Kà nípa Naana Opoku-Agyemang, obìnrin àkọ́kọ́ tí wọ́n yàn sípò igbákejì Ààrẹ Ghana

Ọjọgbọn Naana Jane Opoku-Agyemang, obinrin akọkọ ti wọn dibo yan sipo Igbakeji aarẹ ni Ghana.

Oríṣun àwòrán, Naana Jane Opoku-Agyemang/Facebook.

Àkọlé àwòrán, Ọjọgbọn Naana Jane Opoku-Agyemang.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ṣinkin ni inu awọn eeyan n dun lorilẹ-ede Ghana lasiko yii, paapaa awọn obinrin, fun ti Naana Jane Opoku-Agyemang, obinrin akọkọ ti wọn dibo yan si ipo Igbakeji aarẹ.

Ọjọgbọn Opoku-Agyemang pẹlu John Mahama ni wọn jọ jawe olubori gẹgẹ bi Igbakeji aarẹ ati aarẹ orilẹede Ghana, ti wọn yoo si bẹrẹ iṣakoso ilu naa loṣu kin-in-ni ọdun 2025.

Naana Opoku, ẹni ọdun mẹtalelaadọrin (73), ni minisita eto ẹkọ lorilẹede Ghana lati 2013 si 2017, iyẹn lasiko iṣakoso John Mahama gẹgẹ bi aarẹ ilu naa.

Lasiko ti Naana Opoku n ṣe alakooso ẹtọ ẹkọ lo ṣe ohun to yatọ si ti tẹlẹ.

O kọ yara ikawe igbalode fun awọn akẹkọọ, o si tun pin iwe ati aṣọ ile ẹkọ ọfẹ fun wọn.

Ni 2020 ni John Mahama yan an bii Igbakeji rẹ labẹ ẹgbẹ oṣẹlu NDC, ṣugbọn wọn ko wọle ibo naa nigba yẹn.

Onimọ nla ni Ọjọgbọn Naana Opoku, oun naa ni obinrin akọkọ to di ọga agba ni Yunifasiti Cape Coast, laaarin ọdun 2008 si 2012.

O ti gba ami ẹyẹ lorilẹede Ghana ati loke okun kaakiri .

Ajafẹtọọ ọmọniyan tun ni Naana Opoku, ohun to maa n pariwo le lori ni pe ki ẹkọ to ye kooro kari, ati ki ẹnikẹni ma ṣe fiya jẹ awọn obinrin Ghana.

Nípa Naana Jane Opoku-Agyemang

Igbakeji aarẹ Ghana tuntun ree lasiko to n tọmọ lọwọ

Oríṣun àwòrán, Prof.Opoku-Agyemang/X

Àkọlé àwòrán, Ọjọgbọn Naana Opoku lasiko to n ṣ'abiyamọ

Ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla ọdun 1951 ni wọn bi Naana Jane, ọmọ bibi inu Sam.

Ọmọ bibi Cape Coast, Fante, ni Ghana ni.

Jane lọ sile ẹkọ alakọọbẹrẹ Anglican Girls' School, Koforidua, ati Aburi Presby Girls' School.

Lẹyin eyi lo lọ sileewe girama Wesley Girls High School, ni Cape Coast, laaarin ọdun 1964 si 1971.

Ọdun 1977 lo pari ẹkọ lorii imọ oyinbo ati ede Faranse (B.Ed.(Hons) in English and French) ni Yunifasiti Cape Coast).

Naana Opoku tun tẹsiwaju ninu imọ ede Faranse, o si gba iwe-ẹri 'Diploma in Advanced Studies in French', ni Yunifasiti Dakar.

O gba ti Master, ipele keji, ati tawọn ọmọwe ni York University to wa ni Toronto, Ontario ni Canada, eyi jẹ 1980 ati 1986.

Ọkan lara awọn oludari ni Naana Jane jẹ ni 'United Nations Educational, Scientific and Cultural Organization (UNESCO), ati lara awọn olootu Harriet Tubman Series', lori ọrọ awọn ọmọ Africa nilẹ okeere. (Africa World Press Inc.USA).

Ọpọlọpọ iwe ni Ọjọgbọn Opoku-Agyemang ti kọ nipa awọn obinrin, bẹẹ lo ni awọn ewi arofọ naa nilẹẹ Africa.

Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ 'Ghana Academy of Arts and Sciences and Fellow of di Commonwealth of Learning' ni i ṣe.

Igbeyawo Ọjọgbọn Opoku-Agyemang ti pe ogoji ọdun bayii.

Iya naa bi ọmọ mẹta; Kweku Opoku-Agyemang, Kwabena Opoku-Agyemang ati Maame Adwoa Opoku-Agyemang.

Bẹẹ lo ni ọmọ-ọmọ meji.

Kristẹni ni Naana Opoku, ileejọsin Methodist lo ti n jọsin.

Ẹnikan to maa n rọ awọn obinrin Ghana lati da si oṣelu ni Naana Jane Opoku.

Bakan naa lo tum maa n fun wọn ni imọ tuntun to le mu ẹka ẹkọ gunke agba si i ni Ghana.

Naana Jane Opoku lo gba ami ẹyẹ minisita to ṣiṣẹ ju, lasiko to n ṣe alakooso eto ẹkọ lorilẹede Ghana.