Kenya ṣetán láti gbàlejò ìdíje CHAN 2024 pẹ̀lú àwọn orílẹ́èdè méjì míì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Celestine Karoney
- Role, BBC Sport Africa, Nairobi
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Orilẹede Kenya ṣetán láti gbalejo idije ere bọọlu CHAN 2024, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan n kọminu lori igbaradi orilẹede naa fun idije ti yoo bẹrẹ lọjọ kinni oṣu Keji ọdun 2025.
Papa iṣere meji ti i ṣe Papa iṣere Nyayo ati Papa iṣere Kasarani ni Kenya fẹ lo fun idije ti wọn fẹ gbalejo pẹlu orilẹede Tanzania ati Uganda.
Ọpọ lo n sọ pe Kenya le ma lanfaani lati gbalejo idije naa mọ lẹyin ti ajọ CAF ṣabẹwo awọn papa iṣere ti wọn fẹ lo.
Minisita ere idaraya ni Kenya, Kipchumba Murkomen sọ fun BBC pe orilẹede Kenya yoo sa gbogbo ipa rẹ lati gbalejo idije naa.
Igba akọkọ niyi ti orilẹ-ede mẹta yoo jọ gbalejo idije CHAN.
Iroyin kan sọ pe Kenya, Tanzania ati Uganda fẹ gbalejo idije CHAN lati fi le gbaradi fun igbalejo idije AFCON 2027.
Kenya ko ni papa iṣere kankan ti CAF fontẹ lu ni oṣu Kejila ọdun 2023 ti wọn kede awọn orilẹede ti yoo gbalejo idije CHAN.
Tanzania ni tiẹ ni papa iṣere kan ti CAF fontẹ lu nigba naa.
Minisita ere idaraya ni Kenya sọ pe "ọpọlọpọ nkan to yẹ ki a fi ọkọ oju omi ko wa ni a n lo baalu lati ko wa.
Ati pe tọsan torun ni awọn oṣiṣẹ n ṣiṣẹ bayii lori awọn papa iṣere ti a fẹ lo.
Awọn eto kan ti wa lati ti ri pe orilẹede Kenya gbalejo idije CHAN ati Afcon lẹyin naa."
Murkomen ni ajọ CAF ni yoo sọ papa iṣere ti ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba ninu CHAN yoo ti waye.
Kenya ti kuna lati gbalejo idije ere bọọlu tẹlẹ ri

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Anfaani ati gbalejo idije AFCON ọdun 1996 bọ mọ Kenya lọwọ lẹyin ti orilẹede naa sọ fun CAF wi pe oun ko tii wa ni igbaradi.
South Africa lo pada gbalejo idije ọhun lọdun naa.
Iru nkan yii lo tun ṣẹlẹ lọdun 2017 nigba ti Kenya padanu anfani lati gbalejo idije CHAN.
Adari igbimọ CAF to n ri si awọn orilẹede to fẹ gbalejo idije, Kabelo Bosilong, sọ fawọn akọroyin lẹyin àbẹwò igbimọ naa ni Kenya pe ajọ CAF ṣetan lati ri pe awọn idije ere idaraya waye l'awọn orilẹede to ti yẹ ki wọn waye.
Kenya yoo na to $20m fun atunṣe papa iṣere at'awọn ohun elo ere idaraya mii.
Ọpọ lo n kọminu lori owo ti ijọba fẹ na yii papaa julọ pẹlu bi awọn ẹka ijọba mii ṣe nilo amojuto.
Laipẹ yii ni awọn olukọni lẹka eto ẹkọ gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ.
Murkomen ni "gbogbo igba lawọn araalu maa beere pe ki lo de ti ijọba fi fẹ nawo to pọ to yi lori igbalejo ere idaraya.
Amọ, ohun ti ijọba maa n ro ni awọn anfaani to le tibẹ jade.
A tun le lo o lati jẹ ki ẹka Irinajo afẹ wa gbe pẹẹli si.
Bakan naa, gbigba alejo iru idije yii yoo tun jẹ ki ẹka ere idaraya wa dagba si."















