Iléẹjọ́ kọ̀ láti gba béèlì Dele Farotimi, sún ìgbẹ́jọ́ sí ogúnjọ́ oṣù Kéjìlá

Ile ẹjọ ti wọgile ẹbẹ fun beeli ti ajafeto-omoniyan to tun je onkọwe, Amofin Dele Farotimi gbe ka iwaju rẹ lori ẹsun ibanilorukọjẹ ti agba amofin ni, Aarẹ Afẹ Babalọla pe.
Lẹyin wakati bii mẹta ati abọ ti igbẹjọ naa fi waye ni ile ẹjọ Majisireeti kan ni ilu Ado Ekiti ti ṣe olu ilu ipinlẹ Ekiti lọjọ Iṣẹgun, adajọ majisireeti to gbọ ẹjọ naa ni ko tii le si aaye beeli fun Dele Farotimi bayii. O wa sun igbẹjọ naa si ogunjọ oṣu kejila.
Adajọ Magistrati Abayomi Adeosun to gbọ ẹjọ naa paṣẹ ki wọn da Farotimi pada sinu atimole lọgba ẹwọn titi di igba ti wọn yoo fi gbe idajọ kalẹ lori boya ki olujejo naa maa ti ile wa jẹjọ.
Nigba ti olori iko agbejoro to n duro fun Afẹ Babalola nile ẹjọ naa, Owoseeni Ajayi n sọrọ, o salaye wipe, wọn ti satunṣe awọn ẹsun ti wọn fi kan olujejo naa, bee ni wọn kaa si i leti lasiko igbẹjọ ọhun.

Ninu ọrọ tirẹ, Kọmureedi Kehinde Steven bu ẹnu atẹ lu bi adajọ naa ṣe kọ lati fi aye silẹ ki wọn gba beeli afurasi naa.
Kehinde tun bu ẹnu atẹ lu Amofin agba Afe Babalola fun ohun to pe ni lilo ọwọ agbara lori iṣẹlẹ naa.

Elomiran naa to jẹ ajafeto-omoniyan, Tunde Ajofoyinbo gbarata lori bi awọn janduku ṣe pọ ni ayika ile ẹjọ naa.
Ajofoyinbo tọka sii pe ko ni si aaye fun ẹnikẹni lati wa domi alaafia ipinle Ekiti ru, ati wipe ko ni saaye fun ẹnikẹni lati tapo si aso aala Amofin Afe Babalola ni ipinlẹ Ekiti.
Amọ, kete lẹyin ti eto igbẹjọ naa pari tan, awuye wuye rampe kan waye laarin awọn to tẹle Dele Farotimi wa pelu awọn kọọkan to wa soju fun Aarẹ Babalola nile ẹjọ naa.















