Afe Babalola: Ta ni agbẹjọ́rò àgbà tí orúkẹ rẹ̀ ń milẹ̀ tìtì ní Naijiria?

Afe Babalola

Oríṣun àwòrán, Afe Babalola

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ eeyan kaakiri Naijiria lo ti bẹrẹ si n jẹ ọrọ Afe Babalola lẹnu lẹnu lọlọ yii.

Eyii ko ṣẹyin ẹsun ibanilorukọjẹ to fi kan agbẹjọro, Dele Farotimi, ti igbẹjọ rẹ ti n lọ lọwọ niluu Ado Ekiti.

Lọṣẹ to kọja ni awọn ọlọpaa mu fFrotimi ninu ọọfisi rẹ to wa niluu Eko lori ẹsun naa ko to foju bale ẹjọ l'Ekiti.

Lara ẹsun ti Farotimi n jẹjọ rẹ lọwọ ni biba orukọ Babalola jẹ ninu iwe rẹ to kọ, iyẹn 'Nigeria and its Criminal Justice System'.

Amọ ṣa, Farotimi ti sọ pe oun ko jẹbi gbogbo ẹsun mẹrindinlogun ti wọn fi kan oun.

Lẹyin naa ni ile ẹjọ ju afurasi naa si ahamọ ọgba ẹwọn ki igbẹjọ rẹ to tẹ siwaju.

Wayi o, ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori ọrọ naa.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe awọn ri ọrọ naa bii igba ti eeyan n lo agbara le ẹni ti ko lagbara lori ni ẹjọ naa jẹ, lawọn mi n sọ pe ṣe ni Farotimi kọja aye rẹ, to si gbọdọ jẹ iya to tọ labẹ ofin.

Gbgobgo awuyewuye ẹjọ yii lo mu ki ọpọ ọmọ Naijiria maa jẹ ọrọ Afe Babalola lẹnu lori ayelujara.

Ta ni Afe Babalola?

Oniṣowo ati agba ọjẹ agbẹjọro ni Babalola jẹ ni Naijiria.

Oun ni oludasilẹ fastiti Afe Babalola to wa nilu Ado Ekiti, nipinlẹ Ekiti.

Gẹgẹ bii agbẹjọro, ọpọ aṣeyọri ni Babalola ti ṣe, o si ti bori oniruru igbẹjọ fun awọn alẹnulọrọ lawujọ ni Naijiria.

A gbọ pe o le ni ọọdunrun agbẹjọro to ti gba abẹ Babalola kọja ni Naijiria, lara wọn na awọn adajọ ati agbẹjọro agba ipinlẹ, bẹẹ ni ileeṣẹ rẹ jẹ ọkan lara awọn eyii to ti lọwọ si idagbasoke ẹka eto idajọ ni Naijiria.

Ọdun 1987 ni Babalola di agbẹjọro agba, SAN.

Yatọ si pe o jẹ agbẹjọro, o tun jẹ oloju aanu to maa n ṣe iranlọwọ fun awọn eeyan.

Awọn ohun rere to ti gbeṣe

  • O gba oye agbẹjọro agba Naijiria, SAN (1987)
  • O gba oye Officer of the Federal Republic (OFR)
  • O gba oye Commander of the Order of the Niger (CON)
  • Alaga awọn alabojuto fasiti ilu Eko, UNILAG, laarin ọdun 2001 si 2007
  • Oludasilẹ ati adari agba Afe Babalola University, Ado-Ekiti (ABUAD)
  • Ami ẹyẹ Queen Victoria Commemorative, ni Oxford, UK
  • Oye imọ ofin ni fasiti ilu London, Eko, Ekiti, ati bẹẹ bẹẹ lọ