Ilé éjọ́ gba béèlì Yahaya Bello pẹ̀lú ₦500m, onídùró méjì

Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, Yahaya Bello

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti gba beeli gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ, Yahaya Bello pẹlu ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira.

Adajọ Emeka Nwite to gbọ ẹjọ naa lọjọ Ẹti sọ pe afurasi ọhun gbọdọ pese oniduro meji.

Awọn oniduro naa gbọdọ bura nile ẹjọ, wọn si gbọdọ jẹ ẹni to ni ilẹ tabi ile niluu Abuja.

Adajọ sọ siwaju si pe igbakeji akọwe ile ẹjọ giga naa gbọdọ fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni awọn oniduro ọhun ni dukia niluu Abuja.

Ile ẹjọ naa tun paṣẹ pe Bello gbọdọ jọwọ iwe irinna rẹ fun oun, ki awọn oniduro rẹ si fi aworan wọn ṣọwọ sile ẹjọ.

Lẹyin naa ni adajọ ni ki wọn fi afurasi ọhun si ahamọ ọgba ẹwọn Kuje titi di igba ti yoo fi yanju awọn ohun to nilo fun beeli rẹ.

Bello ti sọ fun ile ẹjọ ṣaaju pe oun ko jẹbi ẹsun kiko owo ti iye rẹ le ni ₦80b jẹ, eyii ti ajọ EFCC fi kan an.

EFCC ti kọkọ fẹsun kan ọkunrin naa lori ẹsun mọkandinlogun to rọ mọ lilu owo ilu ni ponpo.

O si ti wa ni ahamọ tẹlẹ lori ẹsun kiko ₦ 110b jẹ ṣaaju ko to bẹbẹ fun beeli.