Ṣé lóòótọ́ ni pé ìjọba àpapọ̀ ti wọ́gilé pápákọ̀ òfúrufú ìlú Ede?

Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ninu oṣu Kọkanla ọdun yii ni ijọba ipinlẹ Ọṣun kede pe papakọ ofurufu ti wọn gbero lati kọ si Ido-Osun tẹlẹri yoo di gbigbe lọ si ilu Ede.

Igbakeji gomina Osun to fidi ọrọ naa mulẹ lori eto redio kan niluu Osogbo ṣalaye pe ijọba pinnu lati gbe papakọ ofurufu ọhun lọ silu Ede tori ko si ilẹ to le to fun kikọ papakọ ofurufu nla naa ni Ido-Osun nibi ti wọn fẹ kọ ọ si tẹlẹ.

Ṣugbọn lọjọ kẹwaa, oṣu Kejila ọdun 2024 yii ni iroyin mii tun lu sita wi pe ijọba apapọ ti wọgile igbesẹ lati gbe papakọ ofurufu naa lọ si ilu Ẹdẹ.

Iroyin naa tọka rẹ wi pe ẹka ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si idagbasoke irina ofurufu lo wọgile ayẹyẹ ifilọlẹ papakọ ofurufu naa.

Iroyin naa tẹsiwaju pe igbesẹ lati wọgile ayẹyẹ ifilọlẹ papakọ ofurufu ọhun lo waye nipasẹ

Ọkanojọkan iwe ẹdun ọkan ti awọn eeyan kan kọ si jọba apapọ lori erongba lati gbe papakọ ofurufu naa kuro ni ibi to yẹ ki o wa.

Ninu iwe kan ti wọn kọ ranṣẹ si Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke lọjọ kẹfa, oṣu kejila, ọdun yii, akọwe ẹka ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si idagbasoke irina ofurufu fi aibalẹ ọkan han lori aratunra awọn ohun elo ati awọn ohun alumọni ti yoo ṣofo nipasẹ igbesẹ ijọba ipinlẹ Ọṣun.

Ileeṣẹ naa tẹpẹlẹ mọ lilo owo ilu ati awọn ohun alumọni awọn eeyan ilu bi o ti tọ, ati bi o ti yẹ.

Nitori idi eyii si ni ẹka ileeṣẹ ijọba apapọ naa fi so gbogbo igbsẹ rọ, lori papakọ ofuru naa.

OSSG

Oríṣun àwòrán, OSSG

Ki ni ijọba ipinlẹ Osun sọ lori ọrọ yii?

BBC Yoruba kan si Kọlapọ Alimi ti o jẹ Kọmisana fun iroyin ati ilanilọyẹ n'ipinlẹ Ọṣun lati gbọ t'ẹnu rẹ lori ọrọ yii.

Alaye ti o ṣe fun akọroyin wa ni pe ijọba ipinlẹ Ọṣun ko gbọ ohunkohun to niiṣẹ pẹlu igbesẹ lati wọgile papakọ ofurufu ilu Ẹdẹ, bẹẹ sini wọn ko gba lẹta kankan lati ọwọ ijọba apapọ.

Alimi ni ijọba apapọ ko le di ipinlẹ Ọṣun lọwọ lori ọrọ papakọ ofurufu naa nitori pe apọnle lasan ni bi wọn ṣe ranṣẹ si ijọba apapọ lati wa ba wọn ṣide akanṣe iṣẹ naa.

O ni to ba jẹ wi pe l'otitọ ni ijọba apapọ kọ iwe ranṣẹ si ipinlẹ Ọṣun lọjọ kẹfa oṣu kejila ọdun yii, yoo to ọjọ kẹtala oṣu yii ki o to de ipinlẹ Ọṣun.

Alaye ti o ṣe siwaju ni pe boya awọn to kọ lẹta naa ni wọn lu iroyin sita, ṣugbọn iṣẹ ti wọn ran ko tii de ipinlẹ Ọṣun.