Wo bàbá tó dèrò àgọ́ ọlọ́pàá lẹ́yìn tí ìyàwó rẹ̀ fẹ̀sùn kàn án pé òun ló ṣekúpa ọmọ oṣù méjì fi ṣògùn owó

Oríṣun àwòrán, Others
Taiwo Ifagbenga, ẹni to pe ara rẹ ni babalawo ti dero atimọle ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fun ẹsun ṣiṣekupa ọmọ rẹ, to jẹ ọmọ ọjọ mọkanlalogoji lati fi ṣe etutu ọla.
agbegbe Keesi ni Adatan ni ilu Abeokuta tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ogun lẹkun iwọ oorun gusu Naijiria ni iṣẹlẹ naa ti waye lọjọ Aje.
Gẹgẹ bi iroyin ti a gbọ ṣe sọ, Raimat Wasilat to jẹ iya ọmọ naa tẹ ẹ si ori ibusun lati le raaye lọ fọ aṣọ ni iwaju ile wọn, amọ nigba ti yoo fi wo fẹrẹ ori ọmọ tuntun jojolo naa ti di awati.
Fọnran kan to lu sita lori ayelujara ṣe afihan bi ọpọ ero ṣe pọ biba ni ita ile ti iṣẹlẹ naa ti sẹlẹ.
Iya ọmọ ọhun sọ pe ni kete ti oun fọ aṣọ tan, ti oun yoo fi pada si inu ile ni oun rii pe wọn ti ge ọrun ọmọ naa, to si fi ọmọ naa silẹ ninu agbara ẹjẹ.
Alabagbe kan ni agbegbe naa, Iyafin Adewumi, ninu fọnran fidio kan to tẹ awọn oniroyin lọwọ ṣalaye pe: "Ariwo ni mo gbọ, ti mo si wa si ile naa lati wa wo ohun to sẹlẹ.
o fi kun un pe nigba ti awọn wọ inu ile ọhun ni wọn kofiri pe eeyan kan ti gba oju ferese wọle sinu yara naa to si ge ọrun ọmọ ikoko naa.
"Iya ọmọ n fọ aṣọ ni ita lasiko naa ko to di pe o wọle , to si ri ọmọ rẹ to ti ku, ni ọmọ to bi ni ọjọ mọkanlelogoji sẹyin."
Bakan naa, Mukaila Olaide, baba iya ọmọ ṣalaye ohun ti oju rẹ ri.
"A wa ni tosi ile wọn ni a ṣa dede gbọ ariwo. Ariwo naa ni a tọ de ile wọn , ti a si ri pe wọn ti ge ọrun ọmọ ikoko.
"Ileeṣẹ ọlọpaa ti wa mu iya ati baba ọmọ lọ si agọ wọn bayii."
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Omotola Odutola ni iya ọmọ fẹsun kan baba ọmọ pe oun lo ṣekupa ọmọ ikiko.
"Iya ọmọ, Raimat Wasilat, lati Keesi, ni ọkọ rẹ, Ifagbenga Taiwo, ẹni to kọ iṣẹ awo ni oun furasi.
"O ni ọkọ oun fẹ fi ọmọ se etutu ọla ni.
"Afurasi naa lo ti wa ni ahamọ, ti iwadi si ti bẹrẹ . A ti gbe oku lọ si ile iwosan fun ayẹwo."















