tí òun jogún lọ́wọ́ bàbá-bàbá òun.
Ó wòye pé kò sí òótọ́ nínú ọ̀rọ̀ pé àwọn Igbo kìí fẹ́ tá ilẹ̀ fún àwọn tí kìí bá ṣe ẹ̀yà nítorí pé ó gbàgbọ́ pé ọ̀rọ̀ gbogbo lórí owó ni.
Ó fi kun pé tó bá jẹ́ pé oko náà ni èèyàn fẹ́ rà, àwọn olórí ìlú ló tọ̀nà kí èèyàn lọ rí láti ra ilẹ̀ bẹ́ẹ̀.
Ṣe àwọn tó ń ta ilẹ̀ máa ń ṣe ẹlẹ́yàmẹ̀yà?

Onyebuchi Igboke tó jẹ́ oníṣòwò ilé àti ilẹ̀ títà ní Enugu sọ pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún òun nígbà tí èèyàn kan wá bá òun pé wọn kò tá ilẹ̀ fún òun nítorí òun kìí ṣe ẹ̀yà Igbo.
Ó ní tí ẹnikẹ́ni tí kìí bá ṣe Igbo bá fẹ́ ra ilẹ̀ kí wọ́n wá bá òun, pé wọ́n máa rí ilẹ̀ rà.
Igboke ṣàlàyé pé kò sí ìgbà kankan tí àwọn kò tá ilẹ̀ tàbí ilé fún èèyàn rí nítorí ẹ̀yà onítọ̀hún.
Ó sọ pé lóòótọ́ ni àwọn kan máa ń ṣe ìwádìí láti mọ irú èèyàn tí wọ́n fẹ́ ra ilẹ̀ fún.
"Àwọn èèyàn yìí máa ń bèèrè lọ́wọ́ wá pé ṣé kìí ṣe ẹni tó le dá wàhálà sí àwọn lọ́rùn ni àwọn fẹ́ tá ilẹ̀ fún."
Ó ní èyí ló máa ń mú àwọn ọmọ onílẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ nígbà mìíràn, láti ṣe ìwádìí ẹni tí àwọn bá fẹ́ tá ilẹ̀ fún.
Ó sọ pé tí kò bá ti ṣí ìbẹ̀rù yìí, kò sí ẹni tí àwọn kò lè ta ilẹ̀ fún láì fi ẹ̀yà tàbí nǹkankan ṣe.
Kí ni àṣà ẹ̀yà Igbo lórí ilẹ̀ títà?

Àgbà oyè kan ní Duruagwu ní Okpurutongi ní ìjọba ìbílẹ̀ Ikeduru ìpínlẹ̀ Imo, Olueze Ukaejuoha ní àṣà Igbo kò fàyè gba ilẹ̀ títà.
Olueze ní àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun ló mú àṣà ilẹ̀ títà wọ agbègbè àwọn.
Ó ní ìran Igbo kìí ta ilẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ bíkòṣe pé wọ́n máa ń fún èèyàn tàbí fi san gbèsè tàbí kí wọ́n fi ra nǹkan míì.
"Ìgbàgbọ́ ẹ̀yà Igbo ni pé ẹni tó bá tá ilẹ̀ yóò kojú ìṣòro nítorí ilẹ̀ kìí ṣe ohun ìní tí èèyàn máa ń tà.
"Ohun àjogúnbá ni ilẹ̀, kò sí nínú àṣà Igbo láti máa ta ilẹ̀ láti ọdún pípẹ́ "
Àmọ́ ní báyìí ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ta ilẹ̀ nítorí owó, wọ́n ń ta ilẹ̀ fún ẹnikẹ́ni láì fi ẹ̀yà tàbí ohunkóhun ṣe.












