Wo àwọn ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu tó milẹ̀ tìtì lọ́dún 2024

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Laarin oṣu Kinni si oṣu Kẹsan an, ọdun 2024 yii, o le ni ẹgbẹrun meji abọ eeyan to foju bale ẹjọ lori oniruru ẹsun iwa ajẹbanu ati lilu owo ilu ni ponpo ti EFCC fi kan wọn.
Ninu awọn ti EFCC gbe lọ sile ẹjọ atawọn ti wọn fẹsun kan lawọn ọmọ yahoo to n lu jibiti ori ayelujara atawọn oloṣelu.
Lara awọn ẹsun to gbajumọ julọ ni ti awọn oloṣelu ti EFCC n ka obitibiti owo mọ lọwọ tabi fẹsun kan pe wọn na owo ilu lọna ti ko yẹ.
Iwọnyii lawọn ẹsun iwa ajẹbanu to mi Naijiria titi ninu ọdun 2024
Yahaya Bello lori ẹsun iwa ajẹbanu to le ni aadọfa biliọnu Naira, (₦110.4b)

Oríṣun àwòrán, Yahaya Bello
Kayeefi nla lo jẹ fun ọpọ araalu lasiko ti EFCC kede pe oun n wa gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, Yahaya Bello.
Ninu atẹjade kan ti EFCC fi le loju opo itakun agbaye rẹ lo ti kede ọrọ naa.
EFCC sọ pe owo to le ni ₦110b ni Bello lu ni ponpo.
Lara awọn iwe kan ti ajọ naa fi lede lo ti ṣafihan bi afurasi naa ṣe na owo ọhun.
Iwe naa fi han pe Yahaya Bello san ẹgbẹlẹgbẹ owo gẹgẹ bii owo ile ẹkọ ọmọ rẹ fun ọdun mẹwaa si asiko yii, bo tilẹ jẹ pe ọmọ naa ko tii wọ ile ẹkọ naa.
Nigba to yẹ ki igbẹjọ rẹ bẹrẹ, Bello kọkọ salọ ki ọwọ to pada tẹ ẹ, to si fojubale ẹjọ.
Wayi o, afurasi naa ti wa ni ahamọ ọgba ẹwọn bayii nibi ti yoo maa gba lọ ile ẹjọ lati jẹjọ rẹ, lẹyin ti ile ẹjọ kọ beeli rẹ.
Godwin Emefiele lori ẹsun iwa ajẹbanu to le ni miliọnu meji dọla owo ilẹ Amẹrika ati ọpọlọpọ dukia

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin ti Aarẹ ana, Muhammadu Buhari kuro lori alefa ni ẹnu bẹrẹ si n kun gomina banki apapọ tẹlẹ, Godwin Emefiele.
Ṣaaju ni ọpọ ọmọ Naijiria ti kọkọ n binu si Emefiele latari bo ṣe ko owo naira kuro laarin ilu lẹyin ti CBN tẹ owo tuntun ni iwoyii ọdun meji ṣeyin.
Wayi o, lẹyin ti iwadii bẹrẹ lori ọrọ Emefiele ni ọpọlọpọ aṣiri bẹrẹ si n tu nipa awọn owo ti ọkunrin naa ko pamọ atawọn ile to n fi owo ilu kọ.
Ṣaaju ni ile ẹjọ ti kọkọ gbẹsẹle awọn dukia rẹ kan ninu eyii ti ọpọlọpọ awọn ile wa.
Amọ ṣa, lẹnu ọjọ mẹta yii ni akara afurasii ọhun tun tu sepo patapata lẹyin ti EFCC kede pe oun ti gbẹsẹle ile ti iye rẹ to 750 ti ọkuntrin naa n kọ lọwọ.
Lootọ ni EFCC kọkọ fi orukọ rẹ pamọ gẹgẹ bii ẹni ti ni awọn ile ọhun.
EFCC sọ pe ile naa wa lara awọn dukia ti oun gbẹsẹle to pọju ninu itan.
Abdullahi Gandujelori ẹsun iwa ajẹbanu to le ni ẹgbẹrun lọna irinwo dọla owo ilẹ Amẹrika ati biliọnu kan Naira

Oríṣun àwòrán, Abdullahi Ganduje
Ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun 2024 yii ni gomina ipinlẹ Kano tẹlẹ naa foju bale ẹjọ lori ẹsun riba ti iye rẹ to $413,000 ati owo to le ni biliọnu kan naira.
Ganduje, iyawo rẹ Hafsat ati ọmọ wọn Umar, to fi mọ awọn mẹfa mii ni wọn fẹsun kan pe wọn gba oniruru riba laarin ọdun 2016 si 2017.
Wọn tun fẹsun kan idile naa pe o gbiyanju lati sọ owo to wa fun ẹka eto ilera di ti ara wọn laarin ọdun 2020 si 2021.
Willie Obiano – ₦4b

Oríṣun àwòrán, Chief Willie Obiano
Gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ, Willie Obiano wa lara awọn afurasi ti EFCC fi ẹsun lilu owo ilu ni ponpo kan.
Lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kinni, ọdun 2024 ni EFCC gbe lọ sile ẹjọ kan niluu Abuja lori ajẹbanu owo ti iye rẹ to biliọnu mẹrin naira.
EFCC sọ pe ọkunrin naa ṣe apapin owo ijọba, o ko owo ilu sapo, bẹẹ lo tun jale lasiko rẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Anambra.
O ni oun ko jẹbi ẹsun ti EFCC fgi kan oun.
Betta Edu - ₦585m

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Betta Edu ni minisita ti ọjọ ori rẹ kere julọ lara awọn minisita ti Aarẹ Bola Ahmed Tinubu yan lati ṣiṣẹ pẹlu rẹ.
Amọ iṣẹ naa bọ lọwọ Betta lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o ko owo ijọba sinu apo iṣuna aladani.
Iye owo naa ni N585 miliọnu.
Ṣaaju ni araalu ti kọkọ ke sita lẹyin ti iwe kan lu sita, eyii to ṣafihan bi afurasi naa ṣe paṣẹ ki wọn ko owo kan to wa fun awọn alaini sinu apo aladani dipo ki wọn ko sinu apo ijọba apapọ.
Lẹyin ti ọrọ naa lu sita ni Tinubu kọkọ jawe lọ gbele ẹ fun obinrin ọhun ko to paarọ rẹ.
Betta ti sọ pe oun ko jẹbi ẹsun naa rara.
wayi o, gbgobo awọn eeyan wọnyii ni wọn sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.














