Trump ṣe ìlérí láti fòpin sí fífún ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá bí sí America ní ìwé ìgbélùú tó máa ń sọ wọ́n di ọmọ onílùú tẹ́lẹ̀

Aworan Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lorilẹede Amẹrika, Donald Trump ni oun yoo darijin awọn eeyan to lọwọ ninu isẹlẹ to waye ni ọdun 2021 nigba ti rogbodiyan bẹ silẹ kete to ba pada si ọfisi ni oṣu to n bọ.

"Awọn eeyan yii n gbe ninu inira," o sọ fun NBC ninu ifọrọwerọ akọkọ to sẹ lẹyin to wọle ninu oṣu kọkanla.

Bakan naa ni Trump ni oun yoo fopin si gbigba iwe igbe ilu fun awọn ẹnikẹni ti wọn ba bi si orilẹede Amẹrika ṣugbọn ti ki n ṣe ọmọ ilu.

O ni oun yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu Democrats lati pese iranlọwọ fun awọn arin irinajo ti wọn ko forukọ silẹ nigba ti wọn wa si Amẹrika.

Ninu ifọrọwerọ naa, Trump ni ọpọ aṣẹ ni oun yoo buwọlu, ti ti to fi mọ eto ọrọ aje, irinajo lẹyin ti wọn ba bura wọle fun ni Ogunjọ oṣu kinni ọdun 2024.

Lori ọrọ iwe igbe ilu

Trump sọ fun NBC ni oun yoo gbe igbesẹ lati fopin si nini anfani si iwe igbe ilu nitori wọn bi eeyan si ilu.

"A ni lati yi pada," Trump sọ.

"A lati pada wa jabọi fun awọn eeyan ṣugbọn a ni lati fopin si."

Trump ni oun setan lati tẹle ohun ti oun sọ lasiko to n polongo ibo pe oun yoo da awọn eeyan ti wọn forukọ silẹ pada si orilẹede wọn paapa awọn to ni mọlẹbi ni Amẹrika.

"N ko fẹ tu mọlẹbi ka, lati ma le tu mọlẹbi ka ni pe ka le gbogbo wọn pada si orilẹede wọn."

N ko ni lati tako Biden pe o forijin ọmọ rẹ

Trump tun jẹ ko di mimọ pe igbesẹ Aarẹ Joe Biden fun bi o ṣe lo ofin forijin ọmọ rẹ Hunter lori iwa ibajẹ.

Trump ni oun ko ni ṣe iwadii kankan lori Biden ati mọlẹbi rẹ.

"N ko lero lati pada si ẹyin. Mo gbaju mọ ilọsiwaju orilẹede wa.

Ṣugbọn o ni awọn amofin to ṣe iwadii rẹ lo yẹ ki wọn lọ si ẹwọn.

Bakan naa ni Trump ni oun ko ni paṣẹ fun ajọ FBI pe ki wọn ṣe iwadii awọn ọta rẹ ṣugbọn o ṣeeṣe ko ṣe bẹ ti wọn ba wuwa lodi si ofin.

Awọn nnkan mii ti Trump sọ

  • O ni ti ajọ North Atlantic Treaty Organization NATO ba se daada pẹ orilẹede Amẹrika,oun bẹẹrẹ ni ma duro sinu ẹgbẹ naa.
  • Trump ni oun ko ni fio ofin de ogun isẹyun ṣugbọn o tun jẹ ko di mimọ pe nnkan le yi pada.
  • O ni ki orilẹede Ukraine ma reti nnkan lọwọ Amẹrika ti oun ba sipo lọdun to n bọ.
  • Nigba ti wọn bi pe boya yoo fowokun owo ori fun awọn onisowo, o ni oun ko le sọ ohunkohun