Bamidele f'ọwọ̀ tẹ ọyán, ló bá rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá he

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileẹjọ to n gbọ ẹsun ibalopọ ati ifiyajẹni labẹle niluu Eko ti sọ ọkunrin kan, Bamidele Folorunsho, si ẹwọn ọdun mẹwaa, nitori ọyan obinrin to fọwọ tẹ lọna aitọ.
Adajọ Rahman Oshodi to gbe idajọ naa kalẹ lọjọ kọkanla, oṣu Kejila ọdun 2024, n'Ikeja, sọ pe gbogbo ẹri lo foju han pe Bamidele jẹbi.
Gẹgẹ bi kootu ṣe ṣalaye, wọn ni ọmọ ọdun mejila pere ni ọmọbinrin ti Bamidele tẹ lọmu.
Yatọ si pe o tẹ ọmu ọmọ ti ko ti i da nnkan kan mọ bẹẹ, wọn lo tun fọwọ ra ibi iho idi ọmọde naa, o ba a ṣere bii pe agbalagba obinrin ni.
Iwa yii lodi si ofin ipinlẹ Eko, ijiya si wa fun un; bo tilẹ jẹ pe olujẹjọ ti kọkọ taku pe oun ko jẹbi.
Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an?
Oṣu keji ọdun 2018 ti iṣẹlẹ yii waye ni wọn kọkọ fi ẹsun pe o tẹ ọyan, o si fọwọ ra iho idi ọmọ ọdun mejila, kan Bamidele Folorunsho.
Wọn fi i si ahamọ lọjọ kejilelogun, oṣu kẹta ọdun 2018 naa.
Ninu oṣu kẹwaa ọdun 2021 ti wọn gbe e wa si kootu lo tun ni oun ko jẹbi.
Ṣugbọn nigba ti wọn tun fẹẹ gbọ ẹjọ naa l'Ọjọru ọsẹ yii, agbenusọ ijọba lori ẹjọ naa, O. Aluko, sọ fun kootu pe Bamidele fẹẹ bẹ kootu fun aanu.
O ni olujẹjọ naa ti gba pe oun jẹbi, o si ṣetan lati faramọ ẹwọn ọdun mẹwaa ti Adari idajọ nipinlẹ Eko, Ọmọwe Babajide Martins, buwọ lu.
Adajọ Rahman Oshodi, beere lọwọ Bamidele pe ṣe itumọ ẹbẹ to n bẹ ye e, ati pe ṣe o mọ ijiya ti ofin la kalẹ fun ẹni to ba hi iru iwa yii.
Ninu idahun rẹ ni Bamidele ti sọ pe o ye oun yeke.
Lẹyin naa ni wọn ka awọn ẹsun naa si etigbọọ rẹ lẹẹkan si i, o si dahun pe oun jẹbi looootọ.
Adájọ́ gbé ìdájọ́ kalẹ̀
Abala 135 ati 236 ti ofin iwa ọdaran nipinlẹ Eko, ti ọdun 2015, lodi si ẹsun ti olujẹjọ n jẹjọ rẹ.
Eyi ni Adajọ Oshodi sẹ sọ ninu idajọ rẹ pe, '' mo ri i pe o jẹbi nigba ti mo wo ẹbẹ ti o bẹ lọjọ Kọkanla, oṣu Kejila ọdun 2024 yii.
''Mo ti farabalẹ wo ẹbẹ ti o bẹ, ati bi o ṣe fi han pe o kabaamọ ohun ti o ṣe.
"Mo sọ ọ si ẹwọn ọdun mẹwaa, eyi to bẹrẹ lati ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta ọdun 2018.
Ki orukọ rẹ si wọ iwe gẹgẹ bi ọdaran to huwa tako ibalopọ."














