Àjọ agbowóorí l'Ondo daṣẹ́ sílẹ̀, nítori owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ

Laipẹ yii ni Gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa, kede sisan ẹgbẹrun mẹtalelaadọrin (73,000) gẹgẹ bii owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ, ti wọn si bẹrẹ si i san owo naa f'awọn osiṣẹ.
Ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ajọ to n pawo wọle labẹle nipinlẹ naa, Ondo State Internal Revenue Service, (ODIRS), sọ pe awọn ko jẹ anfaani owo oṣu tuntun naa, bo tilẹ jẹ pe awọn ni wọn n pawo si apo ijọba.
Eyi lo mu ki wọn ti ọfiisi wọn pa lasiko ti wọn n fi ẹhonu han l'Ọjọbọ ọsẹ yii, ti wọn si n pe fun ayipada si owo oṣu wọn.
Awọn osisẹ naa wọ iru aṣọ kan naa, wọn si gbe paali dani pelu oniruuru àkọlé.
Lara àwọn ohun ti wọn n bẹrẹ fun ni; sisan iye owo oṣu tijọba Ondo kede fun wọn, mimu ayipada ba awọn owo t'awọn osisẹ n gba lati bii ọdun mẹfa sẹyin, fifun wọn ni igbega lenu iṣẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Awọn osisẹ ODIRS ṣalaye pe ẹgbẹrun marundinlọgọta naira (55,000) ni awọn n gba lati bii ọdun mẹfa sẹyin, lai si afikun.
Wọn ni bẹẹ ni ko si igbega lẹ́nu ìṣẹ naa fun awọn lati ọdun mẹfa sẹyin.
Bakan naa ni wọn ni owo oṣu t'awọn n gba kéré si iye ti wọn kọ sinu iwe igbani-sisẹ awọn, eyi ti ko bófin mu.
Wọn rọ ijọba Ondo lati ṣe atunṣe to yẹ ni kia, bi bẹẹ kọ, awọn ko ni i pada sẹnu iṣẹ.
Kì ni ìjọba Ondo sọ lórí àwọn ẹ̀sùn náà?

Ọgbẹni Bola Taiwo, Olugbani-nimọran fun gomina Aiyedatiwa lori ọrọ ẹgbẹ, ṣalaye pe ijọba Ondo ti setan lati ṣe gbogbo ohun ti awọn osisẹ naa n beere, pàápàá julọ, sisan owo oṣu to kere julọ.
O ni gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba Ondo lo ti n gba owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ tijọba kede.
Taiwo ṣalaye pe awọn osisẹ ODIRS ko si lara awọn ti àkọsílẹ̀ wa fun lati gba owo oṣu to kere julọ naa, nitori wọn gbe wọn kalẹ gẹgẹ bii ileeṣẹ adani ni.
Eyi lo ni o mu ki orúkọ ajọ naa ma si lara awọn ileeṣẹ ijọba to gba owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.
Bola Taiwo waa sọ ọ di mimọ, pe Gomina Lucky Aiyedatiwa tí pàṣẹ pe ki wọn san owo oṣu to kere julọ fun awọn osiṣẹ naa.
Nipa awọn isoro miran ti ajọ naa n koju, Bola Taiwo sọ pe gbogbo awọn ẹsun ti awọn osisẹ naa la kalẹ lo jẹ ajoji si ijọba.
O rọ awọn osisẹ naa lati kọ gbogbo awọn ohun ti wọn n la kọja, ki wọn si fi gbogbo rẹ sọwọ si ìjọba.
O ṣeleri pe ayipada yoo de ba eto igbayegbadun wọn laipẹ.














