Ọ̀rọ̀ ìṣẹ́ kò ká àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà lára, orí ayélujára ni wọ́n ń fojojúmọ́ ń jóko sí - Pásítọ̀ Tobi Adegboyega Spac Nation
Laipẹ yii ni okiki kan pe ijọba ilẹ Gẹẹsi n gbero lati da eekan ọmọ Naijiria kan to jẹ ilu mọọka nibẹ, Pasitọ Tobi Adegboyega pada wa si Naijiria.
Ohun ti iroyin naa sọ nigba naa ni pe wọn iwe igbelu rẹ ni baa ninu.
Pasitọ Adegboyega ṣalaye fun BBC pe ọrọ ọhun lọwọ kan oṣelu ninu ni.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, bi ọrọ ṣe ri kọ lawọn to gbe iroyin naa kiri ṣe ro o.
O ni ki oun to si ilu mọọka lohun ti de si ilẹ Gẹẹsi gẹgẹ bi ọpọ to lọ sibẹ fun igbe aye ọtun. O ni oun ro pe awọn ti oun gbe ara ti nigba naa ti yanju eto gbogbo to yẹ ni, amọ nigba ti oun yoo mọ si, ti oun si gbimọran lati gbe awọn igbesẹ gbogbo to tọ, oun ti di ilumọọka nigba naa.
Pasitọ Adegboyega ni eyi fun awọn kan to n ri oun ni iri ẹni to fẹ yi awọn lagbo oṣelu da sina lanfaani lati dide ogun.
Awọn ọdọ to n ṣako ni mo n tọ sọna, - Pasitọ Tobi Adegboyega

Oríṣun àwòrán, tobi adegboyega/ instagram
Iranṣẹ Ọlọrun naa tun ṣalaye siwaju sii pe nigba ti oun de ilu oyinbo ti oun ri bi ọpọ awọn ọdọ to jẹ alawọ dudu, paapaajulọ awọn ọmọ Naijiria ṣe n gbe igbe aye wọn bi aguntan ti ko loluṣọ lo mu ki pun gbe igbesẹ lati ṣe itọnisọna fun wọn pẹlu ironilagbara to loorin lati lee mu ki wọn wulo fun ara wọn ati orilẹede agbaye lapapọ.






