Àwọn èèyàn kan ṣekúpa arúgbó 110 lórí ẹ̀sùn pé àjẹ́ ni wọ́n

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O kere tan aadọfa agbalagba l'awọn eeyan kan ti ṣekúpa lorilẹede Haiti lori ẹsun pe ajẹ ni wọn.
Ẹgbẹ ajafẹtọọ RNDDH fidi rẹ múlẹ pe ilu Port-au-Prince tii ṣe olu ilu orilẹede naa ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Ẹgbẹ RNDDH ṣalaye pe olori ẹgbẹ awọn eeyan to ṣiṣẹ laabi yii gbero lati ṣekúpa awọn agbalagba naa lẹyin ti ọmọkunrin rẹ kan ku.
Ile adahunṣe ti ọkunrin naa lọ ni wọn ti sọ fun un pe awọn agbalagba ajẹ lo wa nidi aisan to n ṣe ọmọ rẹ.
Ajọ iṣọkan agbaye UN sọ pe o ti di ẹgbẹrun marun un eeyan t'awọn oniruuru ẹgbẹ apanle ti ṣekupa lọdun yii lorilẹede Haiti.
Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye
Adari ẹka ẹtọ ọmọniyan fun ajọ UN, Ọgbẹni Volker Turk sọ pe awọn to ba iṣẹlẹ naa ko din ni eeyan 184 lopin ọsẹ to kọja.
Ohun ti a gbọ ni pe awọn ọmọ ẹgbẹ oniwa ipa naa ṣadeedee le awọn agbalagba ti ọjọ ori wọn ti ju ọgọta ọdun jade lati inu ile wọn lagbegbe Wharf Jeremie, ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn fun wọn.
Bakan naa l'awọn kan ninu ẹgbẹ ọhun tun gun wọn lọbẹ t'awọn miran si n ṣa wọn ni ada titi ti ẹmi fi bọ lara wọn.
Awọn olugbe ilu naa sọ pe ni ṣe l'awọn ri bi wọn ṣe jo ara eeyan nina kaakiri loju titi.
Ẹgbẹ ajafẹtọọ RNDDH sọ pe eeyan ọgọta ni wọn pa lọjọ Ẹti, nigba ti aadọta eeyan mii tun lọ si i lọjọ Abamẹta.
Awọn kan tiẹ tun sọ pe awọn ẹgbẹ yii tun ṣekupa awọn ọdọ kan to fẹ gba awọn agbalagba naa silẹ.
Awọn ẹgbẹ ajafẹtọọ sọ pe orukọ ọkunrin to paṣẹ wi pe ki wọn maa pa awọn agbalagba naa ni Monel Felix ti ọpọ mọ si Mikano.
Mikano ni a gbọ pe o jẹ gaba lagbegbe Wharf Jeremie ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.
Awọn olugbe agbegbe naa sọ fun ileeṣẹ iroyin ni Haiti pe awọn ọmọ ẹgbẹ Mikano dina mọ awọn lati kuro ni agbegbe Wharf Jeremie ki iroyin iṣẹlẹ naa ma baa le tan kalẹ.
Iṣẹlẹ iṣekupani ti wọpọ lati ọdun 2021 ti wọn ti pa aarẹ Haiti tẹlẹ, Jovenel Moise.
Ẹwẹ, awọn ọlọpaa ilẹ̀ okeere ti de si Haiti loṣu Kẹfa to lọ lati ṣe iranlọwọ fun ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede naa.
Amọ, ijọba ko rowo lati ra awọn irinṣẹ ti wọn nilo lati le koju awọn ẹgbẹ oniwa ipa to n ṣọṣẹ ni Haiti.
Bakan naa, igbiyanju igbimọ to n ṣiṣẹ lati ṣeto idibo ti araalu yoo fi dibo yan aarẹ mii ko tii so eso rere.















