Mọ̀ nípa ìgbésẹ̀ tuntun tí ìjọba Amẹ́ríkà gbé kalẹ̀ fún àwọn ọmọ Nàìjíríà tó fẹ́ gba Físà

Oríṣun àwòrán, Others
ileeṣẹ aṣoju ijọba orilẹede Amẹrika lorilẹede Naijiria ti kede awọn atunṣe tuntun to de ba ilana gbigba iwe aṣẹ irinajo lọ si Amẹrika.
Gẹgẹbi ileeṣẹ aṣoju ijọba orilẹede Amẹrika lorilẹede NAijiria ṣe sọ, ọjọ kini oṣu kini ọdun 2025 ni igbesẹ ilana tuntun yii yoo bẹrẹ
Ẹka naa tun ṣalaye siwaju sii pe, ẹnikẹni to ba to n forukọ silẹ lati gba ontẹ fisa lati rinrinajo l sorilẹede Amẹrika lati Naijiria yoo ni lati se abẹwọ si ọfiisi aṣoju agba fun ijọba orilẹede Amẹrika to wa nilu Eko ni igba meji ọtọọtọ lasiko ti wọn n se eto Fisa gbigba wọn
Ikede yii wa loju opo ayelujara X ileeṣẹ aṣoju ijọba Amẹrika ni Naijiria.
"Fun awọn eeyan ti wọn ni idanwo ifọrọwerọ lẹyin ọjọ kiini oṣu kinni ọdun 2025, ni lati wa si ọdisi Consulate General niluu Eko ni o kere ju ẹẹmeji lati ti wọn n ba se Fisa.
"Igbesẹ tuntun ni yoo pese iranlọwọ fun igbaradi ifọrọwewrọ ati lati ma jẹ idaduro kankan waye lasiko ti wọn n ba se Fisa.
"Igbesẹ yii yoo jẹ ki awọn to nifẹ lati rin irinajo lati ri awọn iwe ẹri ti wọn ba nilo to sọnu pada ṣaaju ki wọn to lọ fun ifọrọwerọ.
Ifọrọwerọ keji ni yoo waye pẹlu ọkan ninu awọn oṣiṣẹ wa. Ọjọ ti yoo waye fun awọn to ba forukọ silẹ ni a fi to wọn leti.
"Ti o ko ba buwọlu iwe 'In-Person Document Review' ṣaaju ki o to lọ fun ifọrọwerọ, o nilo lati tun ṣe ni ọjọ miiran."
Ninu oṣu keje ni ajọ yii kede pe awọn yoo bẹrẹ si ni ma fun awọn eeyan ni Fisa ni ilu Abuja ati ilu Eko, bẹrẹ lati ninu oṣu kẹjọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















