Ọkùnrin tó lọ sun ilé ọ̀rẹ́ rẹ̀ jóná mọ́lé ní Ilorin

Kawara fire

Oríṣun àwòrán, Kwara fire service

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Baale ile ẹni ọdun mọkanlelogoji kan, Abdulfatai ti ṣagbako iku ojiji nibi iṣẹlẹ ijamba ina kan to waye loru mọju ọjọ Aje, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kejila, ọdun 2024.

Abdufatai yii la gbọ pe, o n gbe ni Agboole Alatẹ, Abayawo niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

Iroyin ni o lọ sun ile ọrẹ rẹ to wa ni agboole Aláparun ni ilu Ilorin ki ọlọjọ to de baa.

Ohun ti a gbọ ni pe ijamba ina naa sẹlẹ ni nkan bii ago meji oru ṣugbọn nigba ti awọn ti wọn jọjọ wa ninu ile ri aye sa asala fun ẹmi wọn, Abdulfatai ko ri anfani, ti o si ku sinu eefin ina ọhun.

Ninu fọnran ti ajọ panapana fi lede, a ri oloogbe ọhun to fọrun kọ iganna nibi to fẹ gba jade lati doola ẹmi ara rẹ ṣugbọn inu igbiyanju naa ni ẹmi rẹ bọ si.

Bakan naa ninu fọnran ọhun, a gbọ ohun ọkunrin kan to ṣeese ko jẹ ohun ọrẹ rẹ to gbaa sile, to n sunkun, to si ke bosi pe, "mo ṣi oore se".

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ pe, bi awọn ara adugbo ṣe kẹẹfin eefin ina ọhun ni wọn ke si ileeṣẹ panapana ṣugbọn ile naa ti jona kọja sisọ ki awọn panapana too de ti eefin ina si ti ṣekupa Abdulfatai.

Alàyè iléeṣẹ́ panápaná lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Ninu atẹjade kan ti alukoro fun ileeṣẹ panapana nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Hassan Hakeem Adekunle, fi sita, o ti fidi rẹ mulẹ pe, eeyan kan lo padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ina ọhun.

O ni awọn ti gbe oku ọkunrin naa le awọn mọlẹbi rẹ lọwọ.

O ṣalaye pe ni nnkan bii aago meji aabọ idaji ọjọ Aje, ni awọn araalu pe ileeṣẹ naa lori nọmba ẹrọ ibanisọrọ pajawiri wọn, awọn ko si fi ọrọ naa falẹ rara tawọn si gbera lati lọ pa ina ọhun.

Adekunle, fi kun ọrọ rẹ pe yara marunlelọgbọn lo wa nibi ile naa ṣugbọn marun-un lo jona deeru nigba tawọn doola yara to n lọ bii ọgbọn niye.

O ni, iwadii awọn fi han pe ijamba ina naa bẹrẹ lati inu yara kan ti wọn ko awọn nkan bi epo rọbi pentiro, batiri, taya, enjini ati bẹẹ bẹẹ lọ pamọ si.

Alakoso ajọ naa ni Kwara, Ọmọ Ọba Falade John, ti wa rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara, ki wọn maa wa ni ojulalakan fi n sọri nigba gbogbo ki wọn si jina si gbogbo awọn ohun to le ṣokunfa ijamba ina lati le dena pipadanu ẹmi ati dukia