Dúkìá ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù ṣòfò níbi ìṣẹ̀lẹ̀ iná tó jó lọ́jà Alaba Rago l'Eko

Oríṣun àwòrán, AFP
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2
Ina to jo laarọ Ọjọru lọja Alaba Rago niluu Eko ti ba dukia ẹgbẹẹgbẹ miliọnu jẹ.
Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko sọ ninu atẹjade to fi sita pe loru ni ina ọhun bẹrẹ.
Ko si ẹni to mọ ohun to ṣokunfa ijamba ina yii titi di akoko yii.
Ọmọwe Femi Oke-Osanyintolu to jẹ ọgagba ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko ṣalaye pe kete ti ajọ naa gbọ nipa ọja ti ina ti n jo lawon oṣiṣẹ pajawiri ti lọ sibẹ.
O ni ki awọn oṣiṣẹ pajawiri to de inu ọja naa, ina ti bẹrẹ si ni mu awọn ṣọọbu to wa ninu ọja naa.
Amọ, Ọmọwe Oke-Osanyintolu ni kete tawon oṣiṣẹ pajawiri de ọja naa ni wọn bẹrẹ si pa ina ọhun.
O tun fidi rẹ múlẹ pe awọn eeyan kan naa yatọ s'awọn oṣiṣẹ pajawiri gbiyanju lati pa ina ọhun.











