Ọ̀gọ̀rọ̀ èrò wọ́de tako bí àwọn kan ṣe ń ṣekú pa àwọn obìnrin, Ọlọ́pàá yín tajútajú

Aworan lati ibi iwọde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ẹni ori yọ o di ile ni ohun to waye lasiko yi ileeṣẹ ọlọpaa Kenya yin tajutaju si awọn oluwọde to n se iwọde tako bi wọn ṣe n ṣekupa awọn obinrin lorilẹede Kenya.

Iṣẹlẹ yii waye ni ọjọ kẹrindinlogun ti iwọde naa ti n waye lorilẹeede Kenya.

Ajọ iṣokan agbaye ni lọdun 2023, o le ni obinrin 140 pẹlu awọn ọdọmọbinrin ti awọn mọlẹbi wọn to sunmọ tabi ọrẹkunrin wọn ṣekupa lagbaya ni ojojumọ.

O to eeyan mẹta to wa ni ahamọ ọlọpaa lorilẹede Kenya bayii, ti awọn olugbọwọ iwọde naa si fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa pe wọn kọ lati buwọlu ipe wọn lati se ifẹhonuhan.

"A bere fun anfani ṣugbọn wọn kọ, wọn ni aarẹ ti fun wa lowo, ti awọn ko si ri idi fun wa lati se ifẹhonuhan ,"Onigbọwọ iwọde naa, Njeri Migwi sọ fun BBC.

Ni O ṣu Kọkanla, Aarẹ William Ruto ni ijọba n sa gbogbo agbara lati fopin si bi iṣekupa obinrin to wọpọ lorilẹeede naa, ti ijọba si ti na owo toto 800,000 dọla lati se ipolongo eyi ti wọn pe ni "Safe Home, Safe Space".

Awọn onigbọwọ iwọde yii ti lewaju fun ọpọ iwọde lorilẹede Kenya , paapa eyi to waye ni oṣu kini.

Bakan naa ni wọn pe fun opin si iṣekupa obinrin, ti wọn si tun bere fun ijiya nla fun aqwọn ti wọn ba ka pẹlu iwa naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Kenya ninu atẹjade kan sọ pe o diẹ diẹ ni ọgọrun un ni iye isẹlẹ iṣekupa obinrin ti awọn ṣe akọsilẹ rẹ laarin oṣu mẹta.

.