Agboola Ajayi gba ilé ẹjọ́ lọ, ó ní èsì ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo kò tẹ́ òun lọ́rùn

Oríṣun àwòrán, Agboola Ajayi
Oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo gomina to kọja nipinlẹ Ondo, Agboola Ajayi ti gba ile ẹjọ lọ lati tako esi ibo naa.
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu to kọja ni eto idibo naa waye, ti ajọ eleto idibo, INEC, si kede gomina Lucky Aiyedatiea gẹgẹ bii ẹni to bori ninu eto idibo naa.
Gẹgẹ bii ọrọ INEC, ibo 366,781 lo gbe Aiyedatiwa wọle, nigba ti Ajayi ni apapọ ibo 117,845.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu awọn akọroyin niluu Akure ni Ajayi ti fidi rẹ mulẹ pe awọn agbẹjọro oun ti pe ẹjọ tako esi ibo naa.
Amọ ṣa, o kọ lati ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa ipẹjọ ọhun.
Oludije ẹgbẹ oṣelu PDP naa sọ pe oun ko framọ esi ibo gomina ti INEC, o si fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu to wọle pe ṣe ni wọn ra ibo ti wọn si dunkoko mọ awọn oludibo lawọn agbegbe kan.
Ajafi fi kun pe esi ibo naa kii ṣe ifẹ inu awọn eeyan ipinlẹ Ondo.
O wa ke si ile igbimọ aṣofin agba lati ṣe atunṣe si ofin eto idibo to kan ẹrọ Bimodal Voter Accreditation System, BVAS, eyii to sọ pe awọn kan ti ti ọwọ bọ.
Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹ naa sọ pe oun gbagbọ pe idajọ ododo yoo waye lẹyin ipẹjọ ti oun pe nitori awọn araalu lẹtọọ lati yan ẹni ti ọkan wọn n fẹ sipo gomina lai si idunkokomọni kankan.
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti ile ẹjọ giga kan niluu Akure kọkọ da ẹjọ Ajayi nu, ninu eyii to ti pe iwe ẹri Aiyedatiewa ati igbakeji rẹ nija.
Ile ẹjọ naa sọ pe ko pe ipẹjọ akọkọ naa bo ṣe tọ ati pe ipẹjọ ọhun ko lẹsẹ nilẹ.















